Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Betrayal

31 ẹsẹ · 4 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Àwọn ayọ́lẹ̀wò náà rí ọkùnrin kan tí ń jáde láti inú ìlú náà wá, wọ́n sì wí fún un pé, “Fi ọ̀nà àtiwọ ìlú yìí hàn wá, àwa ó sì dá ẹ̀mí rẹ sí, a ó sì ṣe àánú fún ọ.”

  2. Ó sì fi ọ̀nà ìlú náà hàn wọ́n, wọ́n sì fi ojú idà kọlu ìlú náà, ṣùgbọ́n wọ́n dá ọkùnrin náà àti gbogbo ìdílé rẹ̀ si.

  3. Dafidi sì wá sí Nobu sọ́dọ̀ Ahimeleki àlùfáà, Ahimeleki sì bẹ̀rù láti pàdé Dafidi, ó sì wí fún un pé, “Èéha ti rí tí o fi ṣe ìwọ nìkan, àti tí kò sì sí ọkùnrin kan tí ó pẹ̀lú rẹ?”

  4. Dafidi sì wí fún Ahimeleki àlùfáà pé, “Ọba pàṣẹ iṣẹ́ kan fún mi, ó sì wí fún mi pé, ‘Má ṣe jẹ́ kí ẹnìkan mọ ìdí iṣẹ́ náà ti mo rán ọ, àti èyí tí èmi ti pàṣẹ fún ọ.’ Èmi sì yan àwọn ìránṣẹ́ mi sí ibí báyìí.

  5. Ǹjẹ́ kín ni ó wà ní ọwọ́ rẹ̀? Fún mi ni ìṣù àkàrà márùn-ún tàbí ohunkóhun tí o bá rí.”

  6. Àlùfáà náà sí dá Dafidi lóhùn ó sì wí pé, “Kò sí àkàrà mìíràn lọ́wọ́ mi bí kò ṣe àkàrà mímọ́. Kìkì pé bi àwọn ọmọkùnrin bá ti pa ara wọn mọ́ kúrò lọ́dọ̀ obìnrin!”

  7. Dafidi sì dá àlùfáà náà lóhùn, ó sì wí fún un pé, “Nítòótọ́ ni a tí ń pa ara wá mọ́ kúrò lọ́dọ̀ obìnrin láti ìwọ̀n ọjọ́ mẹ́ta wá, tí èmí ti jáde. Gbogbo nǹkan àwọn ọmọkùnrin náà ni ó mọ́, àti àkàrà náà sì wá dàbí àkàrà mìíràn, pàápàá nígbà tí ó jẹ́ pé òmíràn wà tí a yà sí mímọ́ lónìí nínú ohun èlò náà!”

  8. Bẹ́ẹ̀ ni àlùfáà náà sì fi àkàrà mímọ́ fún un; nítorí tí kò sí àkàrà mìíràn níbẹ̀ bí kò ṣe àkàrà ìfihàn tí a ti kó kúrò níwájú Olúwa, láti fi àkàrà gbígbóná síbẹ̀ ní ọjọ́ tí a kó o kúrò.

  9. Ọkùnrin kan nínú àwọn ìránṣẹ́ Saulu sì ń bẹ níbẹ̀ lọ́jọ́ náà, tí a tí dádúró síwájú Olúwa; orúkọ rẹ̀ sì ń jẹ́ Doegi, ará Edomu olórí nínú àwọn darandaran Saulu.

  10. Dafidi sì tún wí fún Ahimeleki pé, “Kò sí ọ̀kọ̀ tàbí idà lọ́wọ́ rẹ níhìn-ín? Nítorí tí èmi kò mú idà mi, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò mú nǹkan ìjà mi lọ́wọ́, nítorí pé iṣẹ́ ọba náà jẹ́ iṣẹ́ ìkánjú.”

  11. Àlùfáà náà sì wí pé, “Idà Goliati ará Filistini tí ó pa ní àfonífojì Ela ní ń bẹ, wò ó, a fi aṣọ kan wé e lẹ́yìn efodu; bí ìwọ yóò bá mú èyí, mú un; kò sì sí òmíràn níhìn-ín mọ́ bí kò ṣe ọ̀kan náà.” Dafidi sì wí pé, “Kò sí èyí tí ó dàbí rẹ̀ fún mi.”

  12. Dafidi sì dìde, o sì sá ni ọjọ́ náà níwájú Saulu, ó sì lọ sọ́dọ̀ Akiṣi, ọba Gati.

  13. Doegi ará Edomu tí a fi jẹ olórí àwọn ìránṣẹ́ Saulu, sì dáhùn wí pé, “Èmi rí ọmọ Jese, ó wá sí Nobu, sọ́dọ̀ Ahimeleki ọmọ Ahitubu.

  14. Òun sì béèrè lọ́dọ̀ Olúwa fún un, ó sì fún un ní oúnjẹ, ó sí fún un ni idà Goliati ará Filistini.”

  15. Nígbà náà ni ọ̀kan nínú àwọn aposteli méjìlá ti à ń pè ní Judasi Iskariotu lọ sọ́dọ̀ àwọn olórí àlùfáà.

  16. Òun sì béèrè pé, “Kí ni ẹ̀yin yóò san fún mi bí mo bá fi Jesu lé yín lọ́wọ́?” Wọ́n sì fún un ní ọgbọ́n owó fàdákà. Ó sì gbà á.

  17. Láti ìgbà náà lọ ni Judasi ti bẹ̀rẹ̀ sí i wá ọ̀nà láti fà á lé wọn lọ́wọ́.

  18. Nígbà náà ni ó tọ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wá, ó wí pé, “Àbí ẹ̀yin sì ń sùn síbẹ̀, ti ẹ sì ń sinmi? Wò ó wákàtí náà tí dé ti a ó fi Ọmọ Ènìyàn lé àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ lọ́wọ́.

  19. Ẹ dìde! Ẹ jẹ́ kí a máa lọ! Ẹ wò ó, ẹni tí yóò fi mi hàn ń bọ̀ wá!”

  20. Bí ó ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, Judasi, ọ̀kan nínú àwọn méjìlá dé pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ènìyàn pẹ̀lú idà àti kùmọ̀ lọ́wọ́ wọn, wọ́n ti ọ̀dọ̀ àwọn olórí àlùfáà àti àgbàgbà Júù wá.

  21. Ẹni tí ó sì fi í hàn ti fi àmì fún wọn, pé, “Ẹnikẹ́ni tí mo bá fi ẹnu kò ní ẹnu, òun náà ni; ẹ mú un.”

  22. Nísinsin yìí, Judasi wá tààrà sọ́dọ̀ Jesu, ó wí pé, “Àlàáfíà, Rabbi!” Ó fi ẹnu kò ó ní ẹnu.

  23. Jesu wí pé, “Ọ̀rẹ́, kí ni nǹkan tí ìwọ bá wá.” Àwọn ìyókù sì sún síwájú wọ́n sì mú Jesu.

  24. Nígbà náà ni Judasi Iskariotu, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn olórí àlùfáà, láti ṣètò bí yóò ti fi Jesu lé wọn lọ́wọ́.

  25. Inú wọn dùn láti gbọ́ èyí, wọ́n sì yọ̀, wọ́n sì ṣe ìlérí láti fún un ní owó. Nítorí náà ó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣọ àkókò tí ó rọrùn tí òun yóò fi Jesu lé wọn lọ́wọ́.