Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Holy Spirit

145 ẹsẹ · 2 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ṣùgbọ́n ó sọ èyí ní ti ẹ̀mí, tí àwọn tí ó gbà á gbọ́ ń bọ̀ wá gbà, nítorí a kò tí ì fi Èmí Mímọ́ fún ni; nítorí tí a kò tí ì ṣe Jesu lógo.

  2. Nígbà náà èmi yóò wá béèrè lọ́wọ́ Baba. Òun yóò sì fún yín ní olùtùnú mìíràn. Olùtùnú náà yóò máa bá yín gbé títí láé.

  3. Òun ni Ẹ̀mí òtítọ́. Ayé kò le gbà á. Nítorí ayé kò mọ̀ ọ́n, bẹ́ẹ̀ ni kò rí i rí. Ẹ̀yin mọ̀ ọn nítorí láti ìgbà tí ẹ ti wà pẹ̀lú mí. Òun náà ti wà pẹ̀lú yín. Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ kan yóò wọ inú yín láti máa gbé ibẹ̀.

  4. Ṣùgbọ́n òtítọ́ ni èmi ń sọ fún yín; àǹfààní ni yóò jẹ́ fún yín bí èmi bá lọ, nítorí bí èmi kò bá lọ, Olùtùnú kì yóò tọ̀ yín wá; ṣùgbọ́n bí mo bá lọ, èmi ó rán an sí yín.

  5. Nígbà tí òun bá sì dé, yóò fi òye yé aráyé ní ti ẹ̀ṣẹ̀, àti ní ti òdodo, àti ní ti ìdájọ́,

  6. ní ti ẹ̀ṣẹ̀, nítorí tí wọn kò gbà mí gbọ́;

  7. ní ti òdodo, nítorí tí èmi ń lọ sọ́dọ̀ Baba, ẹ̀yin kò sì mọ̀ mí.

  8. Ní ti ìdájọ́, nítorí tí a ti ṣe ìdájọ́ ọmọ-aládé ayé yìí.

  9. “Mo ní ohun púpọ̀ láti sọ fún yín pẹ̀lú, ṣùgbọ́n ẹ kò lè gbà wọ́n nísinsin yìí.

  10. Ṣùgbọ́n nígbà tí òun, àní Ẹ̀mí òtítọ́ náà bá dé, yóò tọ́ yín sí ọ̀nà òtítọ́ gbogbo, nítorí kì yóò sọ ti ara rẹ̀; ṣùgbọ́n ohunkóhun tí ó bá gbọ́, òun ni yóò máa sọ, yóò sì sọ ohun tí ń bọ̀ fún yín.

  11. Òun ó máa yìn mí lógo, nítorí tí yóò gbà nínú ti èmi, yóò sì máa sọ ọ́ fún yín.

  12. Lójijì ìró sì ti ọ̀run wá, gẹ́gẹ́ bí ìró ẹ̀fúùfù líle, ó sì kún gbogbo ilé níbi tí wọ́n gbé jókòó.

  13. Ẹ̀là ahọ́n bí i iná sì yọ sí wọn, ó pín, ó sì bà lé olúkúlùkù wọn.

  14. Gbogbo wọn sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, wọn sì bẹ̀rẹ̀ sí í fi èdè mìíràn sọ̀rọ̀, gẹ́gẹ́ bí Ẹ̀mí ti fi fún wọn ni ohùn.

  15. Ṣùgbọ́n Peteru wí pé, “Anania, èéṣe ti Satani fi kún ọkàn rẹ láti ṣèké sí Ẹ̀mí Mímọ́, tí ìwọ sì fi yan apá kan pamọ́ nínú owó ilẹ̀ náà?

  16. Nígbà tí ó wà níbẹ̀ tìrẹ kọ́ ní í ṣe? Nígbà tí a sì ta á tan, kò ha wà ní ìkáwọ́ rẹ̀? Èéha ti ṣe tí ìwọ fi rò nǹkan yìí lọ́kàn rẹ? Ènìyàn kọ́ ni ìwọ ṣèké sí bí kò ṣe sí Ọlọ́run?”

  17. Nígbà tí wọ́n sì lọ, wọ́n gbàdúrà fún wọn, kí wọn bá à lè gba Ẹ̀mí Mímọ́,

  18. nítorí títí ó fi di ìgbà náà Ẹ̀mí Mímọ́ kò tí ì bà lé ẹnikẹ́ni nínú wọn; kìkì pè a bamitiisi wọn lórúkọ Jesu Olúwa ni.

  19. Nígbà náà ni Peteru àti Johanu gbé ọwọ́ lé wọn, wọn sí gba Ẹ̀mí Mímọ́.

  20. Nígbà tí Simoni rí i pé nípa gbígbé ọwọ́ lé ni ni a ń ti ọwọ́ àwọn aposteli fi Ẹ̀mí Mímọ́ fún ni, ó fi owó lọ̀ wọ́n,

  21. ó wí pé, “Ẹ fún èmi náà ni àṣẹ yìí pẹ̀lú, kí ẹnikẹ́ni tí èmi bá gbé ọwọ́ lé lè gba Ẹ̀mí Mímọ́.”

  22. Ṣùgbọ́n Peteru dá a lóhùn wí pé, “Kí owó rẹ ṣègbé pẹ̀lú rẹ, nítorí tí ìwọ rò láti fi owó ra ẹ̀bùn Ọlọ́run!

  23. Ìwọ kò ni ipa tàbí ìpín nínú ọ̀ràn yìí, nítorí ọkàn rẹ kò ṣe déédé níwájú Ọlọ́run.

  24. Nítorí náà ronúpìwàdà ìwà búburú rẹ yìí, kí ó sì gbàdúrà sọ́dọ̀ Ọlọ́run bóyá yóò dárí ète ọkàn rẹ jì ọ́.

  25. Bí Peteru sì ti ń ronú ìran náà, Ẹ̀mí wí fún un pé, “Wò ó, àwọn ọkùnrin mẹ́ta ń wá ọ.