Fò sí àkóónú

circa 1446–1406 BC

The Wilderness Years

Forty years of wandering in the desert test Israel's faith and prepare a new generation to enter the promised land.

2,247 ẹsẹ · 2 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Deuteronomi 23:5nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Síbẹ̀síbẹ̀, Olúwa Ọlọ́run rẹ kò ní fetí sí Balaamu ṣùgbọ́n ó yí ègún sí ìbùkún fún ọ, nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ fẹ́ràn rẹ.

  2. Deuteronomi 23:6nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Ìwọ kò gbọdọ̀ wá àlàáfíà, tàbí ire wọn níwọ̀n ìgbà tí o sì wà láààyè.

  3. Deuteronomi 23:7nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Ìwọ kò gbọdọ̀ kórìíra ará Edomu kan nítorí arákùnrin rẹ ni. Ìwọ kò gbọdọ̀ kórìíra ará Ejibiti, nítorí o gbé gẹ́gẹ́ bí àjèjì ní ilẹ̀ rẹ̀.

  4. Deuteronomi 23:8nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Ìran kẹta àwọn ọmọ tí a bí fún wọn lè wọ ìpéjọ Olúwa.

  5. Deuteronomi 23:9nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí o bá dó ti àwọn ọ̀tá rẹ, pa gbogbo ohun àìmọ́ kúrò.

  6. Deuteronomi 23:10nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Bí ọ̀kan nínú àwọn ọkùnrin rẹ bá jẹ́ aláìmọ́ nítorí ìtújáde tí ó ní, o ní láti jáde kúrò nínú àgọ́, kí o má ṣe wọ inú àgọ́.

  7. Deuteronomi 23:11nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n nígbà tí ó bá di ìrọ̀lẹ́ o ní láti wẹ ara rẹ, àti ní àṣálẹ́ kí o padà sínú àgọ́.

  8. Deuteronomi 23:12nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Sàmì sí ibìkan lóde àgọ́, níbi tí o lè máa lọ láti dẹ ara rẹ lára.

  9. Deuteronomi 23:13nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Kí ìwọ kí ó sì mú ìwalẹ̀ kan pẹ̀lú ohun ìjà rẹ; yóò sì ṣe, nígbà tí ìwọ yóò bá gbọnṣẹ̀ lẹ́yìn ibùdó, kí ìwọ kí ó mú ìwalẹ̀, kí ìwọ kí ó sì yípadà, kí o sì bo ohun tí ó jáde láara rẹ.

  10. Deuteronomi 23:14nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ ń rìn láàrín àgọ́ láti dáàbò bò ọ́ àti láti fi àwọn ọ̀tá à rẹ lé ọ lọ́wọ́. Àgọ́ rẹ ní láti jẹ́ mímọ́, nítorí kí ó má ba à rí ohun àìtọ́ láàrín yín kí ó sì yípadà kúrò lọ́dọ̀ yín.

  11. Deuteronomi 23:15nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Bí ẹrú kan bá ti gba ààbò lọ́dọ̀ rẹ, má ṣe fi lé ọ̀gá rẹ̀ lọ́wọ́.

  12. Deuteronomi 23:16nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Jẹ́ kí ó máa gbé láàrín rẹ níbikíbi tí ó bá fẹ́ àti èyíkéyìí ìlú tí ó bá mú. Má ṣe ni í lára.

  13. Deuteronomi 23:17nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Kí ọkùnrin tàbí obìnrin Israẹli má ṣe padà di alágbèrè ojúbọ òrìṣà.

  14. Deuteronomi 23:18nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Ìwọ kò gbọdọ̀ mú owó iṣẹ́ panṣágà obìnrin tàbí ọkùnrin wá sí ilé Olúwa Ọlọ́run rẹ láti fi san ẹ̀jẹ́ kankan; nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ kórìíra àwọn méjèèjì.

  15. Deuteronomi 23:19nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Ìwọ kò gbọdọ̀ ka èlé sí arákùnrin rẹ lọ́rùn, bóyá lórí owó tàbí oúnjẹ tàbí ohunkóhun mìíràn tí ó lè mú èlé wá.

  16. Deuteronomi 23:20nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Ìwọ lè ka èlé sí àlejò lọ́rùn, ṣùgbọ́n kì í ṣe arákùnrin ọmọ Israẹli, nítorí kí Olúwa Ọlọ́run rẹ lè bùkún ọ nínú ohun gbogbo tí o bá dáwọ́lé ní ilẹ̀ tí ò ń wọ̀ lọ láti ní.

  17. Deuteronomi 23:21nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Bí o bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ, má ṣe lọ́ra láti san án, nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò béèrè rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ, o sì máa jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀.

  18. Deuteronomi 23:22nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n tí o bá fàsẹ́yìn láti jẹ́ ẹ̀jẹ́, o kò ní jẹ̀bi.

  19. Deuteronomi 23:23nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Rí i dájú pé o ṣe ohunkóhun tí o bá ti ètè rẹ jáde, nítorí pé ìwọ fi tinútinú rẹ jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú ẹnu ara rẹ.

  20. Deuteronomi 23:24nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Bí ìwọ bá wọ inú ọgbà àjàrà aládùúgbò rẹ, o lè jẹ gbogbo èso àjàrà tí o bá fẹ́, ṣùgbọ́n má ṣe fi nǹkan kan sínú agbọ̀n rẹ.

  21. Deuteronomi 23:25nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Bí ìwọ bá wọ inú oko ọkà aládùúgbò rẹ, o lè fi ọwọ́ rẹ ya síírí rẹ̀, ṣùgbọ́n o kò gbọdọ̀ ki dòjé bọ ọkà tí ó dúró.

  22. Deuteronomi 24:1nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Bí ọkùnrin kan bá fẹ́ obìnrin kan, tí ó sì gbe ní ìyàwó, yóò sì ṣe, bí obìnrin náà kò bá rí ojúrere ní ojú ọkùnrin náà, nítorí ó rí ohun àìtọ́ kan lára rẹ̀, ǹjẹ́ kí ó kọ ìwé ìkọ̀sílẹ̀ fún obìnrin náà, kí ó sì fi lé e lọ́wọ́, kí ó sì ran jáde kúrò nínú ilé rẹ̀,

  23. Deuteronomi 24:2nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    tí ó bá di ìyàwó ọkùnrin mìíràn lẹ́yìn ìgbà tí ó kúrò nílé rẹ,

  24. Deuteronomi 24:3nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    àti tí ọkọ rẹ̀ kejì kò bá fẹ́ràn rẹ̀ tí ó sì kọ ìwé-ẹ̀rí ìkọ̀sílẹ̀ sí i, kí ó fi fún un kí ó sì lé e kúrò nílé e rẹ̀, tàbí tí ọkọ rẹ̀ kejì bá kú,

  25. Deuteronomi 24:4nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    nígbà náà ni ọkọ, tí ó ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀, kò gbọdọ̀ fẹ́ ẹ mọ́ lẹ́yìn tí ó ti di àìmọ́. Nítorí èyí ni ìríra níwájú Olúwa. Má ṣe mú ẹ̀ṣẹ̀ wá sórí ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò fi fún ọ bí ogún.