Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Sin (1)

240 ẹsẹ · 2 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Èmi jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi sí ọ àti pé èmi kò sì fi àìṣòdodo mi pamọ́. Èmi wí pé, “Èmi yóò jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi fún Olúwa,” ìwọ sì dárí ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ mi jì mí. Sela.

  2. Kò sí ibi yíyè ní ara à mi, nítorí ìbínú rẹ; kò sí àlàáfíà nínú egungun mi nítorí i ẹ̀ṣẹ̀ mi.

  3. Nítorí àìṣedéédéé mi ti borí mi mọ́lẹ̀; wọ́n tó ìwọ̀n bi àjàgà tí ó wúwo jù fún mi.

  4. Mo jẹ́wọ́ ìrékọjá mi; àánú sì ṣe mí fún ẹ̀ṣẹ̀ mi.

  5. Ìwọ má ṣe, fa àánú rẹ tí ó rọ́nú sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ mi Olúwa; jẹ́ kí ìṣeun ìfẹ́ rẹ àti òtítọ́ rẹ kí ó máa pa mi mọ́ títí ayérayé.

  6. Nítorí pé àìníye ibi ni ó yí mi káàkiri, ẹ̀ṣẹ̀ mi sì dì mọ́ mi, títí tí èmi kò fi ríran mọ́; wọ́n pọ̀ ju irun orí mi lọ, àti wí pé àyà mí ti kùnà.

  7. Ní ti èmi, mo wí pé “Olúwa, ṣàánú fún mi; wò mí sàn, nítorí pé mo ti ṣẹ̀ sí ọ”.

  8. Wẹ gbogbo àìṣedéédéé mi nù kúrò kí o sì wẹ̀ mi mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ mi!

  9. Nítorí mo mọ̀ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi, nígbà gbogbo ni ẹ̀ṣẹ̀ mi wà níwájú mi.

  10. Sí ọ, ìwọ nìkan ṣoṣo, ni mo dẹ́ṣẹ̀ sí ni mo sì ṣe búburú níwájú rẹ̀, kí a lè dá ọ láre nígbà tí ìwọ bá ń sọ̀rọ̀, kí o sì le wà láìlẹ́bi, nígbà tí ìwọ bá ń ṣe ìdájọ́.

  11. Nítòótọ́, nínú ẹ̀ṣẹ̀ ni a ti bí mi, nínú ẹ̀ṣẹ̀ ni ìyá mí sì lóyún mi.

  12. Ìwọ mọ òmùgọ̀ mi, Ọlọ́run; ẹ̀bi mi kò pamọ́ lójú rẹ.

  13. Nígbà tí inú mi bàjẹ́ àti ọkàn mi ṣì korò,

  14. mo jẹ́ aṣiwèrè àti aláìlóye; mo jẹ́ ẹranko ní iwájú rẹ.

  15. Òun yóò san ẹ̀san ibi wọn fún wọn yóò sì pa wọ́n run nítorí búburú wọn Olúwa Ọlọ́run wa yóò pa wọ́n run.

  16. Àwa ti dẹ́ṣẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wa ti ṣe, àwa ti ṣe ohun tí kò dá a, a sì ti hùwà búburú.

  17. Èmi ti kíyèsi ọ̀nà mi èmi sì ti gbé ìgbésẹ̀ mi sí òfin rẹ.

  18. Èmi yóò yára, ń kò ni lọ́ra láti gbọ́rọ̀ sí àṣẹ rẹ.

  19. Èmí ti ṣìnà bí àgùntàn tí ó sọnù. Wá ìránṣẹ́ rẹ, nítorí èmi kò gbàgbé àṣẹ rẹ.

  20. Olúwa, ìbá ṣe pé kí ìwọ máa sàmì ẹ̀ṣẹ̀, Olúwa, tá ni ìbá dúró.

  21. Jẹ́ kí àwọn ẹni búburú ṣubú sínú àwọ̀n ara wọn, nígbà tí èmi bá kọjá lọ láìléwu.

  22. wọn yóò jẹ èrè iṣẹ́ ọwọ́ wọn wọn yóò sì jèrè èso ètè wọn ní kíkún.

  23. Ọlọ́gbọ́n jogún iyì, ṣùgbọ́n àwọn aṣiwèrè ni yóò ru ìtìjú wọn.

  24. Ìwà búburú ènìyàn búburú ni yóò mú kó bọ́ sínú okùn; okùn ẹ̀ṣẹ̀ ara rẹ̀ yóò sì dìímú.

  25. Yóò kú ní àìgba ẹ̀kọ́ ìwà òmùgọ̀ ara rẹ̀ yóò sì mú kí ó máa ṣìnà kiri.