- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 1380–1050 BC
The Judges & Ruth
Israel cycles through rebellion, oppression, and rescue under charismatic leaders—culminating in Ruth's faithful love story.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Onidajọ 8:16nǹkan bí 1245 ṣáájú Kristi
Ó mú àwọn àgbàgbà ìlú náà, ó sì fi kọ́ àwọn Sukkoti lọ́gbọ́n nípa jíjẹ wọ́n ní yà pẹ̀lú àwọn ẹ̀gún ijù àti ẹ̀gún ọ̀gàn.
- Onidajọ 8:17nǹkan bí 1245 ṣáájú Kristi
Ó wó ilé ìṣọ́ Penieli, ó sì pa àwọn ọkùnrin ìlú náà.
- Onidajọ 8:18nǹkan bí 1245 ṣáájú Kristi
Gideoni bi Seba àti Salmunna pé, “Irú ọkùnrin tí ẹ pa ní Tabori, báwo ni wọ́n ṣe rí?” “Àwọn ọkùnrin náà dàbí rẹ ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn dàbí ọmọ ọba,” ní ìdáhùn wọn.
- Onidajọ 8:19nǹkan bí 1245 ṣáájú Kristi
Gideoni dáhùn pé, “Arákùnrin mi ni wọ́n, àwọn ọmọ ìyá mi. Mo fi Olúwa búra, bí ó bá ṣe pé ẹ dá ẹ̀mí wọn sí, èmi náà ò nípa yín.”
- Onidajọ 8:20nǹkan bí 1245 ṣáájú Kristi
Ó yí padà sí Jeteri, ọmọ rẹ̀ tí ó dàgbà jùlọ, ó wí fún un pé, “Pa wọ́n!” Ṣùgbọ́n Jeteri kò fa idà rẹ̀ yọ láti pa wọ́n nítorí ó jẹ́ ọ̀dọ́mọdé ẹ̀rù sì bà á láti pa wọ́n.
- Onidajọ 8:21nǹkan bí 1245 ṣáájú Kristi
Seba àti Salmunna dá Gideoni lóhùn pé, “Wá pa wá fún raàrẹ, ‘Nítorí bí ènìyàn bá ti rí bẹ́ẹ̀ ni agbára rẹ̀ yóò rí.’ ” Gideoni bọ́ síwájú ó sì pa wọ́n, ó sì mú ohun ọ̀ṣọ́ tí ó wà ní ọrùn àwọn ìbákasẹ wọn.
- Onidajọ 8:22nǹkan bí 1245 ṣáájú Kristi
Àwọn ará Israẹli wí fún Gideoni pé, “Jọba lórí wa—ìwọ, àwọn ọmọ rẹ àti àwọn ọmọ ọmọ rẹ pẹ̀lú, nítorí tí ìwọ ti gbà wá lọ́wọ́ àwọn ará Midiani.”
- Onidajọ 8:23nǹkan bí 1245 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n Gideoni dá wọn lóhùn pé, “Èmi kì yóò jẹ ọba lórí yín, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ mi kì yóò jẹ ọba lórí yín. Olúwa ni yóò jẹ ọba lórí yín.”
- Onidajọ 8:24nǹkan bí 1245 ṣáájú Kristi
Gideoni sì wí pé, “Mo ní ẹ̀bẹ̀ kan tí mo fẹ́ bẹ̀ yín kí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín fún mi ní yẹtí kọ̀ọ̀kan láti inú ohun ti ó kàn yín láti inú ìkógun.” (Àṣà àwọn ará Iṣmaeli ni láti máa fi yẹtí wúrà sétí.)
- Onidajọ 8:25nǹkan bí 1245 ṣáájú Kristi
Wọ́n dáhùn pé, “Tayọ̀tayọ̀ ni àwa yóò fi wọ́n sílẹ̀.” Wọ́n tẹ́ aṣọ kan sílẹ̀ ọkùnrin kọ̀ọ̀kan sì ń sọ yẹtí kọ̀ọ̀kan tí ó kàn wọ́n láti ibi ìkógun síbẹ̀.
- Onidajọ 8:26nǹkan bí 1245 ṣáájú Kristi
Ìwọ̀n òrùka wúrà tí ó béèrè fún tó ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀sán (1,700) ìwọ̀n ṣékélì, láìka àwọn ohun ọ̀ṣọ́ àti ohun sísorọ̀ tí ó wà lára ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn àti aṣọ elése àlùkò tí àwọn ọba Midiani ń wọ̀ tàbí àwọn ẹ̀wọ̀n tí ó wà ní ọrùn àwọn ìbákasẹ wọn.
