Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Ministers

201 ẹsẹ · 118 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Nígbà náà ni ó wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Lóòótọ́ ni ìkórè pọ̀ ṣùgbọ́n àwọn alágbàṣe kò tó nǹkan.

  2. Nítorí náà, ẹ gbàdúrà sí Olúwa ìkórè kí ó rán àwọn alágbàṣe sínú ìkórè rẹ̀.”

  3. Ohun tí mo bá wí fún yín ní òkùnkùn, òun ni kí ẹ sọ ní ìmọ́lẹ̀. Èyí tí mo sọ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ sì etí yín ni kí ẹ kéde rẹ́ lórí òrùlé.

  4. Ẹ má ṣe bẹ̀rù àwọn tí ó le pa ara nìkan; ṣùgbọ́n tí wọn kò lè pa ẹ̀mí. Ẹ bẹ̀rù Ẹni tí ó le pa ẹ̀mí àti ara run ní ọ̀run àpáàdì.

  5. ẹ fi wọ́n sílẹ̀; afọ́jú tí ń fi ọ̀nà han afọ́jú ni wọ́n. Bí afọ́jú bá sì ń fi ọ̀nà han afọ́jú, àwọn méjèèjì ni yóò jìn sí kòtò.”

  6. nítorí náà, ẹ gbọdọ̀ gbọ́ tiwọn, kí ẹ sì ṣe ohun gbogbo tí wọ́n bá sọ fún yín. Ṣùgbọ́n ẹ má ṣe ohun tí wọ́n ṣe, nítorí àwọn pàápàá kì í ṣe ohun tí wọn kọ́ yín láti ṣe.

  7. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, èmi yóò sì fi irú ẹni bẹ́ẹ̀ ṣe alákòóso gbogbo ohun tí mo ní.

  8. Ṣùgbọ́n bí ọmọ ọ̀dọ̀ náà bá jẹ́ ènìyàn búburú náà bá wí ní ọkàn rẹ̀ pé, ‘Olúwa mi kì yóò tètè dé.’

  9. Tí ó sì bẹ̀rẹ̀ si í fi ìyà jẹ́ àwọn ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, tí ó ń jẹ, tí ó sì ń mu àmupara.

  10. Nígbà náà ni olúwa ọmọ ọ̀dọ̀ yóò wá ní ọjọ́ àti wákàtí tí kò retí.

  11. Yóò sì jẹ ẹ́ ní ìyà gidigidi, yóò sì rán an sí ibùgbé àwọn àgàbàgebè, níbẹ̀ ni ẹkún àti ìpayínkeke yóò wà.

  12. Nígbà náà ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mọ́kànlá náà lọ sí Galili ní orí òkè níbi tí Jesu sọ pé wọn yóò ti rí òun.

  13. Nígbà tí wọ́n sì rí i, wọ́n foríbalẹ̀ fún un. Ṣùgbọ́n díẹ̀ nínú wọn ṣe iyèméjì bóyá Jesu ni tàbí òun kọ́.

  14. Nígbà náà ni Jesu wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Gbogbo agbára ni ọ̀run àti ní ayé ni a ti fi fún mi.

  15. Nítorí náà, ẹ lọ, ẹ sọ wọ́n di ọmọ-ẹ̀yìn orílẹ̀-èdè gbogbo, ẹ máa bamitiisi wọn ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti Ẹ̀mí Mímọ́.

  16. Ẹni tí ó bá gbàgbọ́, tí a sì tẹ̀bọmi yóò là. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá kọ̀ tí kò gbàgbọ́ yóò jẹ̀bi.

  17. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì jáde lọ. Wọ́n ń wàásù káàkiri. Ọlọ́run sì wà pẹ̀lú wọn, ó sì ń fi ìdí ọ̀rọ̀ rẹ̀ múlẹ̀ nípa àwọn àmì tí ó tẹ̀lé e.

  18. Jesu sì wí fún un pé, “Jẹ́ kí àwọn òkú máa sìnkú ara wọn, ṣùgbọ́n ìwọ lọ kí o sì máa wàásù ìjọba Ọlọ́run.”

  19. Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Olúwa sì yan méjìléláàádọ́rin ọmọ-ẹ̀yìn mìíràn pẹ̀lú, ó sì rán wọn ní méjì méjì lọ ṣáájú rẹ̀, sí gbogbo ìlú àti ibi tí òun tìkára rẹ̀ yóò sì dé.

  20. “Ẹni tí ó bá gbọ́ tiyín, ó gbọ́ tèmi. Ẹni tí ó bá sì kọ̀ yín, ó kọ̀ mi. Ẹni tí ó bá sì kọ̀ mi, ó kọ ẹni tí ó rán mi.”

  21. Àwọn àádọ́rin náà sì fi ayọ̀ padà, wí pé, “Olúwa, àwọn ẹ̀mí èṣù tilẹ̀ foríbalẹ̀ fún wa ní orúkọ rẹ.”

  22. Ṣùgbọ́n mo ti gbàdúrà fún ọ, kí ìgbàgbọ́ rẹ má ṣe yẹ̀; àti ìwọ nígbà tí ìwọ bá sì padà bọ̀ sípò, mú àwọn arákùnrin rẹ lọ́kàn le.”

  23. Ṣùgbọ́n alágbàṣe, tí kì í ṣe olùṣọ́-àgùntàn, ẹni tí àwọn àgùntàn kì í ṣe tirẹ̀, ó rí ìkookò ń bọ̀, ó sì fi àgùntàn sílẹ̀, ó sì fọ́n wọn ká kiri.

  24. Ǹjẹ́ lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n jẹun òwúrọ̀ tan, Jesu wí fún Simoni Peteru pé, “Simoni, ọmọ Jona, ìwọ fẹ́ mi ju àwọn wọ̀nyí lọ bí?” Ó sì wí fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa; ìwọ mọ̀ pé, mo fẹ́ràn rẹ.” Ó wí fún un pé, “Máa bọ́ àwọn àgùntàn mi.”

  25. Ó tún wí fún un nígbà kejì pé, “Simoni ọmọ Jona, ìwọ fẹ́ mi bí?” Ó wí fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa; ìwọ mọ̀ pé, mo fẹ́ràn rẹ.” Ó wí fún un pé, “Máa bọ́ àwọn àgùntàn mi.”