Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Sin (1)

240 ẹsẹ · 2 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ̀ láti rí ń pa ara rẹ̀ lára gbogbo ẹni tí ó kórìíra mi fẹ́ ikú.”

  2. Ohun tí ènìyàn búburú bẹ̀rù yóò dé bá a; olódodo yóò rí ohun tí ó fẹ́ gbà.

  3. Ọ̀nà Olúwa jẹ́ ààbò fún olódodo, ṣùgbọ́n ìparun ni ó jẹ́ fún àwọn tí ń ṣe ibi.

  4. A kì yóò fa olódodo tu láéláé, ṣùgbọ́n ènìyàn búburú kì yóò dúró pẹ́ lórí ilẹ̀.

  5. Ẹnu olódodo ń mú ọgbọ́n jáde wá, ṣùgbọ́n ètè àyípadà ni a ó gé kúrò.

  6. Òdodo aláìlẹ́gàn ṣe ọ̀nà tààrà fún wọn, ṣùgbọ́n ìwà búburú ènìyàn búburú yóò fà á lulẹ̀.

  7. Òdodo ẹni ìdúró ṣinṣin gbà wọ́n là, ṣùgbọ́n ìdẹ̀kùn ètè búburú mú aláìṣòótọ́.

  8. Nígbà tí ènìyàn búburú bá kú, ìrètí rẹ̀ a parun; gbogbo ohun tó ń fojú ṣọ́nà fún nípa agbára rẹ̀ já ṣófo.

  9. Ènìyàn búburú gba èrè ìtànjẹ ṣùgbọ́n ẹni tó fúnrúgbìn òdodo yóò gba èrè tó dájú.

  10. Olódodo tòótọ́ rí ìyè ṣùgbọ́n ẹni tí ń lépa ibi lé e sí ibi ikú ara rẹ̀.

  11. Ẹni tí ń lépa ohun rere yóò rí ohun rere ṣùgbọ́n ibi yóò dé bá ẹni tí ń lépa ibi.

  12. Ẹni tí ó ń mú ìdààmú dé bá ìdílé rẹ̀ yóò jogún afẹ́fẹ́ lásán aláìgbọ́n yóò sì máa ṣe ìránṣẹ́ fún ọlọ́gbọ́n.

  13. A mú ènìyàn búburú nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ṣùgbọ́n olódodo bọ́ kúrò lọ́wọ́ ìdààmú.

  14. Láti inú èso rẹ̀, ènìyàn kún fún onírúurú ohun rere bí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ti ń pín in lérè dájúdájú.

  15. Ibi kì í ṣubú lu olódodo rárá ṣùgbọ́n ènìyàn búburú gba ìpín ìyọnu tiwọn.

  16. Olódodo ènìyàn máa ń ṣọ́ra láti dọ́rẹ̀ẹ́ ṣùgbọ́n ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú ń mú wọn ṣìnà.

  17. Olódodo kórìíra ohun tí í ṣe irọ́, ṣùgbọ́n ènìyàn búburú hu ìwà ìríra àti ìtìjú.

  18. Òdodo ń ṣamọ̀nà ènìyàn olóòtítọ́ inú, ṣùgbọ́n ìwà búburú ṣí ẹlẹ́ṣẹ̀ ní ipò.

  19. Òye pípé ń mú ni rí ojúrere, ṣùgbọ́n ọ̀nà aláìṣòótọ́ kì í tọ́jọ́.

  20. Ẹni tí ó bá fúnrúgbìn ẹ̀ṣẹ̀, yóò ká asán: ọ̀pá ìbínú rẹ̀ yóò kùnà.

  21. Bí ẹyẹ tí ó ṣáko lọ kúrò níbi ìtẹ́ rẹ̀ ni ènìyàn tí ó ṣáko lọ kúrò ní ilé rẹ̀.

  22. Ènìyàn búburú ń sá bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹnìkan kò lé e ṣùgbọ́n olódodo láyà bí i kìnnìún.

  23. Ẹ̀ṣẹ̀ ènìyàn ibi ni ó jẹ́ ìdẹ̀kùn rẹ̀ ṣùgbọ́n olódodo le è kọrin kí ó sì máa yọ̀.

  24. “Èyí ni ọ̀nà alágbèrè obìnrin ó jẹun ó sì nu ẹnu rẹ̀ ó sì wí pé, ‘N kò ṣe ohunkóhun tí kò tọ́.’

  25. Ìwò ojú wọn ń jẹ́rìí lòdì sí wọn, wọ́n ń polongo ẹ̀ṣẹ̀ wọn bí i Sodomu; wọn ò fi pamọ́! Ègbé ni fún wọn! Wọ́n ti mú ìparun wá sórí ara wọn.