Fò sí àkóónú

circa 1446–1406 BC

The Wilderness Years

Forty years of wandering in the desert test Israel's faith and prepare a new generation to enter the promised land.

2,247 ẹsẹ · 2 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Numeri 7:5nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    “Gba gbogbo nǹkan wọ̀nyí lọ́wọ́ wọn, kí wọ́n ba à lè wúlò fún iṣẹ́ inú àgọ́ ìpàdé. Kó wọn fún àwọn ọmọ Lefi gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan bá ṣe nílò rẹ̀.”

  2. Numeri 7:6nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Mose sì kó àwọn kẹ̀kẹ́ ẹrù àti akọ màlúù náà fún àwọn ọmọ Lefi.

  3. Numeri 7:7nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Ó fún àwọn ọmọ Gerṣoni ní kẹ̀kẹ́ méjì àti akọ màlúù mẹ́rin, gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn ṣe jẹ mọ́.

  4. Numeri 7:8nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Ó fún àwọn ọmọ Merari ní kẹ̀kẹ́ mẹ́rin àti akọ màlúù mẹ́jọ gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn ṣe jẹ mọ́. Gbogbo wọn wà lábẹ́ àkóso Itamari ọmọ Aaroni tí í ṣe àlùfáà.

  5. Numeri 7:9nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n Mose kò fún àwọn ọmọ Kohati ní nǹkan kan nítorí pé èjìká wọn ni wọn yóò fi ru àwọn ohun mímọ́ èyí tí ó jẹ́ ojúṣe tiwọn.

  6. Numeri 7:10nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí a ta òróró sórí pẹpẹ. Àwọn olórí mú àwọn ọrẹ wọn wá fún ìyàsímímọ́ rẹ̀, wọ́n sì kó wọn wá síwájú pẹpẹ.

  7. Numeri 7:11nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Nítorí tí Olúwa ti sọ fún Mose pé, “Olórí kọ̀ọ̀kan ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ni yóò máa mú ọrẹ tirẹ̀ wá fún ìyàsímímọ́ pẹpẹ.”

  8. Numeri 7:12nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Ẹni tí ó mú ọrẹ tirẹ̀ wá ní ọjọ́ kìn-ín-ní Nahiṣoni ọmọ Amminadabu láti inú ẹ̀yà Juda.

  9. Numeri 7:13nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Ọrẹ rẹ̀ jẹ́: àwo fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje ṣékélì àti àwokòtò ti fàdákà tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin ṣékélì, méjèèjì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́ àwo kọ̀ọ̀kan kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára tí a fi òróró pò gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ;

  10. Numeri 7:14nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá tí ó kún fún tùràrí;

  11. Numeri 7:15nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    ọ̀dọ́ akọ màlúù kan, àgbò kan, akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun,

  12. Numeri 7:16nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀,

  13. Numeri 7:17nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    akọ màlúù méjì, àgbò márùn-ún, òbúkọ ọlọ́dún kan márùn-ún tí wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà. Wọ̀nyí ni ọrẹ Nahiṣoni ọmọ Amminadabu.

  14. Numeri 7:18nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Ní ọjọ́ kejì ni Netaneli ọmọ Suari olórí àwọn ọmọ Isakari mú ọrẹ tirẹ̀ wá.

  15. Numeri 7:19nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Ọrẹ tí ó kó wá ní: àwo fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje ṣékélì àti àwokòtò tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin ṣékélì, méjèèjì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́, àwo kọ̀ọ̀kan sì kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára tí á fi òróró pò gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ;

  16. Numeri 7:20nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá tí ó kún fún tùràrí,

  17. Numeri 7:21nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    ọ̀dọ́ akọ màlúù kan, àgbò kan, àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan, fún ẹbọ sísun;

  18. Numeri 7:22nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;

  19. Numeri 7:23nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Màlúù méjì, àgbò márùn-ún, akọ ewúrẹ́ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún tí wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà. Èyí ni ọrẹ Netaneli ọmọ Suari.

  20. Numeri 7:24nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Eliabu ọmọ Heloni, olórí àwọn ọmọ Sebuluni ni ó mú ọrẹ rẹ̀ wá ní ọjọ́ kẹta.

  21. Numeri 7:25nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Àwọn ọrẹ rẹ̀ ni: àwo fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje ṣékélì àti àwokòtò tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin ṣékélì, méjèèjì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́, àwo kọ̀ọ̀kan sì kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára tí á fi òróró pò gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ;

  22. Numeri 7:26nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá tí ó kún fún tùràrí;

  23. Numeri 7:27nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    akọ ọ̀dọ́ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun;

  24. Numeri 7:28nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;

  25. Numeri 7:29nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Màlúù méjì, àgbò márùn-ún, òbúkọ márùn-ún akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún tí wọn o fi rú ẹbọ àlàáfíà. Èyí ni ọrẹ Eliabu ọmọ Heloni.