Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Psalms

896 ẹsẹ · 16 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Òun ni ó fi ìgbàlà fún àwọn ọba, ẹni tí ó gba Dafidi ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ idà ìpanilára. Lọ́wọ́ pípanirun.

  2. Gbà mí kí o sì yọ mí nínú ewu kúrò lọ́wọ́ àwọn ọmọ àjèjì tí ẹnu wọn kún fún èké, tí ọwọ́ ọ̀tún wọn jẹ́ ọwọ́ ọ̀tún èké.

  3. Kí àwọn ọmọkùnrin wa kí ó dàbí igi gbígbìn tí ó dàgbà ni ìgbà èwe wọn, àti ọmọbìnrin wa yóò dàbí òpó ilé tí a ṣe ọ̀nà sí bí àfarawé ààfin.

  4. Àká wa yóò kún pẹ̀lú gbogbo onírúurú oúnjẹ àgùntàn wa yóò pọ̀ si ní ẹgbẹ̀rún, ní ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ní oko wa:

  5. àwọn màlúù wa yóò ru ẹrù wúwo kí ó má sí ìkọlù, kí ó má sí ìkólọ sí ìgbèkùn, kí ó má sí i igbe ìpọ́njú ní ìgboro wa.

  6. Ìbùkún ni fún àwọn ènìyàn náà tí ó wà ní irú ipò bẹ́ẹ̀, ìbùkún ni fún àwọn ènìyàn náà, tí ẹni tí Ọlọ́run Olúwa ń ṣe.

  7. Ẹ fi ìyìn fún Olúwa. Ẹ fi ìyìn fún Olúwa láti ọ̀run wá, ẹ fi ìyìn fún un níbi gíga.

  8. Ẹ fi ìyìn fún un, gbogbo ẹ̀yin angẹli rẹ̀, ẹ fi ìyìn fún un, gbogbo ẹ̀yin ọmọ-ogun rẹ̀.

  9. Ẹ fi ìyìn fún un, oòrùn àti òṣùpá. Ẹ fi ìyìn fún un, gbogbo ẹ̀yin ìràwọ̀ ìmọ́lẹ̀.

  10. Ẹ fi ìyìn fún un, ẹ̀yin ọ̀run àti àwọn ọ̀run gíga àti ẹ̀yin omi tí ń bẹ ní òkè ọ̀run.

  11. Ẹ jẹ́ kí wọn kí ó yin orúkọ Olúwa nítorí ó pàṣẹ a sì dá wọn

  12. Ó fi ìdí wọn múlẹ̀ láé àti láéláé ó sì ti ṣe ìlànà kan tí kì yóò já.

  13. Ẹ yin Olúwa láti ilẹ̀ ayé wá ẹ̀yin ẹ̀dá inú òkun títóbi àti ẹ̀yin ibú òkun,

  14. mọ̀nàmọ́ná àti òjò yìnyín ìdí omi àti àwọn ìkùùkuu, ìjì líle tí ń mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ,

  15. òkè ńlá àti gbogbo òkè kéékèèké, igi eléso àti gbogbo igi kedari,

  16. àwọn ẹranko ńlá àti ẹran ọ̀sìn gbogbo ohun afàyàfà àti àwọn ẹyẹ abìyẹ́,

  17. àwọn ọba ayé àti ènìyàn ayé gbogbo àwọn ọmọ-aládé àti gbogbo àwọn onídàájọ́ ayé,

  18. ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin àwọn arúgbó àti àwọn ọmọdé.

  19. Ẹ jẹ́ kí wọn kí ó yin orúkọ Olúwa nítorí orúkọ rẹ̀ nìkan ni ó ní ọlá ògo rẹ̀ kọjá ayé àti ọ̀run

  20. Ó sì gbé ìwo kan sókè fún àwọn ènìyàn rẹ̀, ìyìn fún gbogbo ènìyàn mímọ́ rẹ̀ àní fún àwọn ọmọ Israẹli, àwọn ènìyàn tí ó súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀. Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

  21. Ẹ fi ìyìn fún Olúwa. Ẹ fi ìyìn fún Ọlọ́run ní ibi mímọ́ rẹ̀, ẹ yìn ín nínú agbára ọ̀run rẹ̀.

  22. Ẹ yìn ín fún iṣẹ́ agbára rẹ̀. Ẹ yìn ín fún títóbi rẹ̀ tí ó tayọ̀.

  23. Ẹ fi ohùn ìpè yìn ín. Ẹ fi ohun èlò orin yìn ín.

  24. Ẹ fi ohun èlò orin àti ijó yìn ín fi ohun èlò orin olókùn àti ìpè yìn ín,

  25. Ẹ yìn ín pẹ̀lú aro olóhùn òkè, ẹ yìn ín lára aro olóhùn gooro.