Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Lasciviousness

68 ẹsẹ · 1 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ọkọ ọ̀ mi ò sí nílé; ó ti lọ sí ìrìnàjò jíjìn.

  2. Ó mú owó púpọ̀ lọ́wọ́ kò sì ní darí dé kí ó tó di ọ̀sán.”

  3. Pẹ̀lú ọ̀rọ̀ dídùn ó sì í lọ́nà; ó tàn án jẹ pẹ̀lú ẹnu dídùn.

  4. Òun sì tọ̀ ọ́ lọ lẹsẹ̀ kan náà, bí i màlúù tí ń lọ sí ibi pípa, tàbí bí àgbọ̀nrín tí ń lọ sí ibi okùn ìso.

  5. Títí tí ọ̀kọ̀ fi gún un ní ẹ̀dọ̀, bí ẹyẹ ṣe ń fẹ́ wọ inú okùn, láìmọ̀ pé yóò gba ẹ̀mí òun.

  6. Nítorí náà báyìí ẹ̀yin ọmọ mi, tẹ́tí sí mi fọkàn sí nǹkan tí mo sọ.

  7. Má ṣe jẹ́ kí ọkàn rẹ kí ó yà sí ọ̀nà rẹ̀, tàbí kí ó rìn lọ sí ipa ọ̀nà rẹ̀.

  8. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn tí ó ti fà lulẹ̀. Ogunlọ́gọ̀ àwọn alágbára ni ó ti pa.

  9. Ilé e rẹ̀ ni ọ̀nà tààrà sí isà òkú, tí ó lọ tààrà sí àgbàlá ikú.

  10. Òmùgọ̀ obìnrin jẹ́ aláriwo; ó jẹ́ aláìlẹ́kọ̀ọ́ àti aláìní ìmọ̀.

  11. Ó jókòó ní ẹnu-ọ̀nà ilé rẹ̀ lórí ìjókòó níbi tí ó ga jù láàrín ìlú,

  12. ó ń pe àwọn tí ó ń kọjá lọ, tí wọn ń lọ tààrà ní ọ̀nà wọn.

  13. “Jẹ́ kí gbogbo ẹni tí ó jẹ́ aláìlóye súnmọ́ bí!” Ni ó wí fún ẹni tí òye kù díẹ̀ ká à tó fún.

  14. “Omi tí a jí mu dùn oúnjẹ tí a jẹ ní ìkọ̀kọ̀ a máa ládùn!”

  15. Ṣùgbọ́n wọn ò funra pé àwọn òkú wà níbẹ̀, pé àwọn àlejò rẹ̀ wà ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀ isà òkú.

  16. “Àwọn nǹkan mẹ́ta wà tí ó jẹ́ ìyàlẹ́nu fún mi, mẹ́rin tí kò yé mi,

  17. ipa ẹyẹ idì ní òfúrufú ipa ejò lórí àpáta ipa ọkọ̀ ojú omi lójú agbami Òkun àti ipa ọ̀nà ọkùnrin tí ó mú wúńdíá lọ́wọ́.

  18. “Èyí ni ọ̀nà alágbèrè obìnrin ó jẹun ó sì nu ẹnu rẹ̀ ó sì wí pé, ‘N kò ṣe ohunkóhun tí kò tọ́.’

  19. Nítorí pé láti inú ọkàn ènìyàn ni àwọn èrò búburú wọ̀nyí ti ń jáde wá: àgbèrè, olè, ìpànìyàn, panṣágà,

  20. ọ̀kánjúwà, odì yíyàn, ìtànjẹ, ìmọ-tara-ẹni, ìlara, ọ̀rọ̀ ẹ̀yìn, ìgbéraga, òmùgọ̀.

  21. Gbogbo àwọn nǹkan búburú wọ̀nyí ń tí inú wá, àwọn ló sì ń sọ yín di aláìmọ́.”

  22. Níwọ́n bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé wọ́n pe ara wọn ní ọlọ́gbọ́n ṣùgbọ́n wọ́n di òmùgọ̀ pátápátá,

  23. wọ́n sì yí ògo Ọlọ́run tí kì í díbàjẹ́ sí àwọn àwòrán ère bí i ti ènìyàn tí í díbàjẹ́ àti ti ẹyẹ, àti ti ẹranko ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́rin àti ti ẹranko afàyàfà.

  24. Nítorí náà Ọlọ́run fà wọ́n lé ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ọkàn wọn lọ́wọ́ láti máa ṣe ohun ìríra pẹ̀lú ara wọn èyí tí kò tọ́.

  25. Wọ́n yí òtítọ́ Ọlọ́run sí èké, wọ́n sì ń foríbalẹ̀ láti máa sin ẹ̀dá dípò ẹlẹ́dàá—ẹni tí ìyìn tọ́ sí láéláé. Àmín.