Fò sí àkóónú

circa 1446–1406 BC

The Wilderness Years

Forty years of wandering in the desert test Israel's faith and prepare a new generation to enter the promised land.

2,247 ẹsẹ · 2 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Deuteronomi 22:10nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Ìwọ kò gbọdọ̀ fi akọ màlúù àti akọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tulẹ̀ pọ̀.

  2. Deuteronomi 22:11nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Ìwọ kò gbọdọ̀ wọ aṣọ onírun àgùntàn àti aṣọ funfun papọ̀.

  3. Deuteronomi 22:12nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Kí o ṣe wajawaja sí etí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin aṣọ ìlekè rẹ.

  4. Deuteronomi 22:13nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Bí ọkùnrin kan bá mú ìyàwó àti, lẹ́yìn ìgbà tí ó ti dùbúlẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, kórìíra rẹ̀,

  5. Deuteronomi 22:14nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    tí ó ṣì sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ sì i, tí o sì fún un ní orúkọ búburú, wí pé, “Mo fẹ́ obìnrin yìí, ṣùgbọ́n nígbà tí mo súnmọ́ ọn. Èmi kò rí àmì ìbálé rẹ̀.”

  6. Deuteronomi 22:15nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni baba ọmọbìnrin náà àti ìyá rẹ̀ yóò mú ẹ̀rí pé, ó ti wà ní ìbálé tẹ́lẹ̀ wá sí ọ̀dọ̀ àwọn àgbàgbà ìlú ní ẹnu-bodè.

  7. Deuteronomi 22:16nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Baba obìnrin náà yóò wí fún àwọn àgbàgbà pé, “Mo fi ọmọbìnrin mi fún ọkùnrin yìí láti fẹ́ níyàwó, ṣùgbọ́n ó kórìíra rẹ̀.

  8. Deuteronomi 22:17nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Ní ìsinsin yìí ó ti sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ sí i ó sì wí pé, ‘Èmi kò rí ọmọbìnrin rẹ kí ó wà ní wúńdíá.’ Ṣùgbọ́n níhìn-ín yìí ni ẹ̀rí ìbálé ọmọbìnrin mi.” Nígbà náà ni àwọn òbí rẹ̀ yóò fi aṣọ hàn níwájú àwọn àgbàgbà ìlú,

  9. Deuteronomi 22:18nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    àwọn àgbàgbà yóò sì mú ọkùnrin náà, wọn yóò sì jẹ ní yà.

  10. Deuteronomi 22:19nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Wọn yóò sì gba ìtánràn ọgọ́rùn-ún ṣékélì owó fàdákà fún baba ọmọbìnrin náà, nítorí ọkùnrin yìí ti fi orúkọ búburú fún wúńdíá Israẹli. Yóò sì máa ṣe ìyàwó rẹ̀; kò gbọdọ̀ kọ̀ ọ́ sílẹ̀ ní gbogbo ayé e rẹ̀.

  11. Deuteronomi 22:20nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n bí ẹ̀sùn náà bá jẹ́ òtítọ́ tí a kò sí rí ẹ̀rí ìbálé obìnrin náà,

  12. Deuteronomi 22:21nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    wọn yóò mú wá sí ẹnu-ọ̀nà ilé baba rẹ̀ níbẹ̀ sì ni àwọn ọkùnrin ìlú rẹ̀ yóò ti sọ ọ́ ní òkúta pa. Ó ti ṣe ohun ìtìjú ní Israẹli nípa ṣíṣe àgbèrè nígbà tí ó wà nílé baba rẹ̀. Ẹ ní láti pa ohun búburú kúrò láàrín yín.

  13. Deuteronomi 22:22nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Bí o bá rí ọkùnrin kan tí ó bá ìyàwó ọkùnrin mìíràn lòpọ̀, àwọn méjèèjì ní láti kú. Ẹ ní láti pa ohun búburú kúrò láàrín Israẹli.

  14. Deuteronomi 22:23nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Bí ó bá ṣẹlẹ̀ wí pé ọkùnrin kan pàdé wúńdíá tí a ti fi fún ni láti fẹ́ láàrín ìlú tí ó sì lòpọ̀ pẹ̀lú u rẹ̀,

  15. Deuteronomi 22:24nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    ìwọ yóò mú àwọn méjèèjì lọ sí ẹnu ibodè ìlú náà kí o sì sọ wọ́n ní òkúta pa nítorí ọmọbìnrin náà wà ní ìlú kò sì kígbe fún ìrànlọ́wọ́, àti ọkùnrin náà nítorí ó ba ìyàwó ọkùnrin mìíràn jẹ́. O ní láti wẹ búburú kúrò láàrín rẹ.

  16. Deuteronomi 22:25nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n bí ó bá ṣe ìgbẹ́ ní ó ti ṣẹlẹ̀ pé ọkùnrin kan ti pàdé ọmọbìnrin tí a ti fẹ́ ṣọ́nà tí o sì fi tagbára tagbára bá a ṣe, ọkùnrin náà nìkan tí ó ṣe èyí ni yóò kú.

  17. Deuteronomi 22:26nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Má ṣe fi ohunkóhun ṣe ọmọbìnrin náà; kò ṣẹ ẹ̀ṣẹ̀ tí ó tọ́ sí ikú. Ẹjọ́ yìí rí bí i ti ẹnìkan tí a gbámú tí ó pa aládùúgbò rẹ̀.

  18. Deuteronomi 22:27nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Nítorí ọkùnrin náà rí ọmọbìnrin náà ní ìta ibodè, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọbìnrin àfẹ́sọ́nà kígbe, kò sí ẹnìkankan níbẹ̀ láti gbà á kalẹ̀.

  19. Deuteronomi 22:28nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ọkùnrin pàdé wúńdíá tí kò ì tí ì ní àfẹ́sọ́nà tí ó sì fi tipátipá bá a ṣe tí a gbá wọn mú.

  20. Deuteronomi 22:29nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Ó ní láti san àádọ́ta fàdákà fún baba obìnrin náà, nítorí tí ó ti bà á jẹ́. Kò lè kọ̀ ọ́ sílẹ̀ níwọ̀n ìgbà tí ó sì wà láààyè.

  21. Deuteronomi 22:30nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Ọkùnrin kò gbọdọ̀ fẹ́ ìyàwó baba rẹ̀; kò gbọdọ̀ sọ ìtẹ́ baba rẹ̀ di àìlọ́wọ̀.

  22. Deuteronomi 23:1nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Kí ẹnikẹ́ni tí a fọ́ ní kóró ẹpọ̀n nípa rírùn tàbí gígé má ṣe wọ inú ìjọ Olúwa wá.

  23. Deuteronomi 23:2nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Kí ọmọ àlè má ṣe wọ ìpéjọ Olúwa, pàápàá títí dé ìran kẹwàá.

  24. Deuteronomi 23:3nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Kí ọmọ Ammoni tàbí ọmọ Moabu, kì yóò wọ ìjọ Olúwa, àní títí dé ìran kẹwàá, ènìyàn wọn kan kì yóò wọ inú ìjọ ènìyàn Olúwa láéláé.

  25. Deuteronomi 23:4nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Nítorí wọn kò fi àkàrà àti omi pàdé e yín lójú ọ̀nà nígbà tí ò ń bọ̀ láti Ejibiti àti nítorí wọ́n gba ẹ̀yà iṣẹ́ láti fi ọ́ gégùn ún Balaamu ọmọ Beori ará a Petori ti Aramu-Naharaimu.