Fò sí àkóónú

Creation Era

Creation & The Fall

God creates the heavens and earth, forming humanity in his image before sin enters the world.

138 ẹsẹ · 1 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

  1. Gẹnẹsisi 4:21nǹkan bí 4003 ṣáájú Kristi

    Orúkọ arákùnrin rẹ̀ ni Jubali, òun ni baba irú àwọn tí ń tẹ dùùrù tí wọ́n sì ń fọn fèrè.

  2. Gẹnẹsisi 4:22nǹkan bí 4003 ṣáájú Kristi

    Silla náà sì bí ọmọkùnrin tí ń jẹ́ Tubali-Kaini, tí ó ń rọ oríṣìíríṣìí ohun èlò láti ara idẹ àti irin. Arábìnrin Tubali-Kaini ni Naama.

  3. Gẹnẹsisi 4:23nǹkan bí 4003 ṣáájú Kristi

    Lameki wí fún àwọn aya rẹ̀, “Adah àti Silla, ẹ tẹ́tí sí mi; ẹ̀yin aya Lameki, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi. Mo ti pa ọkùnrin kan tí ó kọlù mí, ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó pa mí lára.

  4. Gẹnẹsisi 4:24nǹkan bí 4003 ṣáájú Kristi

    Bí a ó bá gbẹ̀san Kaini ní ìgbà méje, ǹjẹ́ kí a gba ti Lameki nígbà mẹ́tàdínlọ́gọ́rin (77).”

  5. Gẹnẹsisi 4:25nǹkan bí 4003 ṣáájú Kristi

    Adamu sì tún bá aya rẹ̀ lòpọ̀, ó sì bí ọmọkùnrin kan tí ó pe orúkọ rẹ̀ ní Seti, tí ó túmọ̀ sí pé, “Ọlọ́run fún mi ní ọmọkùnrin mìíràn ní ipò Abeli tí Kaini pa.”

  6. Gẹnẹsisi 4:26nǹkan bí 3769 ṣáájú Kristi

    Seti náà sì bí ọmọkùnrin kan, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Enoṣi. Láti àkókò náà lọ ni àwọn ènìyàn ti bẹ̀rẹ̀ sí ní ké pe orúkọ Olúwa.

  7. Èyí ni àkọsílẹ̀ ìran Adamu. Nígbà tí Ọlọ́run dá ènìyàn, ní àwòrán Ọlọ́run ni ó dá a.

  8. Àti akọ àti abo ni Ó dá wọn, ó sì súre fún wọn, ó sì pe orúkọ wọ́n ní Adamu ní ọjọ́ tí ó dá wọn.

  9. Gẹnẹsisi 5:3nǹkan bí 3874 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí Adamu di ẹni àádóje ọdún, ó bí ọmọkùnrin kan tí ó jọ ọ́, tí ó jẹ́ àwòrán ara rẹ̀, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Seti.

  10. Gẹnẹsisi 5:4nǹkan bí 3874 ṣáájú Kristi

    Ọjọ́ Adamu, lẹ́yìn ìgbà tí ó bí Seti, jẹ́ ẹgbẹ̀rin (800) ọdún, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin.

  11. Gẹnẹsisi 5:5nǹkan bí 3074 ṣáájú Kristi

    Àpapọ̀ ọdún tí Adamu gbé ní orí ilẹ̀ jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún ọdún ó lé ọgbọ̀n (930), ó sì kú.

  12. Gẹnẹsisi 5:6nǹkan bí 3769 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí Seti pé àrùnlélọ́gọ́rùn-ún ọdún, ó bí Enoṣi.

  13. Gẹnẹsisi 5:7nǹkan bí 3769 ṣáájú Kristi

    Lẹ́yìn ìgbà tí ó bí Enoṣi, Seti sì gbé fún ẹgbẹ̀rin ọdún ó lé méje (807), ó sì bí àwọn; ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin.

  14. Gẹnẹsisi 5:8nǹkan bí 2962 ṣáájú Kristi

    Àpapọ̀ ọdún Seti sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún ọdún ó lé méjìlá (912), ó sì kú.

  15. Gẹnẹsisi 5:9nǹkan bí 3679 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí Enoṣi di ẹni àádọ́rùn-ún ọdún ni ó bí Kenani.

  16. Gẹnẹsisi 5:10nǹkan bí 3679 ṣáájú Kristi

    Lẹ́yìn tí ó bí Kenani, Enoṣi sì wà láààyè fún ẹgbẹ̀rin ọdún ó lé mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (815), ó sì bí àwọn ọkùnrin àti obìnrin.

  17. Gẹnẹsisi 5:11nǹkan bí 2864 ṣáájú Kristi

    Àpapọ̀ ọdún Enoṣi jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún ọdún ó lé márùn-ún (905), ó sì kú.

  18. Gẹnẹsisi 5:12nǹkan bí 3609 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí Kenani di àádọ́rin ọdún ni ó bí Mahalaleli.

  19. Gẹnẹsisi 5:13nǹkan bí 3609 ṣáájú Kristi

    Lẹ́yìn tí ó bí Mahalaleli, Kenani wà láààyè fún òjìlélẹ́gbẹ̀rin ọdún (840), ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin.

  20. Gẹnẹsisi 5:14nǹkan bí 2769 ṣáájú Kristi

    Àpapọ̀ ọjọ́ Kenani jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún ọdún ó lé mẹ́wàá (910), ó sì kú.

  21. Gẹnẹsisi 5:15nǹkan bí 3544 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí Mahalaleli pé ọmọ àrùnlélọ́gọ́ta ọdún ni ó bí Jaredi.

  22. Gẹnẹsisi 5:16nǹkan bí 3544 ṣáájú Kristi

    Mahalaleli sì gbé fún ẹgbẹ̀rin ọdún ó lé ọgbọ̀n (830) lẹ́yìn ìgbà tí ó bí Jaredi, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin.

  23. Gẹnẹsisi 5:17nǹkan bí 2714 ṣáájú Kristi

    Àpapọ̀ iye ọdún Mahalaleli jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún ọdún ó dín márùn-ún (895), ó sì kú.

  24. Gẹnẹsisi 5:18nǹkan bí 3382 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí Jaredi pé ọmọ ọgọ́jọ ọdún ó lé méjì ni ó bí Enoku.

  25. Gẹnẹsisi 5:19nǹkan bí 3382 ṣáájú Kristi

    Lẹ́yìn èyí, Jaredi wà láààyè fún ẹgbẹ̀rin (800) ọdún Enoku sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin.