Fò sí àkóónú

circa 1446–1406 BC

The Wilderness Years

Forty years of wandering in the desert test Israel's faith and prepare a new generation to enter the promised land.

2,247 ẹsẹ · 2 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Numeri 21:15nǹkan bí 1453 ṣáájú Kristi

    àti ní ìṣàn odò tí ó darí sí ibùjókòó Ari tí ó sì fi ara ti ìpínlẹ̀ Moabu.”

  2. Numeri 21:16nǹkan bí 1453 ṣáájú Kristi

    Láti ibẹ̀ ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ rìn dé Beeri, èyí ni kànga tí Olúwa sọ fún Mose, “Kó àwọn ènìyàn jọ èmi ó sì fún wọn ní omi.”

  3. Numeri 21:17nǹkan bí 1453 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni Israẹli kọ orin yìí pé, “Sun jáde, ìwọ kànga! Ẹ máa kọrin nípa rẹ̀,

  4. Numeri 21:18nǹkan bí 1453 ṣáájú Kristi

    nípa kànga tí àwọn ọmọ-aládé gbẹ́, nítorí àwọn ọlọ́lá ènìyàn ni ó gbẹ́ ẹ; tí àwọn ọlọ́lá àwọn ènìyàn sì fi ọ̀pá aládé àti ọ̀pá oyè wọn gbẹ́.” Nígbà náà wọ́n kúrò láti aginjù lọ sí Mattana,

  5. Numeri 21:19nǹkan bí 1453 ṣáájú Kristi

    láti Mattana lọ sí Nahalieli, láti Nahalieli lọ sí Bamoti,

  6. Numeri 21:20nǹkan bí 1453 ṣáájú Kristi

    àti láti Bamoti lọ sí àfonífojì ní Moabu níbi tí òkè Pisga, tí ó wà ní òkè ilé omi ti kọjú sí aginjù.

  7. Numeri 21:21nǹkan bí 1453 ṣáájú Kristi

    Israẹli rán oníṣẹ́ láti sọ fún Sihoni ọba àwọn ará Amori wí pé,

  8. Numeri 21:22nǹkan bí 1453 ṣáájú Kristi

    “Jẹ́ kí a kọjá ní orílẹ̀-èdè rẹ. A kò ní kọjá sí inú oko pápá tàbí ọgbà àjàrà àbí mu omi láti inú kànga. A máa gba òpópónà náà ti ọba títí tí a ó fi la ilẹ̀ rẹ kọjá.”

  9. Numeri 21:23nǹkan bí 1453 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n Sihoni kò ní jẹ́ kí àwọn Israẹli kọjá ní ilẹ̀ wọn. Ó pe àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ jọ wọ́n sì wọ́de ogun lọ sí aginjù nítorí àwọn ọmọ Israẹli. Nígbà tí ó dé Jahasi, ó bá àwọn ọmọ Israẹli jà.

  10. Numeri 21:24nǹkan bí 1453 ṣáájú Kristi

    Àmọ́, Israẹli ṣẹ́gun, wọn fi ojú idà pa wọ́n, wọ́n sì gba ilẹ̀ láti ọwọ́ Arnoni lọ dé Jabbok, títí tí ó fi dé ilẹ̀ àwọn ará Ammoni, nítorí pé ààlà wọn jẹ́ olódi.

  11. Numeri 21:25nǹkan bí 1453 ṣáájú Kristi

    Israẹli sì gba gbogbo ìlú Amori wọ́n sì ń gbé ibẹ̀ pẹ̀lú Heṣboni, àti gbogbo ibùgbé ìlú tó yí i ká.

  12. Numeri 21:26nǹkan bí 1453 ṣáájú Kristi

    Heṣboni ni ìlú Sihoni ọba àwọn ará Amori, ẹni tí ó bá ọba Moabu ti tẹ́lẹ̀ jà tí ó sì gba gbogbo ilẹ̀ rẹ̀ ní ọwọ́ rẹ̀ títí dé Arnoni.

