Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Religious Zeal: Exemplified by Paul

423 ẹsẹ · 5 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Exemplified by Paul

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Lójúkan náà ó sì ń wàásù Kristi nínú àwọn Sinagọgu pé, Jesu ni Ọmọ Ọlọ́run.

  2. Ẹnu sì yà gbogbo àwọn ti ó ń gbọ́, wọn sì wí pé, “Èyí ha kọ ẹni ti ó ti fóòro àwọn ti ń pe orúkọ yìí ni Jerusalẹmu? Nítorí èyí náà ni ó sa ṣe wá sí ìhín yìí, láti mú wọn ní dìde lọ sọ́dọ̀ àwọn olórí àlùfáà.”

  3. Ṣùgbọ́n Saulu ń pọ̀ sí i ní agbára ó sì ń dààmú àwọn Júù tí ó ń gbé Damasku, ó fihàn pé, èyí ni Kristi náà.

  4. Lẹ́yìn ìgbà tí ọjọ́ púpọ̀ kọjá, àwọn Júù ń gbìmọ̀ láti pa á.

  5. Ṣùgbọ́n ìdìtẹ̀ wọn di mí mọ̀ fún Saulu. Wọ́n sì ń ṣọ́ ẹnu ibodè pẹ̀lú lọ́sàn àti lóru, wọ́n ń wá ọ̀nà láti pa á.

  6. Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ gbé ní òru, wọ́n sì sọ̀ ọ́ kalẹ̀ lára odi nínú agbọ̀n.

  7. Nígbà ti Saulu sì de Jerusalẹmu ó pète láti da ara rẹ̀ pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn; gbogbo wọn sì bẹ̀rù rẹ̀, nítorí wọn kò gbàgbọ́ pé ọmọ-ẹ̀yìn kan ni.

  8. Ṣùgbọ́n Barnaba mú un, ó sì sìn ín lọ sọ́dọ̀ àwọn aposteli, ó sì sọ fún wọn bí ó ti rí Olúwa ní ọ̀nà, àti bí ó ti fi ìgboyà wàásù ní Damasku ní orúkọ Jesu.

  9. Saulu sì wà pẹ̀lú wọn, ó ń wọlé, ó sì ń jáde ní Jerusalẹmu. Ó sì ń fi ìgboyà wàásù ni orúkọ Olúwa.

  10. Ó ń sọ̀rọ̀ lòdì sí àwọn ará Helleni, ó sì ń jà wọ́n ní iyàn; ṣùgbọ́n wọn ń pète láti pa a.

  11. Paulu sì dìde dúró, ó sì juwọ́ sí wọn, ó ní, “Ẹ̀yin Israẹli, àti ẹ̀yin ti ó bẹ̀rù Ọlọ́run, ẹ fi etí sílẹ̀ sí mi!

  12. Ọlọ́run àwọn ènìyàn Israẹli yìí yan àwọn baba wa, ó sì gbé àwọn ènìyàn náà lékè, nígbà tí wọ́n ṣe àtìpó ní ilẹ̀ Ejibiti, pẹ̀lú agbára ńlá ni ó sì fi mú wọn jáde kúrò nínú rẹ̀,

  13. ní ìwọ̀n ìgbà ogójì ọdún ni ó fi mú sùúrù fún ìwà wọn ní ijù,

  14. nígbà tí ó sì ti run orílẹ̀-èdè méje ni ilẹ̀ Kenaani, ó sì fi ilẹ̀ wọn fún àwọn ènìyàn rẹ̀ ni ìní.

  15. Gbogbo èyí sì ṣẹlẹ̀ fún ìwọ̀n àádọ́ta lé ní irinwó (450) ọdún. “Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí ni Ọlọ́run fi onídàájọ́ fún wọn, títí ó fi di ìgbà Samuẹli wòlíì.

  16. Lẹ́yìn náà ni wọ́n sì béèrè ọba; Ọlọ́run sì fún wọn ní Saulu ọmọ Kiṣi, ọkùnrin kan nínú ẹ̀yà Benjamini, fún ogójì ọdún.

  17. Nígbà ti ó sì mú Saulu kúrò, ó gbé Dafidi dìde ní ọba fún wọn, ẹni tí ó sì jẹ́rìí rẹ̀ pé, ‘Mo rí Dafidi ọmọ Jese ẹni bí ọkàn mi, ti yóò ṣe gbogbo ìfẹ́ mi.’

  18. “Láti inú irú-ọmọ ọkùnrin yìí ni Ọlọ́run ti gbé Jesu Olùgbàlà dìde fún Israẹli gẹ́gẹ́ bí ìlérí.

  19. Ṣáájú wíwá Jesu ni Johanu ti wàásù bamitiisi ìrònúpìwàdà fún gbogbo ènìyàn Israẹli.

  20. Bí Johanu sì ti ńlá ipa tirẹ̀ já, ó ni, ‘Ta ni ẹ̀yin ṣe bí èmi jẹ́? Èmi kì í ṣe òun. Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsi í, ẹnìkan ń bọ̀ lẹ́yìn mi, bàtà ẹsẹ̀ ẹni tí èmi kò tó tú.’

  21. “Ará, ẹ̀yin ọmọ ìran Abrahamu, àti ẹ̀yin ti ó bẹ̀rù Ọlọ́run, àwa ni a rán ọ̀rọ̀ ìgbàlà yìí sí.

  22. Nítorí àwọn tí ń gbé Jerusalẹmu, àti àwọn olórí wọn, nítorí tiwọn kò mọ̀ Jesu, tí wọn kò sì ní òye ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì, tí a ń kà ní ọjọọjọ́ ìsinmi fún wọn, kò yé wọn, wọ́n mú ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì yìí ṣẹ nípa dídá a lẹ́bi.

  23. Àti bí wọn kò tilẹ̀ ti rí ọ̀ràn ikú sí i, síbẹ̀ wọn rọ Pilatu láti pa á.

  24. Bí wọ́n ti mú nǹkan gbogbo ṣẹ ti a kọ̀wé nítorí rẹ̀, wọn sì sọ̀ ọ́ kalẹ̀ kúrò lórí igi, wọ́n sì tẹ́ ẹ sí ibojì.

  25. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run jí i dìde kúrò nínú òkú,