Fò sí àkóónú

circa 6 BC – AD 30

The Life of Jesus

The eternal Son of God enters history: born in Bethlehem, baptized in the Jordan, crucified at Golgotha, raised on the third day.

3,779 ẹsẹ · 4 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Luku 20:16nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Yóò wá, yóò sì pa àwọn alágbàtọ́jú náà run, yóò sì fi ọgbà àjàrà náà fún àwọn ẹlòmíràn.” Nígbà tí wọ́n sì gbọ́, wọ́n ní, “Kí a má ri i!”

  2. Luku 20:17nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí ó sì wò wọ́n, ó ní, “Èwo ha ni èyí tí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé: “ ‘Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀sílẹ̀, òun náà ni ó di pàtàkì igun ilé’?

  3. Luku 20:18nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ẹnikẹ́ni tí ó ṣubú lu òkúta náà yóò fọ́; ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí òun bá ṣubú lù, yóò lọ̀ ọ́ lúúlúú.”

  4. Luku 20:19nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé ń wá ọ̀nà láti mú un ní wákàtí náà; ṣùgbọ́n wọ́n bẹ̀rù àwọn ènìyàn, nítorí tí wọ́n mọ̀ pé, ó pa òwe yìí mọ́ wọn.

  5. Luku 20:20nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Wọ́n sì ń ṣọ́ ọ, wọ́n sì rán àwọn ayọ́lẹ̀wò tí wọ́n ṣe ara wọn bí ẹni pé olóòtítọ́ ènìyàn, kí wọn ba à lè gbá ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú, kí wọn ba à lè fi í lé agbára àti àṣẹ Baálẹ̀ lọ́wọ́.

  6. Luku 20:21nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Wọ́n sì bí i, pé, “Olùkọ́ àwa mọ̀ pé, ìwọ a máa sọ̀rọ̀ fún ni, ìwọ a sì máa kọ́ni bí ó ti tọ́, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kì í ṣe ojúsàájú ẹnìkan ṣùgbọ́n ìwọ ń kọ́ni ní ọ̀nà Ọlọ́run lóòtítọ́.

  7. Luku 20:22nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ǹjẹ́ ó tọ́ fún wa láti máa san owó òde fún Kesari, tàbí kò tọ́?”

  8. Luku 20:23nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n ó kíyèsi àrékérekè wọn, ó sì wí fún wọn pé,

  9. Luku 20:24nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    “Ẹ fi owó idẹ kan hàn mí. Àwòrán àti àkọlé ti ta ni ó wà níbẹ̀?” Wọ́n sì dá a lóhùn pé, “Ti Kesari ni.”

  10. Luku 20:25nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ó sì wí fún wọn pé, “Ǹjẹ́ ẹ fi ohun tí i ṣe ti Kesari fún Kesari, àti ohun tí í ṣe ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.”

  11. Luku 20:26nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Wọn kò sì lè gbá ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú níwájú àwọn ènìyàn: ẹnu sì yà wọ́n sí ìdáhùn rẹ̀, wọ́n sì pa ẹnu wọn mọ́.

  12. Luku 20:27nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Àwọn Sadusi kan sì tọ̀ ọ́ wá, àwọn tí wọ́n ń wí pé àjíǹde òkú kò sí wọ́n sì bi í,

  13. Luku 20:28nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    wí pé, “Olùkọ́, Mose kọ̀wé fún wa pé, Bí arákùnrin ẹnìkan bá kú, ní àìlọ́mọ, tí ó sì ní aya, kí arákùnrin rẹ̀ ṣú aya rẹ̀ lópó, kí ó lè gbé irú-ọmọ dìde fún arákùnrin rẹ̀.

  14. Luku 20:29nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ǹjẹ́ àwọn arákùnrin méje kan ti wà; èkínní gbé ìyàwó, ó sì kú ní àìlọ́mọ.

  15. Luku 20:30nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Èkejì sì ṣú u lópó: òun sì kú ní àìlọ́mọ.

  16. Luku 20:31nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ẹ̀kẹta sì ṣú u lópó: gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn méjèèje pẹ̀lú: wọn kò sì fi ọmọ sílẹ̀, wọ́n sì kú.

  17. Luku 20:32nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nígbẹ̀yìn pátápátá obìnrin náà kú pẹ̀lú.

  18. Luku 20:33nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ǹjẹ́ ní àjíǹde òkú, aya ti ta ni yóò ha ṣe nínú wọn? Nítorí àwọn méjèèje ni ó sá à ni í ní aya.”

  19. Luku 20:34nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Jesu sì dáhùn ó wí fún wọn pé, “Àwọn ọmọ ayé yìí a máa gbéyàwó, wọn a sì máa fa ìyàwó fún ni.

  20. Luku 20:35nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n àwọn tí a kà yẹ láti jogún ìyè ayérayé náà, àti àjíǹde kúrò nínú òkú, wọn kì í gbéyàwó, wọn kì í sì í fa ìyàwó fún ni.

  21. Luku 20:36nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí wọn kò lè kú mọ́; nítorí tí wọn bá àwọn angẹli dọ́gba; àwọn ọmọ Ọlọ́run sì ni wọ́n, nítorí wọ́n di àwọn ọmọ àjíǹde.

  22. Luku 20:37nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ní ti pé a ń jí àwọn òkú dìde, Mose tìkára rẹ̀ sì ti fihàn nínú igbó, nígbà tí ó pe ‘Olúwa ni Ọlọ́run Abrahamu, àti Ọlọ́run Isaaki, àti Ọlọ́run Jakọbu.’

  23. Luku 20:38nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Bẹ́ẹ̀ ni òun kì í ṣe Ọlọ́run àwọn òkú, bí kò ṣe ti àwọn alààyè, nítorí gbogbo wọn wà láààyè fún un.”

  24. Luku 20:39nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà náà ni àwọn kan nínú àwọn akọ̀wé dá a lóhùn, pé, “Olùkọ́ ìwọ wí rere!”

  25. Luku 20:40nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Wọn kò sì jẹ́ bi í léèrè ọ̀rọ̀ kan mọ́.