- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 1446–1406 BC
The Wilderness Years
Forty years of wandering in the desert test Israel's faith and prepare a new generation to enter the promised land.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Numeri 18:23nǹkan bí 1471 ṣáájú Kristi
Àwọn ọmọ Lefi ní ó gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ tí ó wà nínú àgọ́ ìpàdé, wọn yóò sì jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn bí wọ́n bá kúrò láti ṣe é. Èyí ni ìlànà láéláé fún àwọn ìran tí ó ń bọ̀. Wọn kò nígbà ogún kankan láàrín àwọn ọmọ Israẹli.
- Numeri 18:24nǹkan bí 1471 ṣáájú Kristi
Kàkà bẹ́ẹ̀, mo fún àwọn ọmọ Lefi gẹ́gẹ́ bí ogún wọn, ìdákan nínú ìdámẹ́wàá tí àwọn ọmọ Israẹli pèsè gẹ́gẹ́ bí ọrẹ sí Olúwa. Èyí ni mo wí nípa wọn. Wọn kò ní gba ogún kankan láàrín àwọn ọmọ Israẹli.”
- Numeri 18:25nǹkan bí 1471 ṣáájú Kristi
Olúwa sọ fún Mose pé,
- Numeri 18:26nǹkan bí 1471 ṣáájú Kristi
“Sọ fún àwọn ọmọ Lefi kí o sì wí fún wọn pé: ‘Nígbà tí ìdámẹ́wàá bá ń wọlé láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí ogún rẹ. O gbọdọ̀ mú ìdámẹ́wàá lára rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ Olúwa.
- Numeri 18:27nǹkan bí 1471 ṣáájú Kristi
A ó ka ọrẹ rẹ gẹ́gẹ́ bí ọkà irúgbìn láti ilẹ̀ ìpakà tàbí wáìnì láti fún wa.
- Numeri 18:28nǹkan bí 1471 ṣáájú Kristi
Báyìí ni ìwọ gan an náà yóò mú ọrẹ wa fún Olúwa láti ara ìdámẹ́wàá tí ìwọ gbà láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Israẹli. Láti ara ìdámẹ́wàá ó gbọdọ̀ mú ọrẹ Olúwa fún Aaroni àlùfáà.
- Numeri 18:29nǹkan bí 1471 ṣáájú Kristi
Ìwọ gbọdọ̀ mú wá gẹ́gẹ́ bí ìpín Olúwa èyí tí ó dára jùlọ àti tí ó jẹ́ mímọ́ jùlọ lára gbogbo nǹkan tí wọ́n mú wá fún ọ.’
- Numeri 18:30nǹkan bí 1471 ṣáájú Kristi
“Sọ fún àwọn ọmọ pé, ‘Nígbà tí ẹ̀yin bá mú ìpín tí ó dára jù wá, a ó kà á sí fún àwọn ọmọ Lefi gẹ́gẹ́ bí ìkórè láti ilẹ̀ ìpakà tàbí ìfúntí yín.
- Numeri 18:31nǹkan bí 1471 ṣáájú Kristi
Ìwọ àti àwọn ìdílé rẹ̀ le jẹ èyí tí ó kù ní ibikíbi gbogbo. Nítorí pé ó jẹ́ ọrẹ fún iṣẹ́ rẹ níbi àgọ́ ìpàdé.
- Numeri 18:32nǹkan bí 1471 ṣáájú Kristi
Nípa ṣíṣe ìgbékalẹ̀ ìpín tí ó dára jùlọ o kò ní jẹ̀bi lórí ọ̀rọ̀ yìí, ìwọ kò sì ní ba ọrẹ mímọ́ àwọn ọmọ Israẹli jẹ́, ìwọ kì yóò sì kú.’ ”
- Numeri 19:1nǹkan bí 1471 ṣáájú Kristi
Olúwa sọ fún Mose àti Aaroni pé,
- Numeri 19:2nǹkan bí 1471 ṣáájú Kristi
“Èyí ni ohun tí òfin Olúwa pàṣẹ béèrè lọ́wọ́ yín. Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli, kí wọn mú ẹgbọrọ ọ̀dọ́ màlúù pupa tí kò lábùkù tàbí àbàwọ́n, lára èyí tí a kò tí ì di àjàgà mọ́.
