- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Religious Zeal
Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì
Bí ó bá ṣe tèmi ni, èmi wà ní ọwọ́ yín, ẹ ṣe ohun tí ẹ̀yin bá rò pé ó dára, tí ó sì tọ́ lójú yín fún mi.
Ẹ mọ̀ dájú pé tí ẹ bá pa mí, ẹ ó mú ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ wá sórí ara yín, sórí ìlú yìí àti àwọn olùgbé inú rẹ̀; nítorí pé nítòótọ́ ni Olúwa ti rán mi láti sọ ọ̀rọ̀ yìí fún un yín.”
Ó sì sọ fún un pé, “La àárín ìlú Jerusalẹmu já, kí ìwọ sì fi àmì síwájú orí gbogbo àwọn tó ń kẹ́dùn, tó sì ń sọkún nítorí ohun ìríra tí wọn ń ṣe láàrín rẹ̀.”
“ ‘Ṣùgbọ́n àwọn àlùfáà, tí ó jẹ́ Lefi àti àwọn ìran Sadoku tí fi tọkàntọkàn ṣe iṣẹ́ ibi mímọ́ mi nígbà tí àwọn Israẹli ṣáko lọ kúrò lọ́dọ̀ mi, wọn gbọdọ̀ súnmọ́ iwájú láti ṣe ìránṣẹ́ ní iwájú mi, láti rú ẹbọ ọ̀rá àti ẹ̀jẹ̀, ni Olúwa Olódùmarè wí.
Bí ẹ̀yin bá jù wá sínú iná ìléru, Ọlọ́run tí àwa ń sìn lágbára láti gbà wá kúrò nínú rẹ̀, yóò sì gbà wá lọ́wọ́ ọ̀ rẹ, ìwọ ọba.
Ṣùgbọ́n tí kò bá rí bẹ́ẹ̀, a fẹ́ kí ìwọ ọba mọ̀ dájú wí pé àwa kò ní sin òrìṣà rẹ bẹ́ẹ̀ ni a kò ní fi orí balẹ̀ fún ère wúrà tí ìwọ gbé kalẹ̀.”
Àwọn tí ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n yóò máa tàn bí ìmọ́lẹ̀ ọ̀run, àti àwọn tí ó ń tọ́nisọ́nà sí òdodo, yóò máa tàn bí ìràwọ̀ láé àti láéláé.
Ṣùgbọ́n ní tèmi, èmi kún fún agbára pẹ̀lú ẹ̀mí Olúwa, láti sọ ìré-òfin-kọjá Jakọbu fún un, àti láti sọ ẹ̀ṣẹ̀ Israẹli fún un.
Ìyókù Jakọbu yóò sì wà láàrín ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn bí ìrì láti ọ̀dọ̀ Olúwa wa, bí ọ̀wààrà òjò lórí koríko, tí kò gbẹ́kẹ̀lé ènìyàn tàbí kò dúró de àwọn ọmọ ènìyàn.
Ègbé ni fún mi! Nítorí èmi sì dàbí ẹni tí ń kó èso ẹ̀ẹ̀rùn jọ, ìpèsè ọgbà àjàrà; kò sì ṣí odidi àjàrà kankan láti jẹ, kò sì ṣí àkọ́so ọ̀pọ̀tọ́ nítorí tí ebi ń pa mí.
Àwọn olódodo sì ti kúrò ní ilẹ̀ náà, kò sì ṣí ẹnìkan tí ó ṣẹ́kù tí ó jọ olóòtítọ́; gbogbo wọn sì ń purọ́ ní dídúró nítorí ìtàjẹ̀ sílẹ̀, olúkúlùkù wọ́n sì ń fi àwọ̀n de arákùnrin rẹ̀.
Olúwa, èmi yóò ti ké pẹ́ tó fún ìrànlọ́wọ́, ṣùgbọ́n ti ìwọ kò ni fetí sí mi? Tàbí kígbe sí ọ ní ti, “Ìwà ipá!” Ṣùgbọ́n tí ìwọ kò sì gbàlà?
