Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Miracles

338 ẹsẹ · 37 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Nígbàkígbà ni ó sì máa ń gbé e sínú iná àti sínú omi, láti pa á run, ṣùgbọ́n bí ìwọ bá lè ṣe ohunkóhun, ṣàánú fún wa, kí o sì ràn wá lọ́wọ́.

  2. “Jesu sì wí fún un pé, ‘Bí ìwọ bá le gbàgbọ́: ohun gbogbo ni ó ṣe é ṣe fún ẹni tí ó bá gbàgbọ́.’ ”

  3. Lójúkan náà baba ọmọ náà kígbe ní ohùn rara, ó sì wí pé, “Olúwa, mo gbàgbọ́, ran àìgbàgbọ́ mi lọ́wọ́.”

  4. Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, bí wọ́n ti kúrò ní Betani, ebi ń pa Jesu.

  5. Ó rí igi ọ̀pọ̀tọ́ kan lọ́ọ̀ọ́kán tí ewé kún orí rẹ̀. Nígbà náà, ó lọ sí ìdí rẹ̀ láti wò ó bóyá ó léso tàbí kò léso. Nígbà tí ó dé ibẹ̀, ewé lásán ni ó rí, kò rí èso lórí rẹ̀. Nítorí pé àkókò náà kì í ṣe àkókò tí igi ọ̀pọ̀tọ́ máa ń so.

  6. Lẹ́yìn náà, Jesu pàṣẹ fún igi náà pé, “Kí ẹnikẹ́ni má ṣe jẹ èso lórí rẹ mọ́ títí láé.” Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ gbọ́ nígbà tí ó wí bẹ́ẹ̀.

  7. Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, bí wọ́n ti ń kọjá lọ, wọ́n rí igi ọ̀pọ̀tọ́ tí Jesu fi bú. Wọ́n rí i pé ó ti gbẹ tigbòǹgbò tigbòǹgbò.

  8. Peteru rántí pé Jesu ti bá igi náà wí. Nígbà náà ni ó sọ fún Jesu pé, “Rabbi, wò ó! Igi ọ̀pọ̀tọ́ tí ìwọ fi bú ti gbẹ!”

  9. Jesu sì dáhùn pé, “Ẹ ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run.

  10. Lóòótọ́ ni mò wí fún un yín, bí ẹnikẹ́ni bá wí fún òkè ‘Ṣídìí, gbé ara rẹ sọ sínú Òkun,’ ti kò sì ṣe iyèméjì nínú ọkàn rẹ̀ ṣùgbọ́n tí ó gbàgbọ́ pé ohun tí òun wí yóò ṣẹ, yóò rí bẹ́ẹ̀ fún un.

  11. Torí náà, mo wí fún yín ohunkóhun tí ẹ bá béèrè fún nínú àdúrà, ẹ ní ìgbàgbọ́ pé, ó tí tẹ̀ yín lọ́wọ́, yóò sì jẹ́ tiyín.

  12. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì jáde lọ. Wọ́n ń wàásù káàkiri. Ọlọ́run sì wà pẹ̀lú wọn, ó sì ń fi ìdí ọ̀rọ̀ rẹ̀ múlẹ̀ nípa àwọn àmì tí ó tẹ̀lé e.

  13. Èṣù sì wí fún un pé, “Bí ìwọ bá ṣe Ọmọ Ọlọ́run, pàṣẹ fún òkúta yìí kí ó di àkàrà.”

  14. Èṣù sì wí fún un pé, “Ìwọ ni èmi ó fi gbogbo agbára yìí àti ògo wọn fún: nítorí á sá ti fi fún mi. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì wù mí, èmi a fi í fún.

  15. Bí ó sì ti dákẹ́ ọ̀rọ̀ sísọ, ó wí fún Simoni pé, “Tì í sí ibú, kí o sì ju àwọ̀n yín sí ìsàlẹ̀ fún àkópọ̀.”

  16. Simoni sì dáhùn ó sì wí fún un pé, “Olùkọ́ni, gbogbo òru ni àwa fi ṣiṣẹ́, àwa kò sì mú nǹkan kan: ṣùgbọ́n nítorí ọ̀rọ̀ rẹ èmi ó ju àwọ̀n náà sí ìsàlẹ̀.”

  17. Nígbà tí wọ́n sì ti ṣe èyí, wọ́n kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹja: àwọ̀n wọn sì ya.

  18. Wọ́n sì pe àwọn ẹgbẹ́ wọn, tí ó wà nínú ọkọ̀ kejì, kí wọn kí ó wá ràn wọ́n lọ́wọ́. Wọ́n sì wá, wọ́n kó ẹja ọkọ̀ méjèèjì sì kún, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í rì.

  19. Nígbà tí Simoni Peteru sì rí i, ó wólẹ̀ lẹ́bàá eékún Jesu, ó wí pé, “Lọ kúrò lọ́dọ̀ mi Olúwa; nítorí ẹlẹ́ṣẹ̀ ni mí.”

  20. Ẹnu sì yà wọ́n, àti gbogbo àwọn tí ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀, fún àkópọ̀ ẹja tí wọ́n kó,

  21. bẹ́ẹ̀ ni Jakọbu àti Johanu àwọn ọmọ Sebede, tí ń ṣe alábákẹ́gbẹ́ Simoni. Jesu sì wí fún Simoni pé, “Má bẹ̀rù; láti ìsinsin yìí lọ ìwọ ó máa mú ènìyàn.”

  22. Nígbà tí wọ́n sì ti mú ọkọ̀ wọn dé ilẹ̀, wọ́n fi gbogbo rẹ̀ sílẹ̀, wọ́n sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn lọ.

  23. Ẹnu sì ya gbogbo wọn, wọ́n sì yin Ọlọ́run lógo, ẹ̀rù sì bà wọ́n, wọ́n ń wí pé, “Àwa rí ohun ìyanu lónìí.”

  24. Nígbà tí àwọn ọkùnrin náà sì dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n wí pé, “Johanu onítẹ̀bọmi rán wa sọ́dọ̀ rẹ, pé, ‘Ìwọ ni ẹni tí ń bọ̀, tàbí kí a máa retí ẹlòmíràn?’ ”

  25. Ní wákàtí náà, ó sì ṣe ìmúláradá ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn nínú àìsàn, àti ààrùn, àti ẹ̀mí búburú; ó sì fi ìríran fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn afọ́jú.