Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Afflictions and Adversities

526 ẹsẹ · 5 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Isaaki sì kọ́ pẹpẹ kan síbẹ̀, ó sì pe orúkọ Olúwa. Níbẹ̀ ni ó pàgọ́ rẹ̀ sí, àwọn ìránṣẹ́ rẹ sì gbẹ́ kànga kan níbẹ̀.

  2. Nígbà náà ni Abimeleki tọ̀ ọ́ wá láti Gerari, àti Ahussati, olùdámọ̀ràn rẹ̀ àti Fikoli, olórí ogun rẹ̀.

  3. Isaaki sì bi wọ́n léèrè pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin tọ̀ mí wá, níwọ̀n ìgbà tí ẹ̀yin kórìíra mi tí ẹ sì lé mi jáde kúrò lọ́dọ̀ yín?”

  4. Wọ́n dáhùn pé, “A rí i dájú pé Olúwa wà pẹ̀lú rẹ, nítorí náà ni a fi rò ó wí pé, ó yẹ kí májẹ̀mú kí o wà láàrín àwa àti ìwọ. Jẹ́ kí a ṣe àdéhùn

  5. pé ìwọ kì yóò ṣe wá ní ibi, bí àwa pẹ̀lú kò ti ṣe ọ́ ní aburú, tí a sì ń ṣe ọ́ dáradára, tí a sì rán ọ jáde ní àlàáfíà láìṣe ọ́ ní ibi, kíyèsi Olúwa sì ti bùkún fún ọ.”

  6. Isaaki sì ṣe àsè fún wọn, wọn sì jẹ, wọ́n sì mu.

  7. Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì wọn búra fún ara wọn. Isaaki sì rán wọn lọ, wọ́n sì lọ ní àlàáfíà.

  8. Ní ọjọ́ náà gan an ni àwọn ìránṣẹ́ Isaaki wá sọ fún un pé àwọn ti kan omi ní kànga kan tí àwọn gbẹ́.

  9. Ó sì pe orúkọ kànga náà ní Ṣiba, títí di òní olónìí, orúkọ ìlú náà ni Beerṣeba.

  10. Bí ó bá ṣe pé Ọlọ́run àwọn baba mi, Ọlọ́run Abrahamu àti ẹ̀rù Isaaki kò wà pẹ̀lú mi ni, ìwọ ìbá ti lé mi jáde lọ́wọ́ òfo. Ṣùgbọ́n, Ọlọ́run ti rí gbogbo ìpọ́njú mi àti iṣẹ́ àṣekára tí mo fi ọwọ́ mi ṣe, ó sì kìlọ̀ fún ọ lóru àná.”

  11. Olúwa si wí pé, “Èmí ti rí ìpọ́njú àwọn ènìyàn mi ní ilẹ̀ Ejibiti, mo sì ti gbọ́ ohùn igbe wọn nítorí àwọn akóniṣiṣẹ́ wọn. Ìyà tí ń jẹ wọ́n sì kan mi lára.

  12. Èmi sì ti sọ̀kalẹ̀ wá láti gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn ará Ejibiti, àti láti mú wọn gòkè kúrò ní ilẹ̀ náà lọ sí ilẹ̀ tí ó dára tí ó sì ní ààyè, àní ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin; ibùgbé àwọn ará Kenaani, ará Hiti, Amori, Peresi, Hifi àti Jebusi.

  13. “Lọ, kó àwọn àgbàgbà Israẹli jọ, kí o sì wí fún wọn pé, ‘Olúwa Ọlọ́run àwọn baba yín, Ọlọ́run Abrahamu, ti Isaaki, àti ti Jakọbu; ni ó farahàn mi, ó sì wí pé, lóòótọ́ èmi ti ń bojú wò yín, èmi sì ti rí ohun tí wọ́n ṣe sí i yín ni ilẹ̀ Ejibiti.

