Skip to content

Gerizim

4 verses

32.1900, 35.2700 Wo lórí Google Maps

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Gerizim

  1. Nígbà tí Olúwa Ọlọ́run yín bá ti mú un yín dé ilẹ̀ náà tí ẹ ń wọ̀ láti gbà, kí ẹ kéde àwọn ìbùkún náà ní orí òkè Gerisimu, kí ẹ sì kéde àwọn ègún ní orí òkè Ebali.

  2. Nígbà tí ìwọ bá ti kọjá a Jordani, àwọn ẹ̀yà yìí yóò dúró lórí òkè Gerisimu láti súre fún àwọn ènìyàn: Simeoni, Lefi, Juda, Isakari, Josẹfu àti Benjamini.

  3. Gbogbo Israẹli, àjèjì àti ọmọ ìlú, pẹ̀lú àwọn àgbàgbà, olórí àti onídàájọ́ dúró ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì àpótí ẹ̀rí Olúwa tí ó kọjú sí àwọn àlùfáà tí ó rù ú, tí wọ́n jẹ́ ọmọ Lefi. Ìdajì àwọn ènìyàn náà dúró ní òkè Gerisimu, àwọn ìdajì si dúró ni òkè Ebali, gẹ́gẹ́ bí Mose ìránṣẹ́ Olúwa ti pàṣẹ rí, pé kí wọn súre fún àwọn ènìyàn Israẹli.

  4. Nígbà tí wọ́n sọ ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ yìí fún Jotamu, ó gun orí ṣóńṣó òkè Gerisimu lọ, ó sì ké lóhùn rara pé, “Ẹ tẹ́tí sí mi, ẹ̀yin àgbàgbà Ṣekemu, kí Ọlọ́run le tẹ́tí sí yín.