Fò sí àkóónú

circa 1446–1406 BC

The Wilderness Years

Forty years of wandering in the desert test Israel's faith and prepare a new generation to enter the promised land.

2,247 ẹsẹ · 2 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Numeri 7:30nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Elisuri ọmọ Ṣedeuri olórí àwọn ọmọ Reubeni ni ó mú ọrẹ wá ní ọjọ́ kẹrin.

  2. Numeri 7:31nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Ọrẹ rẹ̀ ni: àwo fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje ṣékélì àti àwokòtò tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin ṣékélì, méjèèjì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́, àwo kọ̀ọ̀kan sì kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára tí á fi òróró pò gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ;

  3. Numeri 7:32nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá tí ó kún fún tùràrí,

  4. Numeri 7:33nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    akọ ọ̀dọ́ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun;

  5. Numeri 7:34nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;

  6. Numeri 7:35nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    màlúù méjì, àgbò márùn-ún, akọ ewúrẹ́ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún tí wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà. Èyí ni ọrẹ Elisuri ọmọ Ṣedeuri.

  7. Numeri 7:36nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Ṣelumieli ọmọ Suriṣaddai, olórí àwọn ọmọ Simeoni ni ó mú ọrẹ wá ní ọjọ́ karùn-ún.

  8. Numeri 7:37nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Ọrẹ tí ó kó wá ni: àwo fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje ṣékélì àti àwokòtò tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin ṣékélì, méjèèjì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́, àwo kọ̀ọ̀kan sì kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára tí á fi òróró pò gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ;

  9. Numeri 7:38nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá tí ó kún fún tùràrí;

  10. Numeri 7:39nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    akọ ọ̀dọ́ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun;

  11. Numeri 7:40nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;

  12. Numeri 7:41nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    màlúù méjì, àgbò márùn-ún, akọ ewúrẹ́ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún tí wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà. Èyí ni ọrẹ Ṣelumieli ọmọ Suriṣaddai.

  13. Numeri 7:42nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Eliasafu ọmọ Deueli olórí àwọn ọmọ Gadi ní ó mú ọrẹ rẹ̀ wá ní ọjọ́ kẹfà.

  14. Numeri 7:43nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Ọrẹ rẹ̀ ni: àwo fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje ṣékélì àti àwokòtò tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin ṣékélì, méjèèjì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́, àwo kọ̀ọ̀kan sì kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára tí á fi òróró pò gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ;

  15. Numeri 7:44nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá tí ó kún fún tùràrí;

  16. Numeri 7:45nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    akọ ọ̀dọ́ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun;

  17. Numeri 7:46nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;

  18. Numeri 7:47nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    màlúù méjì, àgbò márùn-ún, akọ ewúrẹ́ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún, wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà. Èyí ni ọrẹ Eliasafu ọmọ Deueli.

  19. Numeri 7:48nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Eliṣama ọmọ Ammihudu, olórí àwọn ọmọ Efraimu ni ó mú ọrẹ rẹ̀ wá ní ọjọ́ keje.

  20. Numeri 7:49nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Ọrẹ rẹ̀ ni: àwo fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje ṣékélì àti àwokòtò tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin ṣékélì, méjèèjì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́, àwo kọ̀ọ̀kan sì kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára tí á fi òróró pò gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ;

  21. Numeri 7:50nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá tí ó kún fún tùràrí;

  22. Numeri 7:51nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    akọ ọ̀dọ́ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun;

  23. Numeri 7:52nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;

  24. Numeri 7:53nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    màlúù méjì, àgbò márùn-ún, akọ ewúrẹ́ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún, tí wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà. Èyí ni ọrẹ Eliṣama ọmọ Ammihudu.

  25. Numeri 7:54nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Gamalieli ọmọ Pedasuri, olórí àwọn ọmọ Manase ni ó mú ọrẹ tirẹ̀ wá ní ọjọ́ kẹjọ.