Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Miracles

338 ẹsẹ · 37 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Nígbà tí ó sì wí bẹ́ẹ̀ tan, ó kígbe lóhùn rara pé, “Lasaru, jáde wá.”

  2. Ẹni tí ó kú náà sì jáde wá, tí a fi aṣọ òkú dì tọwọ́ tẹsẹ̀ a sì fi gèlè dì í lójú. Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ tú u, ẹ sì jẹ́ kí ó máa lọ!”

  3. Nítorí náà ni ọ̀pọ̀ àwọn Júù tí ó wá sọ́dọ̀ Maria, tí wọ́n rí ohun tí Jesu ṣe, ṣe gbà á gbọ́.

  4. Nígbà náà ni àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisi pe ìgbìmọ̀ jọ. Wọ́n sì wí pé, “Kín ni yóò jẹ àṣeyọrí wa? Nítorí ọkùnrin yìí ń ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ àmì.

  5. Ṣùgbọ́n àwọn olórí àlùfáà gbìmọ̀ kí wọn lè pa Lasaru pẹ̀lú,

  6. nítorí pé nípasẹ̀ rẹ̀ ni ọ̀pọ̀ nínú àwọn Júù jáde lọ, wọ́n sì gbà Jesu gbọ́.

  7. Nítorí èyí ni ìjọ ènìyàn sì ṣe lọ pàdé rẹ̀, nítorí tí wọ́n gbọ́ pé ó ti ṣe iṣẹ́ àmì yìí.

  8. Ṣùgbọ́n bí ó ti ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ àmì tó báyìí lójú wọn, wọn kò gbà á gbọ́.

  9. Lóòótọ́ lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́, iṣẹ́ tí èmi ń ṣe ni òun yóò ṣe pẹ̀lú; iṣẹ́ tí ó tóbi ju wọ̀nyí lọ ni yóò sì ṣe; nítorí tí èmi ń lọ sọ́dọ̀ Baba.

  10. Ìbá ṣe pé èmi kò ti ṣe iṣẹ́ wọ̀n-ọn-nì láàrín wọn tí ẹlòmíràn kò ṣe rí, wọn kì bá tí ní ẹ̀ṣẹ̀, ṣùgbọ́n nísinsin yìí wọ́n sì rí, wọ́n sì kórìíra èmi àti Baba mi.

  11. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ àmì mìíràn ni Jesu ṣe níwájú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, tí a kò kọ sínú ìwé yìí.

  12. Ṣùgbọ́n wọ̀nyí ni a kọ, kí ẹ̀yin lè gbàgbọ́ pé Jesu ní í ṣe Kristi náà, Ọmọ Ọlọ́run, àti pé nípa gbígbàgbọ́, kí ẹ̀yin lè ní ìyè ní orúkọ rẹ̀.

  13. “Ẹ̀yin ènìyàn Israẹli, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí; Jesu tí Nasareti, ọkùnrin tí a mọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá nípa iṣẹ́ agbára àti tí ìyanu, àti àmì ti Ọlọ́run ti ọwọ́ rẹ̀ ṣe láàrín yín, bí ẹ̀yin tìkára yín ti mọ̀ pẹ̀lú.

  14. Ní ọjọ́ kan Peteru àti Johanu jùmọ̀ ń gòkè lọ sí tẹmpili ní wákàtí àdúrà; tí í ṣe wákàtí mẹ́ta ọ̀sán.

  15. Wọn sì gbé ọkùnrin kan ti ó yarọ láti inú ìyá rẹ̀ wá, tí wọ́n máa ń gbé kalẹ̀ lójoojúmọ́ ní ẹnu-ọ̀nà tẹmpili ti a ń pè ni Dáradára, láti máa ṣagbe lọ́wọ́ àwọn tí ń wọ inú tẹmpili lọ.

  16. Nígbà tí ó rí Peteru àti Johanu bí wọn tí fẹ́ wọ inú tẹmpili, ó ṣagbe.

  17. Peteru sì tẹjúmọ́ ọn, pẹ̀lú Johanu, ó ní “Wò wá!”

  18. Ó sì fiyèsí wọn, ó ń retí láti rí nǹkan láti gbà lọ́wọ́ wọn.

  19. Peteru wí pé, “Wúrà àti fàdákà èmi kò ní, ṣùgbọ́n ohun tí mo ní èyí náà ni mo fi fún ọ. Ní orúkọ Jesu Kristi ti Nasareti, dìde kí o sì máa rìn.”

  20. Ó sì fà á lọ́wọ́ ọ̀tún, ó sì gbé dìde; lójúkan náà ẹsẹ̀ rẹ̀ àti egungun kókósẹ̀ rẹ̀ sì mókun.

  21. Ó sì ń fò sókè, ó dúró, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí rìn, ó sì bá wọn wọ inú tẹmpili lọ, ó ń rìn, ó sì ń fò, ó sì yín Ọlọ́run.

  22. Gbogbo ènìyàn sì rí i, ó ń rìn, ó sì yin Ọlọ́run,

  23. Wọn sì mọ̀ pé òun ni ó ti jókòó tí ń ṣagbe ní ẹnu-ọ̀nà Dáradára ti tẹmpili náà; hà, sì ṣe wọn, ẹnu sì yà wọn gidigidi sí ohun tí ó ṣe lára rẹ̀.

  24. Nígbà tí Peteru sì rí i, ó dáhùn, ó wí fún àwọn ènìyàn pé, “Ẹ̀yin ènìyàn Israẹli, èéṣe tí háà fi ń ṣe yín sí èyí? Tàbí èéṣe ti ẹ̀yin fi tẹjúmọ́ wa, bí ẹni pé agbára tàbí ìwà mímọ́ wa ni àwa fi ṣe é ti ọkùnrin yìí fi ń rìn?

  25. Nípa ìgbàgbọ́ nínú orúkọ Jesu, òun ni ó mú ọkùnrin yìí láradá, ẹni tí ẹ̀yin rí, tí ẹ sì mọ̀. Orúkọ Jesu àti ìgbàgbọ́ tí ó wá nípa rẹ̀ ni ó fún un ní ìlera pípé ṣáṣá yìí ni ojú gbogbo yín.