Fò sí àkóónú

circa 1446–1406 BC

The Wilderness Years

Forty years of wandering in the desert test Israel's faith and prepare a new generation to enter the promised land.

2,247 ẹsẹ · 2 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Numeri 4:37nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Èyí ni àpapọ̀ iye àwọn ọmọ Kohati tó ń ṣiṣẹ́ ní àgọ́ ìpàdé; tí Mose àti Aaroni kà gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa á láṣẹ fún Mose.

  2. Numeri 4:38nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Wọ́n ka àwọn ọmọ Gerṣoni nípa ìdílé àti ilé baba wọn.

  3. Numeri 4:39nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Gbogbo ọmọkùnrin láti ọmọ ọgbọ̀n ọdún títí dé àádọ́ta, gbogbo àwọn tó lè ṣiṣẹ́ ní àgọ́ ìpàdé.

  4. Numeri 4:40nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Iye wọn nípa ìdílé àti ilé baba wọn jẹ́ ẹgbẹ̀tàlá ó lé ọgbọ̀n (2,630).

  5. Numeri 4:41nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Èyí jẹ́ àpapọ̀ iye àwọn ọmọ Gerṣoni, àwọn tó ṣiṣẹ́ ní àgọ́ ìpàdé. Mose àti Aaroni ṣe bí àṣẹ Olúwa.

  6. Numeri 4:42nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Wọ́n ka àwọn ọmọ Merari nípa ìdílé àti ilé baba wọn.

  7. Numeri 4:43nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Gbogbo ọkùnrin láti ọmọ ọgbọ̀n ọdún títí dé àádọ́ta ọdún, àwọn tó ṣiṣẹ́ ní àgọ́ ìpàdé.

  8. Numeri 4:44nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Iye wọn nípa ìdílé àti ilé baba wọn jẹ́ ẹgbẹ̀rìndínlógún (3,200).

  9. Numeri 4:45nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Èyí ni àpapọ̀ iye àwọn ọmọ Merari. Mose àti Aaroni kà wọ́n gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Olúwa láti ẹnu Mose.

  10. Numeri 4:46nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Gbogbo àwọn tí a kà nínú àwọn ọmọ Lefi, ti Mose àti Aaroni àti àwọn olórí Israẹli kà, nípa ìdílé wọn àti gẹ́gẹ́ bí ilé baba wọn.

  11. Numeri 4:47nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Gbogbo ọkùnrin láti ọmọ ọgbọ̀n ọdún títí dé àádọ́ta, àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ìsìn tó sì ń ru àwọn ẹrù inú Àgọ́ ìpàdé.

  12. Numeri 4:48nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Àpapọ̀ iye wọn jẹ́ ẹgbẹ̀tàlá lé lẹ́gbàarin ó dín ogún (8,580).

  13. Numeri 4:49nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Wọ́n yan iṣẹ́ àti àwọn ohun tí ẹni kọ̀ọ̀kan yóò máa gbé fún un gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ láti ẹnu Mose. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe kà wọ́n gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

  14. Numeri 5:1nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Olúwa sọ fún Mose pé,

  15. Numeri 5:2nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    “Pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli pé kí wọn ó lé ẹnikẹ́ni tó bá ní ẹ̀tẹ̀, ìtújáde ara ní oríṣìíríṣìí tàbí ẹni tó jẹ́ aláìmọ́ nípa fífọwọ́ kan òkú.

  16. Numeri 5:3nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Irú ẹni bẹ́ẹ̀ yálà ọkùnrin tàbí obìnrin, ẹ lé wọn jáde kúrò nínú ibùdó kí wọn má ba à ba ibùdó wọn jẹ́ níbi tí èmi ń gbé láàrín wọn.”

  17. Numeri 5:4nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Àwọn ọmọ Israẹli sì ṣe bẹ́ẹ̀; wọ́n lé wọn jáde kúrò nínú ibùdó. Wọn ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ fún Mose.

  18. Numeri 5:5nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Olúwa sọ fún Mose pé,

  19. Numeri 5:6nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli: ‘Nígbà tí ọkùnrin kan tàbí obìnrin kan bá ṣẹ̀ ara wọn lọ́nà kan tàbí òmíràn, tí wọ́n sì ṣe àìṣòótọ́ sí Olúwa, ẹni náà jẹ̀bi.

  20. Numeri 5:7nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Ó gbọdọ̀ jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ tí ó sẹ̀. Ó gbọdọ̀ san ẹ̀san rẹ̀ ní ojú owó, kí ó sì fi ìdámárùn-ún rẹ̀ lé e, kí ó sì fi fún ẹni tí òun jẹ̀bi rẹ̀.

  21. Numeri 5:8nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n bí irú ẹni bẹ́ẹ̀ kò bá ní ìbátan tí ó súnmọ́ ọn tí ó lè ṣe àtúnṣe àṣìṣe rẹ̀ náà fún, àtúnṣe náà jẹ́ ti Olúwa, ẹ sì gbọdọ̀ ko fún àlùfáà pẹ̀lú àgbò tí a fi ṣe ètùtù fún ẹni náà.

  22. Numeri 5:9nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Gbogbo ọrẹ ohun mímọ́ tí àwọn ọmọ Israẹli bá mú wá fún àlùfáà jẹ́ tirẹ̀.

  23. Numeri 5:10nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Ọrẹ ohun mímọ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan jẹ́ ti òun nìkan, ṣùgbọ́n ohunkóhun tó bá fún àlùfáà yóò jẹ́ ti àlùfáà.’ ”

  24. Numeri 5:11nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Olúwa sọ fún Mose wí pé,

  25. Numeri 5:12nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    “Bá àwọn ọmọ Israẹli sọ̀rọ̀ kí o sọ fún wọn pé, ‘Bí ìyàwó ọkùnrin kan bá yapa tó sì ṣe àìṣòótọ́ sí i,