Èéṣe tí ìwọ fi mú mi rí àìṣedéédéé? Èéṣe tí ìwọ sì fi ààyè gba ìwà ìkà? Ìparun àti ìwà ipá wà ní iwájú mi; ìjà ń bẹ, ìkọlù sì wà pẹ̀lú.
Nítorí náà, òfin di ohun àìkàsí, ìdájọ́ òdodo kò sì borí. Àwọn ẹni búburú yí àwọn olódodo ká, nítorí náà ni ìdájọ́ òdodo ṣe yí padà.
Nígbà náà ni Olúwa dáhùn pé, “Kọ ìṣípayá náà sílẹ̀ kí o sì fi hàn ketekete lórí wàláà kí ẹni tí ń kà á, lè máa sáré.
Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, múra gírí, ìwọ Serubbabeli,’ ni Olúwa wí. ‘Múra gírí, ìwọ Joṣua ọmọ Josadaki, olórí àlùfáà. Ẹ sì múra gírí gbogbo ẹ̀yin ènìyàn ilẹ̀ náà,’ ni Olúwa wí, ‘kí ẹ sì ṣiṣẹ́. Nítorí èmi wà pẹ̀lú yín,’ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.
‘Èyí ni ohun tí Èmi fi bá a yín dá májẹ̀mú nígbà tí ẹ jáde kúrò ní Ejibiti, bẹ́ẹ̀ ni Ẹ̀mí ì mi sì wà pẹ̀lú yín. Ẹ má ṣe bẹ̀rù.’
Ní ọjọ́ náà ni “mímọ́ sí Olúwa” yóò wà lára ṣaworo ẹṣin: àti àwọn ìkòkò ni ilé Olúwa yóò sì dàbí àwọn ọpọ́n tí ń bẹ níwájú pẹpẹ.
Nítòótọ́, gbogbo ìkòkò ni Jerusalẹmu àti ni Juda yóò jẹ́ mímọ́ sí Olúwa àwọn ọmọ-ogun: àti gbogbo àwọn tí ń rú ẹbọ yóò wá, wọn ó sì mú ìkòkò díẹ̀, wọn ó sì bọ ẹran wọn nínú rẹ̀, ni ọjọ́ náà ni àwọn Kenaani kò ní sí mọ́ ni ilé Olúwa àwọn ọmọ-ogun.
“Ẹ̀yin ni iyọ̀ ayé. Ṣùgbọ́n bí iyọ̀ bá di òbu kí ni a ó fi mú un dùn? Kò tún wúlò fún ohunkóhun mọ́, bí kò ṣe pé kí a dàánù, kí ó sì di ohun tí ènìyàn ń fi ẹsẹ̀ tẹ̀ mọ́lẹ̀.
“Ẹyin ni ìmọ́lẹ̀ ayé. Ìlú tí a tẹ̀dó sórí òkè kò lè fi ara sin.
Bẹ́ẹ̀ ni a kì í tan fìtílà tán, kí a sì gbé e sí abẹ́ òsùwọ̀n; bí kò ṣe sí orí ọ̀pá fìtílà, a sì tan ìmọ́lẹ̀ fún gbogbo ẹni tí ń bẹ nínú ilé.
Bákan náà, ẹ jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ yín kí ó mọ́lẹ̀ níwájú ènìyàn, kí wọ́n lè máa rí iṣẹ́ rere yín, kí wọn lè máa yin baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run lógo.
Olùkọ́ òfin kan sì tọ̀ ọ́ wá, ó wí fún un pé, “Olùkọ́, èmi ó má tọ̀ ọ́ lẹ́yìn níbikíbi tí ìwọ bá ń lọ.”
Jesu dá lóhùn pé, “Àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ní ihò, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ni ìtẹ́; ṣùgbọ́n Ọmọ Ènìyàn kò ní ibi tí yóò fi orí rẹ̀ lé.”