Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Religious Zeal

726 ẹsẹ · 5 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. èyí nì ni pé, kí a lè jẹ́ ìwúrí fún ara wa nípa ìgbàgbọ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan wa.

  2. Mo fẹ́ kí ẹ mọ èyí, ẹ̀yin ará mi, pé mo ti gbìyànjú lọ́pọ̀ ìgbà láti tọ̀ yín wá (ṣùgbọ́n ìdíwọ́ wà fún mi), kí èmi ki ó lè jèrè ọkàn díẹ̀ láàrín yín, gẹ́gẹ́ bí mo ti ní láàrín àwọn aláìkọlà yòókù.

  3. Nítorí mo jẹ́ ajigbèsè sí Giriki àti sí àwọn aláìgbédè tí kì í ṣe Giriki, sí àwọn ọlọ́gbọ́n àti sí àwọn aṣiwèrè.

  4. Nítorí ìdí èyí ni mo ṣe ń làkàkà láti wá sí Romu àti láti fi gbogbo agbára mi wàásù ìyìnrere Ọlọ́run sí i yín.

  5. Nínú ìjìnlẹ̀ ọkàn mi mo ní inú dídùn sí òfin Ọlọ́run;

  6. Òtítọ́ ni èmi ń sọ nínú Kristi, èmi kò ṣèké, ọkàn mi sì ń jẹ́ mi ní ẹ̀rí nínú Ẹ̀mí Mímọ́.

  7. Pé mo ní ìbìnújẹ́ púpọ̀, àti ìkáàánú ìgbà gbogbo ni ọkàn mi.

  8. Nítorí mo fẹ́rẹ lè gbàdúrà pé kí èmi tìkára mi kúrò lọ́dọ̀ Kristi nítorí àwọn ará mi, àwọn ìbátan mi nípa ti ara.

  9. Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, ìfẹ́ ọkàn àti àdúrà mi sí Ọlọ́run fún àwọn ènìyàn Israẹli ni kí wọ́n le ní ìgbàlà.

  10. Nítorí mo gba ẹ̀rí wọn jẹ́ wí pé, wọ́n ní ìtara fún Ọlọ́run, ṣùgbọ́n kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí ìmọ̀.

  11. Nítorí bí wọn kò tí mọ òdodo Ọlọ́run, tí wọ́n si ń wá ọ̀nà láti gbé òdodo ara wọn kalẹ̀, wọn kò tẹríba fún òdodo Ọlọ́run.

  12. Ẹ̀yin tí i ṣe Kèfèrí ni èmi sá à ń bá sọ̀rọ̀, níwọ̀n bí èmi ti jẹ́ aposteli àwọn Kèfèrí, mo gbé oyè mi ga

  13. bí ó le ṣe kí èmi kí ó lè mú àwọn ará mi jowú, àti kí èmi kí ó lè gba díẹ̀ là nínú wọn.

  14. Ní ti iṣẹ́ ṣíṣe, ẹ má ṣe ọ̀lẹ; ẹ máa ní ìgbóná ọkàn; ẹ máa sìn Olúwa.

  15. Síbẹ̀ mo ti fi ìgboyà kọ̀wé sí yín lórí àwọn kókó-ọ̀rọ̀ kan, bí ẹni ti ń rán yín létí àwọn kókó-ọ̀rọ̀ náà, nítorí oore-ọ̀fẹ́ tí a ti fi fún mi láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run

  16. láti jẹ́ ìránṣẹ́ Kristi Jesu láàrín àwọn Kèfèrí láti polongo ìyìnrere Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ojúṣe àlùfáà, kí àwọn Kèfèrí lè jẹ́ ẹbọ ọrẹ ìtẹ́wọ́gbà fún Ọlọ́run, èyí tí a ti fi Ẹ̀mí Mímọ́ yà sí mímọ́.

  17. Nítorí náà, mo ní ìṣògo nínú Kristi Jesu nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ mi fún Ọlọ́run.

  18. Èmi kò sá à gbọdọ̀ sọ ohun kan bí kò ṣe èyí tí Kristi ti ọwọ́ mi ṣe, ní títọ́ àwọn Kèfèrí ṣọ́nà láti ṣe ìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nípa ọ̀rọ̀ àti ìṣe mi,

  19. nípa agbára iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu, nípa agbára Ẹ̀mí Ọlọ́run, tó bẹ́ẹ̀ láti Jerusalẹmu àti yíkákiri, àní títí fi dé Illirikoni, mo ti polongo ìyìnrere Kristi ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.

  20. Ó jẹ́ èrò mi ní gbogbo ìgbà láti wàásù ìyìnrere Kristi ní ibi gbogbo tí wọn kò tí ì mọ̀ ọ́n, kí èmi kí ó má ṣe máa mọ àmọlé lórí ìpìlẹ̀ ẹlòmíràn.

  21. Ṣùgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé: “Àwọn ẹni tí a kò tí ì sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ fún yóò rí i, àti àwọn tí kò tí ì gbọ́, òye yóò sì yé.”

  22. Ìdí nìyìí tí ààyè fi há pẹ́ tó bẹ́ẹ̀ fún mi kí n tó tọ̀ yín wa.

  23. Ṣùgbọ́n báyìí tí kò tún sí ibòmíràn fún mi mọ́ láti ṣiṣẹ́ ní ẹkùn yìí, tí èmi sì ti ń pòǹgbẹ láti ọdún púpọ̀ sẹ́yìn láti bẹ́ yín wò,

  24. mo gbèrò láti ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tí mo bá lọ sí Spania. Èmi yóò rí i yín ní ọ̀nà àjò mi, àti pé ẹ ó mú mi já ọ̀nà níbẹ̀ láti ọ̀dọ̀ yín lọ, lẹ́yìn tí mo bá gbádùn ẹgbẹ́ yín fún ìgbà díẹ̀.

  25. Ṣùgbọ́n ní báyìí, mo ń lọ sí Jerusalẹmu láti sé ìránṣẹ́ fún àwọn ènìyàn mímọ́ níbẹ̀.