Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Serpent

49 ẹsẹ · 16 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ó ti fà oró paramọ́lẹ̀ mú; ahọ́n ejò olóró ní yóò pa á.

  2. Oró wọn dàbí oró ejò, wọn dàbí adití ejò paramọ́lẹ̀ tí ó di ara rẹ̀ ni etí,

  3. tí kò ní gbọ́ ìpè àwọn atunilójú, bí ó ti wù kí ó máa fi ọgbọ́n ṣe ìtujú tó.

  4. Wọ́n ti pọ́n ahọ́n wọn bí ejò, oró paramọ́lẹ̀ ń bẹ ní abẹ́ ètè wọn.

  5. Ìwọ má ṣe wò ọtí wáìnì nígbà tí ó pọ́n, nígbà tí ó bá ń fi àwọ̀ rẹ̀ hàn nínú ago, tí a gbé e mì, tí ó ń dùn.

  6. Níkẹyìn òun á bu ni ṣán bí ejò, a sì bunijẹ bí i paramọ́lẹ̀.

  7. ipa ẹyẹ idì ní òfúrufú ipa ejò lórí àpáta ipa ọkọ̀ ojú omi lójú agbami Òkun àti ipa ọ̀nà ọkùnrin tí ó mú wúńdíá lọ́wọ́.

  8. Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbẹ́ kòtò, ó le è ṣubú sínú rẹ̀; ẹnikẹ́ni tí ó bá la inú ògiri, ejò le è ṣán an.

  9. Bí ejò bá ṣán ni kí a tó lo oògùn rẹ̀, kò sí èrè kankan fún olóògùn rẹ̀.

  10. Má ṣe yọ̀, gbogbo ẹ̀yin Filistia, pé ọ̀pá tí ó lù ọ́ ti dá; láti ibi gbòǹgbò ejò náà ni paramọ́lẹ̀ yóò ti hù jáde, èso rẹ̀ yóò sì jẹ́ oró ejò tí í jóni.

  11. Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ sí àwọn ẹranko tí ó wà ní gúúsù. Láàrín ilẹ̀ ìnira àti ìpọ́njú, ti kìnnìún àti abo kìnnìún ti paramọ́lẹ̀ àti ejò olóró, àwọn ikọ̀ náà kó ẹrù àti ọrọ̀ wọn lẹ́yìn àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àwọn ohun ìní wọn ní orí àwọn ìbákasẹ, sí orílẹ̀-èdè aláìlérè,

  12. Ìkookò àti ọ̀dọ́-àgùntàn yóò jẹun pọ̀, kìnnìún yóò sì jẹ koríko gẹ́gẹ́ bí akọ màlúù, ṣùgbọ́n erùpẹ̀ ni yóò jẹ́ oúnjẹ ejò. Wọn kì yóò pa ni lára tàbí pa ni run ní gbogbo òkè mímọ́ mi,” ni Olúwa wí.

  13. “Wò ó, èmi yóò rán àwọn ejò olóró sí àárín yín, paramọ́lẹ̀ tí ẹ kò lè pa oró wọn, yóò sì bù yín jẹ,” ni Olúwa wí.

  14. Bí wọ́n tilẹ̀ fi ara wọn pamọ́ ni orí òkè Karmeli, èmi yóò wá wọn rí, Èmi yóò si mú wọn kúrò níbẹ̀. Bí wọ́n tilẹ̀ fi ara pamọ́ fún mi sí ìsàlẹ̀ Òkun, láti ibẹ̀ ni Èmi yóò ti pàṣẹ fún ejò kí ó bù wọ́n ṣán.

  15. Wọn yóò lá erùpẹ̀ bí ejò, wọn yóò sì jáde kúrò nínú ihò wọn bí ekòló. Wọn yóò bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run wa, wọn yóò sì bẹ̀rù nítorí rẹ̀.

  16. Tàbí bí ó béèrè ẹja, tí yóò jẹ́ fún un ní ejò?

  17. “Mò ń rán yín lọ gẹ́gẹ́ bí àgùntàn sáàrín ìkookò. Nítorí náà, kí ẹ ní ìṣọ́ra bí ejò, kí ẹ sì ṣe onírẹ̀lẹ̀ bí àdàbà.

  18. Wọn yóò sì gbé ejò lọ́wọ́, bí wọ́n bá sì jẹ májèlé kò nípa wọ́n lára rárá. Wọ́n yóò gbé ọwọ́ lé àwọn aláìsàn, ara wọn yóò sì dá.”

  19. Kíyèsi i, èmí fún yín ní àṣẹ láti tẹ ejò àti àkéekèe mọ́lẹ̀, àti lórí gbogbo agbára ọ̀tá, kò sì ṣí ohun kan bí ó ti wù tí ó ṣe, tí yóò pa yín lára.

  20. Òun sì gbọn ẹranko náà sínú iná ohunkóhun kan kò sì ṣe é.

  21. Ṣùgbọ́n wọn ń wòye ìgbà tí yóò wù, tàbí tí yóò sì ṣubú lulẹ̀ láti kú lójijì; nígbà tí wọ́n wò títí, tí wọn kò sì rí nǹkan kan kí ó ṣe é, wọ́n pa èrò wọn dà pé, òrìṣà kan ni ọkùnrin yìí.

  22. Bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin má ṣe dán Olúwa wò, gẹ́gẹ́ bí àwọn mìíràn nínú wọn ti dán an wò, tí a sì fi ejò run wọ́n.

  23. Ṣùgbọ́n ẹ̀rù ń bà mí, kí ó má bà á jẹ́ pé, bí ejò ti tan Efa jẹ́ nípasẹ̀ àrékérekè rẹ̀, a lè mú ọkàn yín ṣáko lọ kúrò nínú òtítọ́ yín àti ìfarajì fún Kristi.

  24. Nítorí pé agbára àwọn ẹṣin náà ń bẹ ní ẹnu wọn àti ní ìrù wọn: nítorí pé ìrù wọn dàbí ejò, wọn sì ní orí, àwọn wọ̀nyí ni wọn sì fi ń pa ni lára.