- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Religious Zeal
Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì
Èmi wo àwọn ẹlẹ́tàn, inú mi sì bàjẹ́ nítorí wọn kò gba ọ̀rọ̀ rẹ gbọ́.
Èso òdodo ni igi ìyè ẹni tí ó sì jèrè ọkàn jẹ́ ọlọ́gbọ́n.
Àwọn tí ó kọ òfin sílẹ̀ a máa gbóríyìn fún ènìyàn búburú ṣùgbọ́n àwọn tí ó pa òfin mọ́ kọjú ìjà sí ènìyàn búburú.
Má ṣe jẹ́ olódodo jùlọ tàbí ọlọ́gbọ́n jùlọ kí ló dé tí o fi fẹ́ pa ara rẹ run?
Ohunkóhun tí ọwọ́ rẹ bá rí láti ṣe, ṣe é pẹ̀lú gbogbo agbára rẹ, nítorí kò sí iṣẹ́ ṣíṣe tàbí ìpinnu tàbí ìmọ̀ tàbí ọgbọ́n nínú isà òkú níbi tí ò ń lọ.
Kì í ṣe wí pé Oniwaasu jẹ́ ọlọ́gbọ́n nìkan, ṣùgbọ́n ó tún kọ́ àwọn ènìyàn ní ìmọ̀. Ó rò ó dáradára ó sì ṣe àwárí, ó sì gbé ọ̀pọ̀lọpọ̀ òwe kalẹ̀ lẹ́sẹẹsẹ.
Oniwaasu wádìí láti rí àwọn ọ̀rọ̀ tí ó tọ̀nà, ohun tí ó kọ sì dúró ṣinṣin ó sì jẹ́ òtítọ́.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni yóò wá, wọn yóò sì wí pé, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á gòkè ńlá Olúwa, àti sí ilé Ọlọ́run Jakọbu. Òun yóò kọ́ wa ní ọ̀nà rẹ̀, kí àwa kí ó lè rìn ní ọ̀nà rẹ̀.” Òfin yóò jáde láti Sioni wá, àti ọ̀rọ̀ Olúwa láti Jerusalẹmu.
Wá, ẹ̀yìn ará ilé e Jakọbu, ẹ jẹ́ kí a rìn nínú ìmọ́lẹ̀ Olúwa.
Nígbà náà ni mo sì gbọ́ ohùn Olúwa wí pé, “Ta ni èmi yóò rán? Ta ni yóò sì lọ fún wa?” Nígbà náà ni èmi sì wí pé, “Èmi nìyí, rán mi!”
Àwọn ènìyàn rẹ yóò tún ahoro àtijọ́ kọ́ wọn yóò sì gbé ìpìlẹ̀ àtijọ́-tijọ́ ró a ó sì pè ọ́ ní alátúnṣe ògiri tí ó ti wó àti olùmúbọ̀sípò àwọn òpópónà tí ènìyàn gbé inú rẹ̀.
Ó gbé òdodo wọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìgbàyà rẹ̀, àti àṣíborí ìgbàlà ní orí rẹ̀; ó gbé ẹ̀wù ẹ̀san wọ̀ ó sì yí ara rẹ̀ ní ìtara bí ẹ̀wù.
“Dìde, tànmọ́lẹ̀, nítorí ìmọ́lẹ̀ rẹ ti dé, ògo Olúwa sì ràdàbò ọ́.
Nítorí Sioni èmi kì yóò dákẹ́, nítorí i Jerusalẹmu èmi kì yóò sinmi ẹnu, títí tí òdodo rẹ̀ yóò fi tàn bí òwúrọ̀, àti ìgbàlà rẹ̀ bí i fìtílà tí ń jó geere.
Èmi ti fi olùṣọ́ ránṣẹ́ sórí odi rẹ ìwọ Jerusalẹmu; wọn kì yóò lè dákẹ́ tọ̀sán tòru. Ẹ̀yin tí ń ké pe Olúwa, ẹ má ṣe fúnra yín ní ìsinmi,
àti kí ẹ má ṣe fún òun pẹ̀lú ní ìsinmi títí tí yóò fi fi ìdí Jerusalẹmu múlẹ̀ tí yóò sì fi ṣe ìyìn orí ilẹ̀ ayé.
Háà! Orí ìbá jẹ́ orísun omi kí ojú mi sì jẹ́ orísun omijé! Èmi yóò sì sọkún tọ̀sán tòru nítorí ìparun àwọn ènìyàn mi.
Háà, èmi ìbá ní ni aginjù ilé àgbàwọ̀ fún àwọn arìnrìn-àjò, kí n ba à lè fi àwọn ènìyàn mi sílẹ̀ kí n sì lọ kúrò lọ́dọ̀ wọn: nítorí gbogbo wọn jẹ́ panṣágà àjọ aláìṣòótọ́ ènìyàn.
Wọ́n ti pèsè ahọ́n wọn sílẹ̀ bí ọfà láti fi pa irọ́; kì í ṣe nípa òtítọ́ ni wọ́n fi borí ní ilẹ̀ náà. Wọ́n ń lọ láti inú ẹ̀ṣẹ̀ kan sí òmíràn; wọn kò sì náání mi, ní Olúwa wí.
Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá fetísílẹ̀, Èmi yóò sọkún ní ìkọ̀kọ̀ nítorí ìgbéraga yín. Ojú mi yóò sun ẹkún kíkorò, tí omi ẹkún, yóò sì máa sàn jáde, nítorí a kó agbo Olúwa lọ ìgbèkùn.
Èmi kò sá kúrò láti máa jẹ́ olùṣọ àgùntàn rẹ, ìwọ mọ̀ wí pé èmi kò kẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ ìpọ́njú. Ohun tí ó jáde ní ètè mi jẹ́ èyí tí ó hàn sí ọ.
Ṣe kí a fi rere san búburú? Síbẹ̀ wọ́n ti gbẹ́ kòtò fún mi. Rántí pé mo dúró níwájú rẹ, mo sì sọ̀rọ̀ nítorí wọn, láti yí ìbínú rẹ kúrò lọ́dọ̀ wọn.
Ṣùgbọ́n bí mo bá sọ pé, “Èmi kì yóò dárúkọ rẹ tàbí sọ nípa orúkọ rẹ̀ mọ́, ọ̀rọ̀ rẹ̀ ń bẹ bi iná tí ń jó nínú mi nínú egungun mi, agara dá mi ní inú mi nítòótọ́ èmi kò lè ṣe é.
Nígbà náà ni Jeremiah sọ fún gbogbo àwọn aláṣẹ àti gbogbo àwọn ènìyàn wí pé: “Olúwa rán mi láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní ilé yìí àti ìlú yìí, gbogbo ohun tí ẹ ti gbọ́.
Nísinsin yìí, tún ọ̀nà rẹ ṣe àti ìṣe rẹ, kí ẹ sì gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa Ọlọ́run yín. Olúwa yóò yí ọkàn rẹ̀ padà, kò sì ní mú ohun gbogbo tí ó ti sọ jáde ní búburú ṣẹ lórí yín.