circa 6 BC – AD 30
The Life of Jesus
The eternal Son of God enters history: born in Bethlehem, baptized in the Jordan, crucified at Golgotha, raised on the third day.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Luku 21:19nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nínú ìdúró ṣinṣin yín ni ẹ̀yin ó jèrè ọkàn yín.
- Luku 21:20nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
“Nígbà tí ẹ̀yin bá sì rí ti a fi ogun yí Jerusalẹmu ká, ẹ mọ̀ nígbà náà pé, ìsọdahoro rẹ̀ kù sí dẹ̀dẹ̀.
- Luku 21:21nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nígbà náà ni kí àwọn tí ń bẹ ní Judea sálọ sórí òkè; àti àwọn tí ń bẹ láàrín rẹ̀ kí wọn jáde kúrò; kí àwọn tí ó sì ń bọ̀ ní ìgbèríko má ṣe wọ inú rẹ̀ wá.
- Luku 21:22nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nítorí ọjọ́ ẹ̀san ni ọjọ́ wọ̀nyí, kì a lè mú ohun gbogbo tí a ti kọ̀wé rẹ̀ ṣẹ.
- Luku 21:23nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ṣùgbọ́n ègbé ni fún àwọn tí ó lóyún, àti àwọn tí ó fi ọyàn fún ọmọ mu ní ọjọ́ wọ̀nyí! Nítorí tí ìpọ́njú púpọ̀ yóò wà lórí ilẹ̀ àti ìbínú sí àwọn ènìyàn wọ̀nyí.
- Luku 21:24nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Wọn ó sì ti ojú idà ṣubú, a ó sì dìwọ́n ní ìgbèkùn lọ sí orílẹ̀-èdè gbogbo; Jerusalẹmu yóò sì di ìtẹ̀mọ́lẹ̀ lẹ́sẹ̀ àwọn aláìkọlà, títí àkókò àwọn aláìkọlà yóò fi kún.
- Luku 21:25nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
“Àmì yóò sì wà ní oorun, àti ní òṣùpá, àti ní ìràwọ̀; àti lórí ilẹ̀ ayé ìdààmú fún àwọn orílẹ̀-èdè nínú ìpayà híhó Òkun àti ìgbì omi.
- Luku 21:26nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Àyà àwọn ènìyàn yóò máa já fún ìbẹ̀rù, àti ìrètí nǹkan wọ̀nyí tí ń bọ̀ sórí ayé: nítorí àwọn agbára ọ̀run ni a ó mì tìtì.
- Luku 21:27nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nígbà náà ni wọn ó sì rí Ọmọ Ènìyàn tí yóò máa bọ̀ wá nínú àwọsánmọ̀ pẹ̀lú agbára àti ògo ńlá.
- Luku 21:28nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ṣùgbọ́n nígbà tí nǹkan wọ̀nyí bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹ, ǹjẹ́ kí ẹ wo òkè, kí ẹ sì gbé orí yín sókè; nítorí ìdáǹdè yín kù sí dẹ̀dẹ̀.”
- Luku 21:29nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ó sì pa òwe kan fún wọn pé, “Ẹ kíyèsi igi ọ̀pọ̀tọ́, àti sí gbogbo igi.
- Luku 21:30nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nígbà tí wọ́n bá rúwé, ẹ̀yin rí i, ẹ sì mọ̀ fúnra ara yín pé, ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn kù fẹ́ẹ́rẹ́.
- Luku 21:31nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ náà ni ẹ̀yin, nígbà tí ẹ̀yin bá rí nǹkan wọ̀nyí tí o ṣẹ, kí ẹ̀yin mọ̀ pé, ìjọba Ọlọ́run kù sí dẹ̀dẹ̀.
- Luku 21:32nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
“Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ìran yìí kì yóò rékọjá, títí gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò fi ṣẹ.
- Luku 21:33nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ọ̀run àti ayé yóò rékọjá, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ mi kì yóò rékọjá.
- Luku 21:34nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
“Ṣùgbọ́n ẹ máa kíyèsára yín, kí ọkàn yín má ṣe kún fún wọ̀bìà, àti fún ọtí àmupara, àti fún àníyàn ayé yìí, tí ọjọ́ náà yóò sì fi dé bá yín lójijì bí ìkẹ́kùn.
- Luku 21:35nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nítorí bẹ́ẹ̀ ni yóò dé bá gbogbo àwọn tí ń gbé orí gbogbo ilẹ̀ ayé.
- Luku 21:36nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ǹjẹ́ kì ẹ máa ṣọ́nà, kí ẹ sì máa gbàdúrà nígbà gbogbo, kí ẹ ba à lè la gbogbo nǹkan wọ̀nyí tí yóò ṣẹlẹ̀, kí ẹ sì lè dúró níwájú Ọmọ Ènìyàn.”
- Luku 21:37nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Lọ́sàn án, Jesu a sì máa kọ́ni ní tẹmpili, lóru, a sì máa jáde lọ í wọ̀ ní òkè tí à ń pè ní Òkè Olifi.
- Luku 21:38nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Gbogbo ènìyàn sì ń tọ̀ ọ́ wá ní tẹmpili ní kùtùkùtù òwúrọ̀, láti gbọ́rọ̀ rẹ̀.
- Luku 22:1nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Àjọ ọdún àìwúkàrà tí à ń pè ní Ìrékọjá sì kù fẹ́ẹ́rẹ́.
- Luku 22:2nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Àti àwọn olórí àlùfáà, àti àwọn akọ̀wé ń wá ọ̀nà tí wọn ìbá gbà pa á; nítorí tí wọn ń bẹ̀rù àwọn ènìyàn.
- Luku 22:3nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Satani sì wọ inú Judasi, tí à ń pè ní Iskariotu, ọ̀kan nínú àwọn méjìlá.
- Luku 22:4nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ó sì mú ọ̀nà rẹ̀ pọ̀n, ó lọ láti bá àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olórí ẹ̀ṣọ́ gbèrò pọ̀, bí òun yóò tí fi í lé wọn lọ́wọ́.
- Luku 22:5nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Wọ́n sì yọ̀, wọ́n sì bá a dá májẹ̀mú láti fún un ní owó.