Fò sí àkóónú

circa 1446–1406 BC

The Wilderness Years

Forty years of wandering in the desert test Israel's faith and prepare a new generation to enter the promised land.

2,247 ẹsẹ · 2 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Numeri 20:19nǹkan bí 1471 ṣáájú Kristi

    Àwọn ọmọ Israẹli dáhùn pé, “A ó gba ọ̀nà tóóró, bí àwa tàbí ẹran ọ̀sìn wa bá sì mú lára omi rẹ, a ó san owó rẹ̀. A kàn fẹ́ rìn kọjá lórí ilẹ̀ rẹ ni kò sí nǹkan kan mìíràn tí a fẹ́ ṣe.”

  2. Numeri 20:20nǹkan bí 1471 ṣáájú Kristi

    Wọ́n tún dáhùn wí pé, “Ẹ kò lè kọjá.” Nígbà náà ni Edomu jáde wá láti kọjú ìjà sí wọn pẹ̀lú ọ̀pọ̀ àti alágbára ọmọ-ogun.

  3. Numeri 20:21nǹkan bí 1471 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí Edomu sì kọ̀ jálẹ̀ láti jẹ́ kí wọn kọjá ní ilẹ̀ wọn, Israẹli yípadà kúrò lọ́dọ̀ wọn.

  4. Numeri 20:22nǹkan bí 1471 ṣáájú Kristi

    Gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli sì jáde láti Kadeṣi wọ́n sì wá sí orí òkè Hori.

  5. Numeri 20:23nǹkan bí 1471 ṣáájú Kristi

    Ní orí òkè Hori, ní ẹ̀gbẹ́ ààlà Edomu Olúwa sọ fún Mose àti Aaroni pé,

  6. Numeri 20:24nǹkan bí 1471 ṣáájú Kristi

    “Aaroni yóò kú. Kò ní wọ ilẹ̀ tí mo fi fún àwọn ọmọ Israẹli, nítorí ẹ̀yin méjèèjì ṣe àìgbọ́ràn sí òfin mi níbi omi Meriba.

  7. Numeri 20:25nǹkan bí 1471 ṣáájú Kristi

    Mú Aaroni àti ọmọ rẹ̀ Eleasari lọ sí orí òkè Hori.

  8. Numeri 20:26nǹkan bí 1471 ṣáájú Kristi

    Bọ́ aṣọ Aaroni kí o sì gbe wọ ọmọ rẹ̀ Eleasari, nítorí pé Aaroni yóò kú síbẹ̀.”

  9. Numeri 20:27nǹkan bí 1471 ṣáájú Kristi

    Mose sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ, wọ́n lọ sí orí òkè Hori ní ojú gbogbo ìjọ ènìyàn.

  10. Numeri 20:28nǹkan bí 1471 ṣáájú Kristi

    Mose bọ́ aṣọ Aaroni ó sì gbe wọ ọmọ rẹ̀ Eleasari, Aaroni sì kú sí orí òkè. Nígbà náà Mose àti Eleasari sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè,

  11. Numeri 20:29nǹkan bí 1471 ṣáájú Kristi

    nígbà tí gbogbo ìjọ ènìyàn sì gbọ́ pé Aaroni ti kú, gbogbo ilé Israẹli ṣe ìdárò rẹ̀ fún ọgbọ̀n ọjọ́.

  12. Numeri 21:1nǹkan bí 1453 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí ọba Aradi ará Kenaani, tí ń gbé ní gúúsù gbọ́ wí pé Israẹli ń bọ̀ wá ní ojú ọ̀nà Atarimu, ó bá Israẹli jà ó sì fi agbára mú díẹ̀ lára wọn.

  13. Numeri 21:2nǹkan bí 1453 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni Israẹli jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún Olúwa pé, “Bí o bá lè fi àwọn ènìyàn yìí lé wa lọ́wọ́, gbogbo ìlú wọn ni a ó parun.”

  14. Numeri 21:3nǹkan bí 1453 ṣáájú Kristi

    Olúwa gbọ́ ẹ̀bẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli, ó sì fi àwọn ará Kenaani lé wọn lọ́wọ́. Wọ́n pa wọ́n run pátápátá; torí náà ni a ṣe ń pe ibẹ̀ ní Horma.

  15. Numeri 21:4nǹkan bí 1453 ṣáájú Kristi

    Wọ́n rin ìrìnàjò láti òkè Hori lọ sí ọ̀nà tó lọ sí Òkun Pupa, láti kọjá yípo Edomu. Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn bínú ní ojú ọ̀nà;

  16. Numeri 21:5nǹkan bí 1453 ṣáájú Kristi

    wọ́n sì sọ̀rọ̀ lòdì sí Ọlọ́run àti Mose, wọ́n wí pé, “Èéṣe tí ìwọ fi mú wa jáde láti Ejibiti kí a ba le wá kú sí aginjù yìí? Kò sí oúnjẹ! Kò sì sí omi! Àwa sì kórìíra oúnjẹ tí kò dára yìí!”

  17. Numeri 21:6nǹkan bí 1453 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni Olúwa rán ejò olóró sí àárín wọn; wọ́n gé àwọn ènìyàn jẹ, ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Israẹli sì kú.

  18. Numeri 21:7nǹkan bí 1453 ṣáájú Kristi

    Àwọn ènìyàn sì wá sí ọ̀dọ̀ Mose wọn wí pé, “A ti dá ẹ̀ṣẹ̀ nígbà tí asọ̀rọ̀-òdì sí Olúwa àti sí ìwọ pẹ̀lú. Gba àdúrà pé kí Olúwa mú ejò náà kúrò lọ́dọ̀ wa.” Nígbà náà ni Mose gbàdúrà fún àwọn ènìyàn.

  19. Numeri 21:8nǹkan bí 1453 ṣáájú Kristi

    Olúwa sọ fún Mose pé, “Rọ ejò, a ó sì gbé e kọ́ sókè lórí igi, ẹni tí ejò bá ti gé jẹ lè wò ó yóò sì yè.”

  20. Numeri 21:9nǹkan bí 1453 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni Mose sì rọ ejò onírin ó sì gbé e kọ́ sórí igi, bí ejò bá sì bu ẹnikẹ́ni jẹ bí ó bá ti wò ó yóò sì yè.

  21. Numeri 21:10nǹkan bí 1453 ṣáájú Kristi

    Àwọn ọmọ Israẹli tẹ̀síwájú wọ́n sì péjọ sí Obotu.

  22. Numeri 21:11nǹkan bí 1453 ṣáájú Kristi

    Wọ́n gbéra ní Obotu wọ́n sì pa ibùdó sí Iye-Abarimu, ní aginjù tí ó kọjú sí Moabu ní ìdojúkọ ìlà-oòrùn.

  23. Numeri 21:12nǹkan bí 1453 ṣáájú Kristi

    Láti ibẹ̀ ni wọ́n ti gbéra wọ́n sì pa ibùdó ní àfonífojì Seredi.

  24. Numeri 21:13nǹkan bí 1453 ṣáájú Kristi

    Láti ibẹ̀ lọ, wọn ṣí, wọ́n sì dó sí ìhà kejì Arnoni, tí ó wà ní aginjù tí ó wà ní agbègbè ilẹ̀ àwọn ọmọ Amori. Arnoni jẹ́ ààlà fún ilẹ̀ Moabu, láàrín Moabu àti Amori.

  25. Numeri 21:14nǹkan bí 1453 ṣáájú Kristi

    Ìdí nìyìí tí ìwé ogun Olúwa se wí pé, “…Wahebu ní Sufa, Òkun Pupa àti ní odò Arnoni