Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Predestination

142 ẹsẹ · 1 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Wọ́n yín Ọlọ́run, wọn sì rí ojúrere lọ́dọ̀ ènìyàn gbogbo, Olúwa sí ń yàn kún wọn lójoojúmọ́, àwọn tí à ń gbàlà.

  2. Ṣùgbọ́n báyìí ni Ọlọ́run ti ṣe ìmúṣẹ àwọn ohun tí ó ti sọtẹ́lẹ̀ láti ẹnu gbogbo àwọn wòlíì pé, Kristi rẹ̀ yóò jìyà.

  3. láti ṣe ohunkóhun tí ọwọ́ rẹ àti ìmọ̀ rẹ̀ ti pinnu ṣáájú pé yóò ṣe.

  4. Nígbà tí àwọn aláìkọlà sì gbọ́ èyí, wọ́n sì yín ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lógo: gbogbo àwọn tí a yàn sí ìyè àìnípẹ̀kun sì gbàgbọ́.

  5. Ó sì tí tipasẹ̀ ẹnìkan dá gbogbo orílẹ̀-èdè láti tẹ̀dó sí ojú àgbáyé, ó sì ti pinnu àkókò tí a yàn tẹ́lẹ̀, àti ààlà ibùgbé wọn;

  6. “Nígbà náà ni ó wí pé: ‘Ọlọ́run àwọn baba wa ti yàn ọ́ láti mọ ìfẹ́ rẹ̀, àti láti ri Ẹni òdodo náà, àti láti gbọ́ ọ̀rọ̀ láti ẹnu rẹ̀.

  7. Ẹ̀yin pẹ̀lú si wa lára àwọn tí a pè sọ́dọ̀ Jesu Kristi.

  8. Àwa sì mọ̀ pé ohun gbogbo ni ó ń ṣiṣẹ́ pọ̀ sí rere fún àwọn tí ó fẹ́ Ọlọ́run, àní fún àwọn ẹni tí a pè gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ̀.

  9. Nítorí àwọn ẹni tí ó mọ̀ tẹ́lẹ̀, ni ó sì yàn tẹ́lẹ̀ láti rí bí àwòrán ọmọ rẹ̀, kí òun lè jẹ́ àkọ́bí láàrín àwọn arákùnrin púpọ̀.

  10. Àti pé lẹ́yìn tí òun ti pè wá wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀, ó sọ wá di aláìjẹ̀bi lẹ́yìn èyí, ó fi rere Kristi kún inú ọkàn wa. Lékè gbogbo rẹ̀, ó fún wa ní ìdúró rere pẹ̀lú rẹ̀, ó sì pinu ògo rẹ̀ fún wa.

  11. Ta ni ẹni náà tí ó lè dá wa lẹ́bi, àwa ẹni tí Ọlọ́run ti yàn fún ara rẹ̀. Ǹjẹ́ Ọlọ́run yóò dá wa lẹ́bi? Bẹ́ẹ̀ kọ́! Òun ni ẹni tí ó dáríjì wá, tí ó sì fi wá sípò tí ó dára lọ́dọ̀ rẹ̀.

  12. Bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe pé, nítorí wọ́n jẹ́ irú-ọmọ Abrahamu, gbogbo wọn ni ọmọ. Ní ọ̀nà mìíràn, “Nínú Isaaki ni a ó ti pe irú-ọmọ rẹ̀.”

  13. Èyí nì ni pé, kì í ṣe àwọn ọmọ nípa ti ara ni ọmọ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ìlérí ni a kà ní irú-ọmọ.

  14. Nítorí ọ̀rọ̀ ìlérí ni èyí: “Ní ìwòyí àmọ́dún ni èmi yóò wá, Sara yóò sì ní ọmọ ọkùnrin.”

  15. Kì í sì í ṣe kìkì èyí, ṣùgbọ́n nígbà tí Rebeka pẹ̀lú lóyún fún ẹnìkan, fún Isaaki baba wa.

  16. Nítorí nígbà tí kò tí ì bí àwọn ọmọ náà, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò tí ì ṣe rere tàbí búburú—kí ìpinnu Ọlọ́run nípa ti ìyànfẹ́ kí ó lè dúró,

  17. kì í ṣe nípa ti iṣẹ́, bí kò ṣe ti ẹni tí ń peni—a ti sọ fún un pé, “Ẹ̀gbọ́n ni yóò máa sin àbúrò.”

  18. Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, “Jakọbu ni mo fẹ́ràn, ṣùgbọ́n Esau ni mo kórìíra.”

  19. Ǹjẹ́ àwa yóò ha ti wí? Àìṣòdodo ha wà lọ́dọ̀ Ọlọ́run bí? Kí a má ri!

  20. Nítorí ó wí fún Mose pé, “Èmi ó ṣàánú fún ẹni tí èmi yóò ṣàánú fún, èmi yóò sì ṣe ìyọ́nú fún ẹni tí èmi yóò ṣe ìyọ́nú fún.”

  21. Ǹjẹ́ bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ti ẹni tí ó fẹ́, kì í sì í ṣe ti ẹni tí ń sáré, bí kò ṣe ti Ọlọ́run tí ń ṣàánú.

  22. Nítorí ìwé mímọ́ wí fún Farao pé, “Nítorí èyí náà ni mo ṣe gbé ọ dìde, kí èmi kí ó le fi agbára mi hàn lára rẹ, àti kí a bá à le máa ròyìn orúkọ mi ká gbogbo ayé.”

  23. Nítorí náà ni ó ṣe ń ṣàánú fún ẹni tí ó wù ú, ẹni tí ó wù ú a sì mú ní ọkàn le.

  24. Ìwọ ó sì wí fún mi pé, “Kín ni ó ha tún bá ni wí sí? Nítorí ta ni ó ń de ìfẹ́ rẹ lọ́nà?”

  25. Bẹ́ẹ̀ kọ́, ìwọ ènìyàn, tà ni ìwọ tí ń dá Ọlọ́run lóhùn? “Ohun tí a mọ, a ha máa wí fún ẹni tí ó mọ ọ́n pé, ‘Èéṣe tí ìwọ fi mọ mi báyìí?’ ”