- Onidajọ 8:27nǹkan bí 1245 ṣáájú Kristi
Gideoni fi àwọn wúrà náà ṣe efodu èyí tí ó gbé kalẹ̀ ní Ofira ìlú rẹ̀. Àwọn ọmọ Israẹli sì sọ ara wọn di àgbèrè nípa sínsin-ín ní ibẹ̀. Ó sì di ìdẹ̀kùn fún Gideoni àti ìdílé rẹ̀.
- Onidajọ 8:28nǹkan bí 1245 ṣáájú Kristi
Báyìí ni a ṣe tẹrí àwọn ará Midiani ba níwájú àwọn ọmọ Israẹli bẹ́ẹ̀ ni wọn kò tún gbé orí mọ́. Ní ọjọ́ Gideoni, Israẹli wà ní àlàáfíà fún ogójì ọdún.
- Onidajọ 8:29nǹkan bí 1245 ṣáájú Kristi
Jerubbaali ọmọ Joaṣi padà lọ láti máa gbé ní ìlú rẹ̀.
- Onidajọ 8:30nǹkan bí 1245 ṣáájú Kristi
Àádọ́rin ọmọ ni Gideoni bí, nítorí ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìyàwó.
- Onidajọ 8:31nǹkan bí 1245 ṣáájú Kristi
Àlè rẹ̀, tó ń gbé ní Ṣekemu, pàápàá bí ọmọkùnrin kan fún un tí ó pe orúkọ rẹ̀ ní Abimeleki.
- Onidajọ 8:32nǹkan bí 1245 ṣáájú Kristi
Gideoni ọmọ Joaṣi kú ní ògbólógbòó ọjọ́ rẹ̀, ó sì pọ̀ ní ọjọ́ orí, wọ́n sì sin ín sí ibojì baba rẹ̀ ní Ofira ti àwọn ará Abieseri.
- Onidajọ 8:33nǹkan bí 1245 ṣáájú Kristi
Láìpẹ́ jọjọ lẹ́yìn ikú Gideoni ni àwọn ará Israẹli ṣe àgbèrè tọ Baali lẹ́yìn, wọ́n fi Baali-Beriti ṣe òrìṣà wọn.
- Onidajọ 8:34nǹkan bí 1245 ṣáájú Kristi
Wọn kò sì rántí Olúwa Ọlọ́run wọn, ẹni tí ó gbà wọ́n kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn gbogbo tí ó wà ní gbogbo àyíká wọn.
- Onidajọ 8:35nǹkan bí 1245 ṣáájú Kristi
Wọ́n kùnà láti fi inú rere hàn sí ìdílé Jerubbaali (èyí ni Gideoni) fún gbogbo oore tí ó ṣe fún wọn.
Ní ọjọ́ kan Abimeleki ọmọ Jerubbaali lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin ìyá rẹ̀ ní Ṣekemu ó sì bá wọn sọ̀rọ̀ àti gbogbo àwọn ìbátan ìyá rẹ̀ wí pé,
“Ẹ bi gbogbo àwọn ará Ṣekemu léèrè, ‘Èwo ló sàn fún un yín, ṣé kí gbogbo àwọn àádọ́rin ọmọ Jerubbaali jẹ ọba lórí yín ni tàbí kí ẹnìkan ṣoṣo ṣe àkóso yín?’ Ṣùgbọ́n ẹ rántí pé ẹran-ara yín àti ẹ̀jẹ̀ yín ni èmi ń ṣe.”
Nígbà tí àwọn arákùnrin rẹ̀ sọ èyí ní etí àwọn ará Ṣekemu, ọkàn wọn fà sí àti tẹ̀lé Abimeleki torí, wọ́n sọ wí pé, “Arákùnrin wa ní í ṣe.”
Wọ́n fún un ní àádọ́rin ṣékélì fàdákà láti ilé òrìṣà Baali-Beriti, Abimeleki fi owó náà gba àwọn jàǹdùkú àti aláìníláárí ènìyàn tí wọ́n sì di olùtẹ̀lé rẹ̀.
Ó kó wọn lọ sí ilé baba rẹ̀ ní Ofira, níbẹ̀ ní orí òkúta kan ṣoṣo ni ó ti pa àádọ́rin nínú àwọn arákùnrin rẹ̀, àwọn Jerubbaali, ṣùgbọ́n Jotamu, àbíkẹ́yìn nínú àwọn ọmọ Jerubbaali, bọ́ yọ nítorí pé ó sá pamọ́.