Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Reward

166 ẹsẹ · 1 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Èmi a sì máa fi àánú hàn sí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn tí ó fẹ́ mi, tí wọ́n sì ń pa òfin mi mọ́.

  2. Bọ̀wọ̀ fún baba òun ìyá rẹ, kí ọjọ́ rẹ kí ó lè pẹ́ ní orí ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ fi fún ọ.

  3. “ ‘Ẹ tẹ̀lé àwọn ìlànà mi, kí ẹ sì kíyèsi láti pa òfin mi mọ́, kí ẹ ba à le máa gbé láìléwu ní ilẹ̀ náà.

  4. Nígbà yìí ni ilẹ̀ náà yóò so èso rẹ̀, ẹ ó sì jẹ àjẹyó, ẹ ó sì máa gbé láìléwu.

  5. “ ‘Bí ẹ̀yin bá tẹ̀lé àṣẹ mi, tí ẹ̀yin sì ṣọ́ra láti pa òfin mi mọ́.

  6. Èmi yóò rọ̀jò fún yín ní àkókò rẹ̀, kí ilẹ̀ yín le mú èso rẹ̀ jáde bí ó tí yẹ kí àwọn igi eléso yín so èso.

  7. Èrè oko yín yóò pọ̀ dé bi pé ẹ ó máa pa ọkà títí di àsìkò ìkórè igi eléso, ẹ̀yin yóò sì máa gbé ní ilẹ̀ yín láìléwu.

  8. “ ‘Èmi yóò fún yín ní àlàáfíà ní ilẹ̀ yín, ẹ̀yin yóò sì sùn láìsí ìbẹ̀rù ẹnikẹ́ni. Èmi yóò mú kí gbogbo ẹranko búburú kúrò ní ilẹ̀ náà, bẹ́ẹ̀ ni idà kì yóò la ilẹ̀ yín já.

  9. Ẹ̀yin yóò lé àwọn ọ̀tá yín, wọn yóò sì tipa idà kú.

  10. Àwọn márùn-ún péré nínú yín yóò máa ṣẹ́gun ọgọ́rùn-ún ènìyàn, àwọn ọgọ́rùn-ún yóò sì máa ṣẹ́gun ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000), àwọn ọ̀tá yín yóò tipa idà kú níwájú yín.

  11. “ ‘Èmi yóò fi ojúrere wò yín, Èmi yóò mú kí ẹ bí sí i, Èmi yóò jẹ́ kí ẹ pọ̀ sí i, Èmi yóò sì pa májẹ̀mú mi mọ́ pẹ̀lú yín.

  12. Àwọn èrè oko yín yóò pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ẹ̀yin ó máa jẹ èrè ọdún tí ó kọjá, ẹ̀yin ó sì kó wọn jáde, kí ẹ̀yin lè rí ààyè kó tuntun sí.

  13. Èmi yóò kọ́ àgọ́ mímọ́ mi sí àárín yín. Èmi kò sì ní kórìíra yín.

  14. Èmi yóò wà pẹ̀lú yín, Èmi yóò máa jẹ́ Ọlọ́run yín, ẹ̀yin yóò sì máa jẹ́ ènìyàn mi.

  15. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín tí ó mú yín jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti, kí ẹ̀yin má ba à jẹ́ ẹrú fún wọn mọ́. Mo sì já ìdè àjàgà yín, mo sì mú kí ẹ̀yin máa rìn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí a gbé lórí sókè.

  16. “ ‘Bí ẹ̀yin kò bá fetí sí mi tí ẹ̀yin kò sì ṣe gbogbo òfin wọ̀nyí.

  17. Bí ẹ̀yin bá kọ àṣẹ mi tí ẹ̀yin sì kórìíra òfin mi, tí ẹ̀yin sì kùnà láti pa ìlànà mi mọ́, nípa èyí tí ẹ̀yin ti ṣẹ̀ sí májẹ̀mú mi.

  18. Èmi yóò ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí sí yín, Èmi yóò mú ìpayà òjijì bá yín: àwọn ààrùn afiniṣòfò, àti ibà afọ́nilójú, tí í pa ni díẹ̀díẹ̀. Ẹ̀yin yóò gbin èso ilẹ̀ yín lásán, nítorí pé àwọn ọ̀tá yín ni yóò jẹ gbogbo ohun tí ẹ̀yin ti gbìn.

  19. Èmi yóò dojúkọ yín títí tí ẹ̀yin ó fi di ẹni ìkọlù; àwọn tí ó kórìíra yín ni yóò sì ṣe àkóso lórí yín. Ìbẹ̀rù yóò mú yín dé bi pé ẹ̀yin yóò máa sá káàkiri nígbà tí ẹnikẹ́ni kò lé yín.

  20. “ ‘Bí ẹ̀yin kò bá wá gbọ́ tèmi lẹ́yìn gbogbo èyí, Èmi yóò fi kún ìyà yín ní ìlọ́po méje nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín.

  21. Èmi yóò fọ́ agbára ìgbéraga yín, ojú ọ̀run yóò le koko bí irin, ilẹ̀ yóò sì le bí idẹ (òjò kò ní rọ̀: ilẹ̀ yín yóò sì le).

  22. Ẹ ó máa lo agbára yín lásán torí pé ilẹ̀ yín kì yóò so èso, bẹ́ẹ̀ ni àwọn igi yín kì yóò so èso pẹ̀lú.

  23. “ ‘Bí ẹ bá tẹ̀síwájú láì gbọ́ tèmi, Èmi yóò tún fa ìjayà yín le ní ìgbà méje gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ yín.

  24. Èmi yóò rán àwọn ẹranko búburú sí àárín yín, wọn yóò sì pa àwọn ọmọ yín, wọn yóò run agbo ẹran yín, díẹ̀ nínú yín ni wọn yóò ṣẹ́kù kí àwọn ọ̀nà yín lè di ahoro.

  25. “ ‘Bí ẹ kò bá tún yípadà lẹ́yìn gbogbo ìjìyà wọ̀nyí, tí ẹ sì tẹ̀síwájú láti lòdì sí mi.