Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Reward

166 ẹsẹ · 1 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. “Nígbà náà ni yóò sọ fún àwọn tí ọwọ́ òsì pé, ‘Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin ẹni ègún, sínú iná àìnípẹ̀kun tí a ti tọ́jú fún èṣù àti àwọn angẹli rẹ̀.

  2. Nítorí tí ebi pa mi, ẹ̀yin kò tilẹ̀ bọ́ mi, òrùngbẹ gbẹ mi, ẹ kò tilẹ̀ fún mi ní omi láti mu.

  3. Mo jẹ́ àlejò, ẹ̀yin kò tilẹ̀ gbà mi sílé. Mo wà ní ìhòhò, ẹ̀yin kò fi aṣọ bò mi. Mo ṣàìsàn, mo sì wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, ẹ̀yin kò bẹ̀ mí wò.’

  4. “Nígbà náà àwọn pẹ̀lú yóò dáhùn pé, ‘Olúwa, nígbà wo ni àwa rí ọ, tí ebi ń pa ọ́ tàbí tí òǹgbẹ ń gbẹ ọ́, tàbí tí o ṣàìsàn, tàbí tí o wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, tí a kò sí ràn ọ́ lọ́wọ́?’

  5. “Nígbà náà àwọn yóò dáhùn pé, ‘Lóòótọ́ ni mo wí fún pé, nígbà tí ẹ̀yin ti kọ̀ láti ran ọ̀kan nínú àwọn tí ó kéré jù lọ́wọ́ nínú arákùnrin mi, ẹ̀yin tí kọ̀ láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún mi ni.’

  6. “Nígbà náà wọn yóò sì kọjá lọ sínú ìyà àìnípẹ̀kun, ṣùgbọ́n àwọn olódodo yóò lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun.”

  7. Jesu wò ó tìfẹ́tìfẹ́. Ó wí fún un pé, “Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ohun kan ló kù fún ọ láti ṣe, lọ nísinsin yìí, ta gbogbo nǹkan tí o ní, kí o sì pín owó náà fún àwọn aláìní ìwọ yóò sì ní ìṣúra ní ọ̀run, sì wá, kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn.”

  8. Àwọn ènìyàn yóò kórìíra yín nítorí tí ẹ jẹ́ tèmi. Ṣùgbọ́n ẹni tó bá fi ara da ìyà títí dé òpin tí kò sì kọ̀ mí sílẹ̀ òun ni yóò rí ìgbàlà.

  9. Alábùkún fún ni ẹ̀yin, nígbà tí àwọn ènìyàn bá kórìíra yín, tí wọ́n bá yà yín kúrò nínú ẹgbẹ́ wọn, tí wọ́n bá gàn yín, tí wọ́n bá ta orúkọ yín nù bí ohun búburú, nítorí Ọmọ Ènìyàn.

  10. “Ẹ jẹ́ kí inú yín dùn, kí ẹ sì fò fún ayọ̀, nítorí púpọ̀ ní èrè yín ni ọ̀run. Báyìí ni àwọn baba yín ṣe ṣe sí àwọn wòlíì.

  11. Ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin fẹ́ àwọn ọ̀tá yín kí ẹ sì ṣoore, kí ẹ̀yin sì yá ẹlòmíràn, kí ẹ̀yin má ṣe retí láti rí nǹkan gbà padà; èrè yín yóò sì pọ̀, àwọn ọmọ Ọ̀gá-ògo ni a ó sì máa pè yín: nítorí tí ó ṣe rere fún aláìmoore àti fún ẹni búburú.

  12. “Mo sì wí fún yín pẹ̀lú, Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́wọ́ mi níwájú àwọn ènìyàn. Ọmọ Ènìyàn yóò sì jẹ́wọ́ rẹ̀ níwájú àwọn angẹli Ọlọ́run.

  13. láti là wọ́n lójú, kí wọn lè yípadà kúrò nínú òkùnkùn sí ìmọ́lẹ̀, àti kúrò lọ́wọ́ agbára Satani sí Ọlọ́run, kí wọn lè gba ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀, àti ogún pẹ̀lú àwọn tí a sọ di mímọ́ nípa ìgbàgbọ́ nínú mi.’

  14. ṣùgbọ́n ògo, àti ọlá, àti àlàáfíà, fún olúkúlùkù ẹni tí ń hùwà rere, fún Júù, ṣáájú àti fún àwọn Helleni pẹ̀lú.

  15. Ẹni tí ó ń gbìn àti ẹni tí ó ń bu omi rín ní ìrònú kan àti èrèdí kan, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹnìkọ̀ọ̀kan wa yóò gba èrè tirẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe é kárakára tó.

  16. Ẹ̀yin ọmọ, ẹ máa gbọ́ tí àwọn òbí i yín nínú Olúwa, nítorí pé èyí ní ó tọ́.

  17. “Bọ̀wọ̀ fún baba àti ìyá rẹ,” èyí tí í ṣe òfin kìn-ín-ní pẹ̀lú ìlérí,

  18. “ki ó lé dára fún ọ, àti kí ìwọ lè wà pẹ́ ní ayé.”

  19. Nítorí ẹ̀yin bá àwọn tí ó wà nínú ìdè kẹ́dùn, ẹ sì fi ayọ̀ gba ìkólọ ẹrù yin, nítorí ẹ̀yin mọ nínú ara yin pé, ẹ ni ọrọ̀ tí ó wà títí, tí ó sì dára jù bẹ́ẹ̀ lọ.

  20. Nítorí ẹ̀yin kò le ṣe aláìní sùúrù, nítorí ìgbà tí ẹ̀yin bá ti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run tan kí ẹ̀yin le gba ìlérí náà.

  21. Ó ka ẹ̀gàn Kristi si ọrọ̀ tí ó pọ̀jù àwọn ìṣúra Ejibiti lọ, nítorí tí ó ń wo èrè náà.

  22. Nítorí náà bí a ti fi ìkùùkuu àwọsánmọ̀ tí o kún fún àwọn ẹlẹ́rìí tó báyìí yí wa ká, ẹ jẹ́ kí a pa ohun ìdíwọ́ gbogbo tì sí apá kan, àti ẹ̀ṣẹ̀ tí o rọrùn láti di mọ́ wa, kí a sì máa fi sùúrù súré ìje tí a gbé ka iwájú wa,

  23. kí a máa wo Jesu Olùpilẹ̀ṣẹ̀ àti aláṣepé ìgbàgbọ́ wa; ẹni nítorí ayọ̀ tí a gbé ka iwájú rẹ, tí o faradà àgbélébùú láìka ìtìjú sí, tí ó sì jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún ìtẹ́ Ọlọ́run.

  24. Nítorí náà bí àwa tí ń gbà ilẹ̀ ọba ti a kò lè mì, ẹ jẹ́ kí a dá ọpẹ́ nípa èyí ti a fi lè máa sin Ọlọ́run ni ìtẹ́wọ́gbà pẹ̀lú ọ̀wọ̀ àti ìbẹ̀rù rẹ̀.

  25. Ẹ má ṣe fi búburú san búburú, tàbí fi èébú san èébú: ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ máa súre; nítorí èyí ni a pè yín sí, kí ẹ̀yin lè jogún ìbùkún.