Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Religious Zeal

726 ẹsẹ · 5 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. láti là wọ́n lójú, kí wọn lè yípadà kúrò nínú òkùnkùn sí ìmọ́lẹ̀, àti kúrò lọ́wọ́ agbára Satani sí Ọlọ́run, kí wọn lè gba ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀, àti ogún pẹ̀lú àwọn tí a sọ di mímọ́ nípa ìgbàgbọ́ nínú mi.’

  2. “Nítorí náà, Agrippa ọba, èmi kò ṣe àìgbọ́ràn sì ìran ọ̀run náà.

  3. Ṣùgbọ́n mo kọ́kọ́ sọ fún àwọn tí ó wà ní Damasku, àti ní Jerusalẹmu, àti já gbogbo ilẹ̀ Judea, àti fún àwọn kèfèrí, kí wọn ronúpìwàdà, kí wọ́n sì yípadà sí Ọlọ́run, kí wọn máa ṣe iṣẹ́ tí ó yẹ sì ìrònúpìwàdà.

  4. Nítorí nǹkan wọ̀nyí ni àwọn Júù ṣe gbá mi mú nínú tẹmpili, tí wọ́n sì ń fẹ́ pa mí.

  5. Ṣùgbọ́n bí mo sì tí ri ìrànlọ́wọ́ gbà láti ọ́dọ̀ Ọlọ́run, mo dúró títí ó fi di òní, mo ń jẹ́rìí fún èwe àti àgbà, èmi kò sọ ohun mìíràn bí kò ṣe ohun tí àwọn wòlíì àti Mose tí wí pé, yóò ṣẹ.

  6. Pé, Kristi yóò jìyà, àti pé òun ni yóò jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ láti jíǹde kúrò nínú òkú, òun ni yóò sí kéde ìmọ́lẹ̀ fún àwọn ènìyàn àti fún àwọn aláìgbàgbọ́.”

  7. Bí ó sì ti ń sọ tẹnu rẹ̀, Festu wí ní ohùn rara pé, “Paulu! Orí rẹ dàrú; ẹ̀kọ́ àkọ́jù rẹ ti dà ọ́ ní orí rú!”

  8. Paulu dalóhùn wí pé, “Orí mi kò dàrú, Festu ọlọ́lá jùlọ; ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ òtítọ́ àti ọ̀rọ̀ òye ni èmi ń sọ jáde.

  9. Nítorí ọba mọ̀ gbogbo nǹkan wọ̀nyí, níwájú ẹni tí èmi ń sọ̀rọ̀ ni àìbẹ̀rù: nítorí mo gbàgbọ́ pé ọ̀kan nínú nǹkan wọ̀nyí kò pamọ́ fún un, nítorí tí a kò ṣe nǹkan yìí ní ìkọ̀kọ̀.

  10. Agrippa ọba, ìwọ gba àwọn wòlíì gbọ́ bí? Èmi mọ̀ pé ìwọ gbàgbọ́.”

  11. Agrippa sì wí fún Paulu pé, “Ǹjẹ́ ìwọ lérò pé ìwọ le fi àkókò díẹ̀ yìí sọ mí di Kristiani?”

  12. Paulu sì dáhùn wí pé, “Ní àkókò kúkúrú tàbí gígùn, mo gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kí ó má ṣe ìwọ nìkan, ṣùgbọ́n kí gbogbo àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ mi lónìí pẹ̀lú lè di irú ènìyàn tí èmi jẹ́ láìsí ẹ̀wọ̀n wọ̀nyí.”

  13. Àwọn fi ẹnu kò lórí ọjọ́ tí wọn yóò ṣe ìpàdé pẹ̀lú Paulu, ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ni ó tọ̀ ọ́ wa ni ilé àgbàwọ̀ rẹ̀; àwọn ẹni tí òun sọ àsọyé ọ̀rọ̀ ìjọba Ọlọ́run fún, ó ń yí wọn padà nípa ti Jesu láti inú òfin Mose àti àwọn wòlíì, láti òwúrọ̀ títí ó fi di àṣálẹ́.

  14. Àwọn ẹlòmíràn gba ohun tí ó wí gbọ́, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹlòmíràn kò sì gbà á gbọ́.

  15. Nígbà tí ohùn wọn kò ṣọ̀kan láàrín ara wọn, wọ́n túká, lẹ́yìn ìgbà tí Paulu sọ̀rọ̀ kan pé, “Ẹ̀mí Mímọ́ sọ òtítọ́ fún àwọn baba yín nígbà tí ó sọ láti ẹnu wòlíì Isaiah wí pé:

  16. “ ‘Tọ àwọn ènìyàn wọ̀nyí lọ, kí ó sì wí pé, “Ní gbígbọ́ ẹ̀yin yóò gbọ́, kì yóò sì yé e yín; à ti ní rí rí ẹ̀yin yóò rí, ẹ̀yin kì yóò sí wòye.”

  17. Nítorí ti àyà àwọn ènìyàn yìí yigbì, etí wọn sì wúwo láti fi gbọ́, ojú wọn ni wọn sì ti di. Nítorí kí wọn má ba à fi ojú wọn rí, kí wọn kí ó má ba à fi etí wọn gbọ́, àti kí wọn má ba à fi ọkàn wọn mọ̀, kí wọn kí ó má ba à yípadà, àti kí èmi má ba à mú wọn láradá.’

  18. “Ǹjẹ́ kí ẹ̀yin mọ́ èyí pé, a rán ìgbàlà Ọlọ́run sí àwọn kèfèrí wọ́n ó sì gbọ́!”

  19. Paulu sì gbé ilé àgbàwọ̀ rẹ̀ lọ́dún méjì gbáko, ó sì ń gbà gbogbo àwọn tí ó wọlé tọ̀ ọ́ wá.

  20. Ó ń wàásù ìjọba Ọlọ́run, ó ń fi ìgboyà kọ́ni ní àwọn ohun tí i ṣe ti Jesu Kristi Olúwa, ẹnìkan kò si dá a lẹ́kun.

  21. Paulu, ìránṣẹ́ Jesu Kristi, ẹni tí a ti pè láti jẹ́ aposteli, tí a sì ti yà sọ́tọ̀ láti wàásù ìyìnrere Ọlọ́run,

  22. Ní àkọ́kọ́, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nípasẹ̀ Jesu Kristi fún gbogbo yín, nítorí a ń ròyìn ìgbàgbọ́ yin káàkiri gbogbo ayé.

  23. Ọlọ́run ṣá à ni ẹlẹ́rìí mi, ẹni tí èmí ń fi gbogbo ẹ̀mí mi sìn nínú ìyìnrere Ọmọ rẹ̀, bí ó ti ṣe pé ní àìsimi ni èmí ń rántí yín nígbà gbogbo nínú àdúrà mi

  24. nínú àdúrà mi ìgbà gbogbo; mo tún ń gbàdúrà wí pé nípa oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run kí ọ̀nà ó ṣí fún mi láti wá sọ́dọ̀ yín.

  25. Nítorí èmi ń fẹ́ gidigidi láti tọ̀ yín wá, kí èmi lè fún yín ní ẹ̀bùn ẹ̀mí díẹ̀, kí a bá a le sọ yín di alágbára nínú Olúwa,