Fò sí àkóónú

circa 1446–1406 BC

The Wilderness Years

Forty years of wandering in the desert test Israel's faith and prepare a new generation to enter the promised land.

2,247 ẹsẹ · 2 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Deuteronomi 24:5nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Bí ọkùnrin kan bá ṣẹ̀ṣẹ̀ gbéyàwó, o kò gbọdọ̀ ran lọ sí ogun tàbí kí ó ní iṣẹ́ kan láti ṣe. Ó ní láti ní òmìnira fún ọdún kan kí ó dúró sílé kí ó sì mú inú dídùn bá ìyàwó rẹ̀ tí ó fẹ́.

  2. Deuteronomi 24:6nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ gba ìyá ọlọ tàbí ọmọ ọlọ gẹ́gẹ́ bí ohun ìdúró fún gbèsè, nítorí pé ẹ̀mí ènìyàn ni ó gbà ní pàṣípàrọ̀ n nì.

  3. Deuteronomi 24:7nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Bí a bá mú ọkùnrin kan tí ó jí ọ̀kan nínú arákùnrin rẹ̀ ní Israẹli gbé àti tí ó jí ọ̀kan nínú ẹrú tàbí kí ó tà á, ẹni tí ó jí ènìyàn gbé ní láti kú. Ẹ ní láti wẹ búburú kúrò láàrín yín.

  4. Deuteronomi 24:8nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Ní ti ààrùn ẹ̀tẹ̀ kíyèsára láti máa ṣe gẹ́gẹ́ bí àwọn àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ọmọ Lefi ti pàṣẹ fún ọ. O ní láti máa fi ìṣọ́ra tẹ̀lé ohun tí mo ti pàṣẹ fún wọn.

  5. Deuteronomi 24:9nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Rántí ohun tí Olúwa Ọlọ́run rẹ ṣe sí Miriamu lójú ọ̀nà lẹ́yìn ìgbà tí o jáde kúrò ní Ejibiti.

  6. Deuteronomi 24:10nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí o bá wín arákùnrin rẹ ní ohunkóhun, má ṣe lọ sí ilé rẹ̀ láti gba ohun tí ó bá mú wá bí ẹ̀rí.

  7. Deuteronomi 24:11nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Dúró síta gbangba kí o sì jẹ́ kí ọkùnrin tí o wín mú ògo rẹ jáde wá fún ọ.

  8. Deuteronomi 24:12nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Bí ọkùnrin náà bá jẹ́ tálákà má ṣe lọ sùn ti ìwọ ti ògo rẹ.

  9. Deuteronomi 24:13nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Dá aṣọ ìlekè rẹ padà ní àṣálẹ́ kí ó bá à le sùn lórí i rẹ̀. Nígbà náà ni yóò dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, ó sì máa jásí ìwà òdodo níwájú Olúwa Ọlọ́run rẹ.

  10. Deuteronomi 24:14nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Má ṣe ni alágbàṣe kan lára tí ó jẹ́ tálákà àti aláìní, bóyá ó jẹ́ arákùnrin Israẹli tàbí àlejò tí ó ń gbé ní ọ̀kan nínú àwọn ìlú rẹ.

  11. Deuteronomi 24:15nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    San owó iṣẹ́ rẹ̀ ní ọjọ́ kan náà kí ó tó di àṣálẹ́, nítorí ó jẹ́ tálákà, ó sì gbẹ́kẹ̀lé e bí kò ṣe bẹ́ẹ̀ ó lè ké pe Olúwa sí ọ, o sì máa gba ìdálẹ́bi ẹ̀ṣẹ̀.

  12. Deuteronomi 24:16nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Baba kò gbọdọ̀ kú fún àwọn ọmọ wọn tàbí kí àwọn ọmọ kú fún baba wọ́n; olúkúlùkù ní láti kú fún ẹ̀ṣẹ̀ òun tìkára rẹ̀.