- Numeri 19:3nǹkan bí 1471 ṣáájú Kristi
Ẹ mú fún Eleasari àlùfáà, yóò sì mu jáde lọ sí ẹ̀yìn ibùdó kí ó sì pa á ní ojú rẹ.
- Numeri 19:4nǹkan bí 1471 ṣáájú Kristi
Nígbà náà ni Eleasari àlùfáà yóò mú lára ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sórí ìka ọwọ́ rẹ̀ yóò sì wọn lẹ́ẹ̀méje ní ọ̀kánkán iwájú àgọ́ ìpàdé.
- Numeri 19:5nǹkan bí 1471 ṣáájú Kristi
Ní ojú rẹ̀ ni àlùfáà yóò ti sun ọ̀dọ́ abo màlúù yìí: awọ ara rẹ̀, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ẹran-ara àti ìgbẹ́ rẹ̀.
- Numeri 19:6nǹkan bí 1471 ṣáájú Kristi
Àlùfáà yóò mú igi kedari, hísópù àti òwú òdòdó yóò sì jù wọ́n sí àárín ọ̀dọ́ abo màlúù tí a ń sun.
- Numeri 19:7nǹkan bí 1471 ṣáájú Kristi
Lẹ́yìn náà, àlùfáà gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ ara rẹ̀ pẹ̀lú omi lẹ́yìn náà ó lè wá sínú àgọ́. Ṣùgbọ́n yóò jẹ́ aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́.
- Numeri 19:8nǹkan bí 1471 ṣáájú Kristi
Ẹni tí ó sun ún náà gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀ kí ó sì wẹ̀ pẹ̀lú omi, òun náà yóò jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.
- Numeri 19:9nǹkan bí 1471 ṣáájú Kristi
“Ẹni tó wà ní mímọ́ ni yóò kó eérú ọ̀dọ́ màlúù náà lọ sí ibi tí a yà sí mímọ́ lẹ́yìn ibùdó. Kí gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli kó o pamọ́ fún lílò fún omi ìwẹ̀nùmọ́. Ó jẹ́ ìwẹ̀nùmọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀.
- Numeri 19:10nǹkan bí 1471 ṣáájú Kristi
Ọkùnrin tí ó kó eérú ọ̀dọ́ abo màlúù náà gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, òun náà yóò sì jẹ́ aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́. Èyí ni yóò jẹ́ ìlànà láéláé fún àwọn ọmọ Israẹli àti fún àwọn àjèjì tí ó ń gbé láàrín wọn.
- Numeri 19:11nǹkan bí 1471 ṣáájú Kristi
“Ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọwọ́ kan òkú ẹnikẹ́ni, yóò jẹ́ aláìmọ́ fún ọjọ́ méje.
- Numeri 19:12nǹkan bí 1471 ṣáájú Kristi
Ó gbọdọ̀ wẹ ara rẹ̀ pẹ̀lú omi ní ọjọ́ kẹta àti ní ọjọ́ keje; nígbà náà ni yóò jẹ́ mímọ́. Ṣùgbọ́n tí ó bá jẹ́ pé kò wẹ ara rẹ̀ mọ́ ní ọjọ́ kẹta àti ní ọjọ́ keje yóò jẹ́ aláìmọ́.
- Numeri 19:13nǹkan bí 1471 ṣáájú Kristi
Ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọwọ́ kan òkú ẹnìkan tí kò sì wẹ ara rẹ̀ mọ́, ó ba àgọ́ Olúwa jẹ́. A ó ké irú ẹni bẹ́ẹ̀ kúrò lára àwọn ọmọ Israẹli. Nítorí pé a kò tí ì wọ́n omi ìwẹ̀nùmọ́ lé e lórí, ó jẹ́ aláìmọ́, àìmọ́ rẹ̀ sì wà lára rẹ̀.
- Numeri 19:14nǹkan bí 1471 ṣáájú Kristi
“Èyí ni òfin tí ó jẹ mọ́ bí ènìyàn bá kú nínú àgọ́, ẹnikẹ́ni tí ó bá wọ inú àgọ́ àti ẹni tí ó wà nínú àgọ́ yóò di aláìmọ́ fún ọjọ́ méje,
- Numeri 19:15nǹkan bí 1471 ṣáájú Kristi
gbogbo ohun èlò tí a kò bá fi omọrí dé ni yóò jẹ́ aláìmọ́.