  14. Èmi sì ti ṣe ìlérí láti mú un yín jáde kúrò nínú ìpọ́njú yín ni ilẹ̀ Ejibiti wá sí ilẹ̀ Kenaani, ará Hiti, Amori, Peresi, Hifi àti Jebusi; ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin.’

  15. Olúwa sì sọ fún un pé, “Ta ni ó fún ènìyàn ni ẹnu? Ta ni ó mú un ya odi tàbí adití? Ta ni ó mú un ríran, tàbí mú un fọ́jú? Ǹjẹ́ kì í ṣe èmi Olúwa?

  16. Nígbà náà ni Mose sọ fún àwọn ènìyàn náà pé, “Ẹ má bẹ̀rù, ẹ dúró ṣinṣin kí ẹ sì rí ìdáǹdè tí Olúwa yóò fi fún un yín lónìí, àwọn ará Ejibiti ti ẹ̀yin rí lónìí ni ẹ kò ni tún padà rí wọn mọ́.

  17. Olúwa yóò jà fún un yín; kí ẹ̀yin kí ó sá à mu sùúrù.”

  18. Ẹ kíyèsi i, mo ti kọ́ ọ yín ní àwọn òfin àti àṣẹ bí Olúwa Ọlọ́run mi ti pàṣẹ fún mi, kí ẹ ba à le tẹ̀lé wọn ní ilẹ̀ náà tí ẹ ń lọ láti ní ní ìní.

  19. Ẹ máa kíyèsi wọn dáradára. Èyí ni yóò fi ọgbọ́n àti òye yín han àwọn orílẹ̀-èdè. Àwọn tí wọn yóò gbọ́ nípa àwọn ìlànà wọ̀nyí, tí wọn yóò sì máa wí pé, “Dájúdájú, orílẹ̀-èdè ńlá yìí kún fún ọgbọ́n àti òye.”

  20. Orílẹ̀-èdè olókìkí wo ni ọlọ́run wọn tún súnmọ́ wọn, bí Olúwa Ọlọ́run wa ti súnmọ́ wa nígbàkígbà tí a bá ń ké pè é?

  21. Orílẹ̀-èdè wo ló tún le lókìkí láti ní àwọn ìlànà òdodo, àti òfin gẹ́gẹ́ bí àwọn òfin wọ̀nyí tí mo ń gbé kalẹ̀ fún un yín lónìí.

  22. Kìkì i kí ẹ kíyèsára, kí ẹ sì ṣọ́ra a yín gidigidi kí ẹ má ba à gbàgbé àwọn ohun tí ojú yín ti rí, kí wọn má sì ṣe sá kúrò lóókan àyà yín níwọ̀n ìgbà tí ẹ sì wà láààyè. Ẹ máa fi wọ́n kọ́ àwọn ọmọ yín àti àwọn ọmọ wọn tí ń bọ̀ lẹ́yìn wọn.

  23. Ẹ rántí ọjọ́ tí ẹ dúró níwájú Olúwa Ọlọ́run yín ní Horebu, nígbà tí ó wí fún mi pé, “Kó àwọn ènìyàn wọ̀nyí jọ síwájú mi láti gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, kí wọ́n lè kọ́ láti máa bu ọlá náà fún mi ní gbogbo ìgbà tí wọ́n bá gbé lórí ilẹ̀ náà, kí wọ́n sì le è fi wọ́n kọ́ àwọn ọmọ wọn.”

  24. Ẹ̀yin súnmọ́ tòsí, ẹ sì dúró ní ẹsẹ̀ òkè náà, òkè náà sì ń jóná dé agbede-méjì ọrun, pẹ̀lú òkùnkùn, àti àwọsánmọ̀, àti òkùnkùn biribiri.

  25. Olúwa sì bá yín sọ̀rọ̀ láti àárín iná náà wá. Ẹ gbọ́ àwọn ìró ohùn, ṣùgbọ́n ẹ kò rí ẹnikẹ́ni, ohùn nìkan ni ẹ gbọ́.