  13. Deuteronomi 24:17nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Má ṣe yí ìdájọ́ po fún àlejò tàbí aláìní baba, tàbí gba aṣọ ìlekè opó bí ẹ̀rí.

  14. Deuteronomi 24:18nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Rántí pé o jẹ́ ẹrú ní Ejibiti tí Olúwa Ọlọ́run rẹ sì gbà ọ́ níbẹ̀. Ìdí nìyí tí mo fi pa á láṣẹ fún ọ láti ṣe èyí.

  15. Deuteronomi 24:19nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí o bá ń kórè oko rẹ tí o sì fojú fo ìtí kan, má ṣe padà lọ mú u. Fi í kalẹ̀ fún àwọn àlejò, aláìní baba àti opó, kí Olúwa Ọlọ́run rẹ lè bùkún fún gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ ọ̀ rẹ.

  16. Deuteronomi 24:20nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí o bá ń gun igi olifi lára àwọn igi i rẹ, má ṣe padà lọ sí ẹ̀ka náà ní ìgbà kejì. Fi èyí tí ó kù fún àlejò, aláìní baba àti opó.

  17. Deuteronomi 24:21nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí ìwọ bá kórè èso àjàrà nínú ọgbà àjàrà rẹ, má ṣe lọ sí ọgbà náà mọ́. Fi èyí tí ó kù fún àlejò, aláìní baba àti opó.

  18. Deuteronomi 24:22nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Rántí pé ìwọ ti jẹ́ àlejò ní Ejibiti. Ìdí nìyí tí mo fi pa á láṣẹ fún ọ láti ṣe èyí.

  19. Deuteronomi 25:1nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí àwọn ènìyàn méjì bá ń jà, kí wọn kó ẹjọ́ lọ sí ilé ìdájọ́, kí àwọn onídàájọ́ dá ẹjọ́ náà, kí wọn dá àre fún aláre àti ẹ̀bi fún ẹlẹ́bi.

  20. Deuteronomi 25:2nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Bí ó bá tọ́ láti na ẹlẹ́bi, kí onídàájọ́ dá a dọ̀bálẹ̀ kí a sì nà án ní ojú u rẹ̀ ní iye pàṣán tí ó tọ́ sí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó sẹ̀.

  21. Deuteronomi 25:3nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n kò gbọdọ̀ fún un ju ogójì pàṣán lọ. Bí ó bá nà án ju bẹ́ẹ̀ lọ, arákùnrin rẹ̀ yóò di ẹni ìrẹ̀sílẹ̀ ní ojú rẹ̀.

  22. Deuteronomi 25:4nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Ìwọ kò gbọdọ̀ di màlúù ti ń tẹ ọkà lẹ́nu.

  23. Deuteronomi 25:5nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Bí àwọn arákùnrin bá ń gbé pọ̀, tí ọ̀kan nínú wọn bá sì kú, tí kò sí ní ọmọkùnrin, kí aya òkú má ṣe ní àlejò ará òde ní ọkọ rẹ̀. Arákùnrin ọkọ rẹ̀ ni kí ó wọlé tọ̀ ọ́, kí ó fi ṣe aya, kí ó sì ṣe iṣẹ́ arákùnrin ọkọ fún un.

  24. Deuteronomi 25:6nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Ọmọkùnrin tí ó bá kọ́ bí ni yóò máa jẹ́ orúkọ arákùnrin rẹ̀ tí ó kú náà, kí orúkọ rẹ̀ má ba á parẹ́ ní Israẹli.

  25. Deuteronomi 25:7nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n bí ọkùnrin náà kò bá fẹ́ fi aya arákùnrin rẹ̀ ṣe aya rẹ̀, obìnrin náà yóò lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn àgbàgbà ní ẹnu-bodè ìlú láti sọ pé, “Arákùnrin ọkọ ọ̀ mi kọ̀ láti gbé orúkọ arákùnrin rẹ̀ ró ní Israẹli. Kò ní ṣe ojúṣe rẹ̀ bí arákùnrin ọkọ mi sí mi.”