  13. Numeri 21:27nǹkan bí 1453 ṣáájú Kristi

    Ìdí nìyìí tí akọrin sọ wí pé, “Wá sí Heṣboni kí ẹ jẹ́ kí a tún un kọ́; jẹ́ kí ìlú Sihoni padà bọ̀ sípò.

  14. Numeri 21:28nǹkan bí 1453 ṣáájú Kristi

    “Iná jáde láti Heṣboni, ọ̀wọ́-iná láti Sihoni. Ó jó Ari àti Moabu run, àti ìlú àwọn olùgbé ibi gíga Arnoni.

  15. Numeri 21:29nǹkan bí 1453 ṣáájú Kristi

    Ègbé ní fún ọ, ìwọ Moabu! Ẹ ti parun, ẹ̀yin ènìyàn Kemoṣi! Ó ti fi ọmọ rẹ̀ ọkùnrin sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìsáǹsá àti ọmọ rẹ̀ obìnrin gẹ́gẹ́ bí ìgbèkùn fún Sihoni ọba àwọn Amori.

  16. Numeri 21:30nǹkan bí 1453 ṣáájú Kristi

    “Ṣùgbọ́n àti bì wọ́n ṣubú; a ti pa ìjẹgàba Heṣboni run, a pa wọ́n run títí dé Diboni. A sì ti bì wọ́n lulẹ̀ títí dé Nofa, tí ó sì fi dé Medeba.”

  17. Numeri 21:31nǹkan bí 1453 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni àwọn ọmọ Israẹli sì ń gbé ní ilẹ̀ Amori.

  18. Numeri 21:32nǹkan bí 1453 ṣáájú Kristi

    Lẹ́yìn ìgbà tí Mose rán ayọ́lẹ̀wò lọ sí Jaseri, àwọn ọmọ Israẹli sì gba àwọn agbègbè tó yí wọn ká wọ́n sì lé àwọn Amori tó wà níbẹ̀ jáde.

  19. Numeri 21:33nǹkan bí 1453 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà wọ́n pẹ̀yìndà wọ́n sì gòkè lọ sí Baṣani, Ogu ọba ti Baṣani àti gbogbo àwọn ọmọ-ogun tí ó wọ́de ogun jáde láti pàdé wọn ní ojú ogun ní Edrei.

  20. Numeri 21:34nǹkan bí 1453 ṣáájú Kristi

    Olúwa sọ fún Mose pé, “Má ṣe bẹ̀rù rẹ̀, nítorí tí mó tí fi òun lé ọ lọ́wọ́, àti àwọn ọmọ-ogun rẹ̀, àti ilẹ̀ rẹ̀, kí ìwọ kí ó ṣe sí i gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti ṣe sí Sihoni ọba Amori ẹni tí ó ń jẹ ọba ní Heṣboni.”

  21. Numeri 21:35nǹkan bí 1453 ṣáájú Kristi

    Wọ́n sì pa á, pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ àti gbogbo àwọn ọmọ-ogun rẹ̀, wọn kò fi ku ẹnìkan fún un láàyè. Wọ́n sì gba ìní ilẹ̀ rẹ̀.

  22. Numeri 22:1nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà àwọn ọmọ Israẹli rin ìrìnàjò lọ sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu wọ́n sì pa ibùdó lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jordani tí ó kọjá lọ sí Jeriko.

  23. Numeri 22:2nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Nísinsin yìí, Balaki ọmọ Sippori rí gbogbo ohun tí àwọn Israẹli ti ṣe sí àwọn ará Amori,

  24. Numeri 22:3nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    ẹ̀rù sì ba Moabu nítorí pé ọ̀pọ̀ ènìyàn wà níbẹ̀ nítòótọ́, Moabu kún fún ẹ̀rù nítorí àwọn ọmọ Israẹli.

  25. Numeri 22:4nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Moabu sọ fún àwọn àgbàgbà Midiani pé, “Nísinsin yìí ni àwọn wọ̀nyí yóò lá gbogbo ohun tí ó yí wa ká, bí màlúù ṣe ń jẹ koríko tí ó wà nínú oko.” Bẹ́ẹ̀ ni Balaki ọmọ Sippori, tí ó jẹ́ ọba Moabu nígbà náà,