circa 6 BC – AD 30
The Life of Jesus
The eternal Son of God enters history: born in Bethlehem, baptized in the Jordan, crucified at Golgotha, raised on the third day.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Luku 22:6nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ó sì gbà; ó sì ń wá àkókò tí ó wọ̀, láti fi í lé wọn lọ́wọ́ láìsí ariwo.
- Luku 22:7nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ọjọ́ àìwúkàrà pé, nígbà tí wọ́n ní láti pa ọ̀dọ́-àgùntàn ìrékọjá fún ìrúbọ.
- Luku 22:8nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ó sì rán Peteru àti Johanu, wí pé, “Ẹ lọ pèsè ìrékọjá fún wa, kí àwa ó jẹ.”
- Luku 22:9nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Wọ́n sì wí fún un pé, “Níbo ni ìwọ ń fẹ́ kí á pèsè sílẹ̀?”
- Luku 22:10nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ó sì wí fún wọn pé, “Kíyèsi i, nígbà tí ẹ̀yin bá ń wọ ìlú lọ, ọkùnrin kan tí ó ru ìkòkò omi yóò pàdé yín, ẹ bá a lọ sí ilé tí ó bá wọ̀,
- Luku 22:11nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
kí ẹ sì wí fún baálé ilé náà pé, ‘Olùkọ́ wí fún ọ pé, níbo ni gbàngàn àpèjẹ náà gbé wà, níbi tí èmi ó gbé jẹ ìrékọjá pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mi?’
- Luku 22:12nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Òun ó sì fi gbàngàn ńlá kan lókè ilé hàn yín, tí a ṣe lọ́ṣọ̀ọ́, níbẹ̀ ni kí ẹ̀yin pèsè sílẹ̀.”
- Luku 22:13nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Wọ́n sì lọ wọ́n sì bá a gẹ́gẹ́ bí ó tí sọ fún wọn, wọ́n sì pèsè ìrékọjá sílẹ̀.
- Luku 22:14nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nígbà tí àkókò sì tó, ó jókòó àti àwọn aposteli pẹ̀lú rẹ̀.
- Luku 22:15nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ó sì wí fún wọn pé, “Tinútinú ni èmi fẹ́ fi bá yín jẹ ìrékọjá yìí, kí èmi tó jìyà.
- Luku 22:16nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nítorí mo wí fún yín, Èmi kì yóò jẹ nínú rẹ̀ mọ́, títí a ó fi mú un ṣẹ ní ìjọba Ọlọ́run.”
- Luku 22:17nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ó sì gba ago, nígbà tí ó sì ti dúpẹ́, ó wí pé, “Gba èyí, kí ẹ sì pín in láàrín ara yín.
- Luku 22:18nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nítorí mo wí fún yín, Èmi kì yóò mu nínú èso àjàrà mọ́, títí ìjọba Ọlọ́run yóò fi dé.”
- Luku 22:19nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ó sì mú àkàrà, nígbà tí ó sì ti dúpẹ́ ó bù ú, ó sì fi fún wọn, ó wí pé, “Èyí ni ara mí tí a fi fún yín, ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.”
- Luku 22:20nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ lẹ́yìn oúnjẹ alẹ́, ó sì mú ago wáìnì, ó wí pé, “Ago yìí ni májẹ̀mú tuntun nínú ẹ̀jẹ̀ mi, tí a ta sílẹ̀ fún yín.
- Luku 22:21nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsi i, ọwọ́ ẹni tí yóò fi mí hàn wà pẹ̀lú mi lórí tábìlì.
- Luku 22:22nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ọmọ Ènìyàn ń lọ nítòótọ́ bí a tí pinnu rẹ̀, ṣùgbọ́n ègbé ni fún ọkùnrin náà nípasẹ̀ ẹni tí a gbé ti fi í hàn.”
- Luku 22:23nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí béèrè láàrín ara wọn, ta ni nínú wọn tí yóò ṣe nǹkan yìí.
- Luku 22:24nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ìjà kan sì ń bẹ láàrín wọn, ní ti ẹni tí a kà sí olórí nínú wọn.
- Luku 22:25nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ó sì wí fún wọn pé, “Àwọn ọba aláìkọlà a máa fẹlá lórí wọn, a sì máa pe àwọn aláṣẹ wọn ní olóore.
- Luku 22:26nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kì yóò rí bẹ́ẹ̀; ṣùgbọ́n ẹni tí ó ba pọ̀jù nínú yín kí ó jẹ́ bí ẹni tí o kéré ju àbúrò; ẹni tí ó sì ṣe olórí, bí ẹni tí ń ṣe ìránṣẹ́.
- Luku 22:27nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nítorí ta ni ó pọ̀jù, ẹni tí ó jókòó tí oúnjẹ, tàbí ẹni tí ó ń ṣe ìránṣẹ́. Ẹni tí ó jókòó ti oúnjẹ kọ́ bí? Ṣùgbọ́n èmi ń bẹ láàrín yín bí ẹni tí ń ṣe ìránṣẹ́.
- Luku 22:28nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ẹ̀yin ni àwọn tí ó ti dúró tì mí nínú ìdánwò mi.
- Luku 22:29nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Mo sì yan ìjọba fún yín, gẹ́gẹ́ bí Baba mi ti yàn fún mi.
- Luku 22:30nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Kí ẹ̀yin lè máa jẹ, kí ẹ̀yin sì lè máa mu lórí tábìlì mi ní ìjọba mi, kí ẹ̀yin lè jókòó lórí ìtẹ́, àti kí ẹ̀yin lè máa ṣe ìdájọ́ fún àwọn ẹ̀yà Israẹli méjìlá.”