Fò sí àkóónú

circa 1446–1406 BC

The Wilderness Years

Forty years of wandering in the desert test Israel's faith and prepare a new generation to enter the promised land.

2,247 ẹsẹ · 2 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Numeri 7:80nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá tí ó kún fún tùràrí;

  2. Numeri 7:81nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    akọ ọ̀dọ́ màlúù kan àgbò kan, àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun;

  3. Numeri 7:82nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;

  4. Numeri 7:83nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    màlúù méjì, àgbò márùn-ún, akọ ewúrẹ́ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún, wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà. Èyí ni ọrẹ Ahira ọmọ Enani.

  5. Numeri 7:84nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Wọ̀nyí ni ọrẹ tí àwọn olórí àwọn ọmọ Israẹli mú wá fún ìyàsímímọ́ pẹpẹ nígbà tí wọ́n ta òróró sí i lórí: àwo fàdákà méjìlá, àwokòtò méjìlá, àwo wúrà méjìlá.

  6. Numeri 7:85nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Àwo fàdákà kọ̀ọ̀kan wọn àádóje ṣékélì, àwokòtò kọ̀ọ̀kan sì wọn àádọ́rin. Àpapọ̀ gbogbo àwo fàdákà jẹ́ egbèjìlá (2,400) ṣékélì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́.

  7. Numeri 7:86nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwo wúrà méjìlá tí tùràrí kún inú wọn ṣékélì mẹ́wàá mẹ́wàá gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́. Àpapọ̀ ìwọ̀n gbogbo àwo wúrà jẹ́ ọgọ́fà ṣékélì.

  8. Numeri 7:87nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Àpapọ̀ iye ẹran fún ẹbọ sísun jẹ́ akọ ọ̀dọ́ màlúù méjìlá, àgbò méjìlá, akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan méjìlá pẹ̀lú ọrẹ ohun jíjẹ. Akọ ewúrẹ́ fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ jẹ́ méjìlá.

  9. Numeri 7:88nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Àpapọ̀ iye ẹran fún ọrẹ àlàáfíà jẹ́ màlúù mẹ́rìnlélógún, ọgọ́ta àgbò, ọgọ́ta akọ ewúrẹ́ àti ọgọ́ta akọ ọ̀dọ́ màlúù ọlọ́dún kan. Wọ̀nyí ni ọrẹ ìyàsímímọ́ pẹpẹ lẹ́yìn tí a ta òróró sí i.

  10. Numeri 7:89nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí Mose wọ inú àgọ́ ìpàdé láti bá Olúwa sọ̀rọ̀, Olúwa sì sọ̀rọ̀ sí i láti àárín àwọn kérúbù méjì láti orí ìtẹ́ àánú tí ó bo àpótí ẹ̀rí, ohùn náà sì bá Mose sọ̀rọ̀.

  11. Numeri 8:1nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Olúwa sọ fún Mose pé,

  12. Numeri 8:2nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    “Bá Aaroni sọ̀rọ̀ kí o wí fún un pé. ‘Nígbà tí ó bá ń to àwọn fìtílà, àwọn fìtílà méjèèje gbọdọ̀ tan ìmọ́lẹ̀ sí àyíká níwájú ọ̀pá fìtílà.’ ”

  13. Numeri 8:3nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Aaroni sì ṣe bẹ́ẹ̀; ó to àwọn fìtílà náà tí wọ́n sì fi kojú síwájú lórí ọ̀pá fìtílà gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

  14. Numeri 8:4nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Bí a ṣe ṣe ọ̀pá fìtílà náà nìyìí, a ṣe é láti ara wúrà lílù: láti ìsàlẹ̀ títí dé ibi ìtànná rẹ̀. Wọ́n ṣe ọ̀pá fìtílà náà gẹ́gẹ́ bí bátànì tí Olúwa fihan Mose.

  15. Numeri 8:5nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Olúwa sọ fún Mose pé,

  16. Numeri 8:6nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    “Yọ àwọn ọmọ Lefi kúrò láàrín àwọn ọmọ Israẹli yòókù, kí o sì wẹ̀ wọ́n mọ́.

  17. Numeri 8:7nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Báyìí ni kí o ṣe wẹ̀ wọ́n mọ́. Wọ́n omi ìwẹ̀nùmọ́ sí wọn lára, mú kí wọn ó fá irun ara wọn, kí wọn ó fọ aṣọ wọn, kí wọn ó ba à lè wẹ ara wọn mọ́ nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀.

  18. Numeri 8:8nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Jẹ́ kí wọn ó mú akọ ọ̀dọ́ màlúù pẹ̀lú ẹbọ ohun jíjẹ rẹ̀ tí í ṣe ìyẹ̀fun ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára tí a fi òróró pò, kí ìwọ náà mú akọ ọ̀dọ́ màlúù kejì fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀.

  19. Numeri 8:9nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Ìwọ ó sì mú àwọn ọmọ Lefi wá síwájú àgọ́ ìpàdé, kí o sì kó gbogbo àpapọ̀ ọmọ Israẹli jọ síbẹ̀ pẹ̀lú.

  20. Numeri 8:10nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Báyìí ni kí o mú àwọn ọmọ Lefi wá síwájú Olúwa, gbogbo ọmọ Israẹli yóò sì gbọ́wọ́ lé àwọn ọmọ Lefi lórí.

  21. Numeri 8:11nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Aaroni yóò sì mú àwọn ọmọ Lefi wá síwájú Olúwa gẹ́gẹ́ bí ọrẹ fífì láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Israẹli wá, kí wọn lè máa ṣiṣẹ́ Olúwa.

  22. Numeri 8:12nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    “Lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Lefi bá gbé ọwọ́ wọn lé orí àwọn akọ ọmọ màlúù náà, ìwọ yóò sì fi ọ̀kan rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti èkejì fún ẹbọ sísun sí Olúwa, láti ṣe ètùtù fún àwọn ọmọ Lefi.

  23. Numeri 8:13nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Mú kí àwọn ọmọ Lefi dúró níwájú Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ kí ó sì gbé wọn kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ fífì sí Olúwa.

  24. Numeri 8:14nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Báyìí ni ìwọ yóò ṣe ya ọmọ Lefi sọ́tọ̀, kúrò láàrín àwọn ọmọ Israẹli yòókù, àwọn ọmọ Lefi yóò sì jẹ́ tèmi.

  25. Numeri 8:15nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    “Lẹ́yìn tí ó ti wẹ àwọn ọmọ Lefi mọ́, tí ó sì ti gbé wọn kalẹ̀ bí ẹbọ fífì nígbà náà ni kí wọn ó lọ máa ṣiṣẹ́ nínú àgọ́ ìpàdé.