Fò sí àkóónú

Jerusalem

753 verses · 2 known names

A tún mọ̀ ọ́n sí: Jerusalem's

31.7700, 35.2300 Wo lórí Google Maps

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Jerusalem

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Bí wọ́n ti súnmọ́ Jerusalẹmu, tí wọ́n dé itòsí ìlú Betfage ní orí òkè Olifi, Jesu sì rán àwọn ọmọ-ẹ̀yìn méjì,

  2. Bí Jesu sì ti ń wọ Jerusalẹmu, gbogbo ìlú mì tìtì, àwọn ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí í bi ara wọn pé, “Ta nìyìí?”

  3. “Jerusalẹmu, Jerusalẹmu, ìlú tí ó pa àwọn wòlíì, tí ó sì sọ òkúta lu àwọn tí a rán sí i. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni èmi tí ń fẹ́ kó àwọn ọmọ rẹ jọ pọ̀ gẹ́gẹ́ bí àgbébọ̀ adìyẹ ti í dáàbò bo àwọn ọmọ rẹ̀ lábẹ́ ìyẹ́ rẹ, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kọ̀.

  4. Gbogbo àwọn tí ń gbé ní agbègbè Judea, àti gbogbo ènìyàn Jerusalẹmu jáde tọ̀ ọ́ lọ, a sì ti ọwọ́ rẹ̀ tẹ gbogbo wọn bọ omi ni odò Jordani, wọ́n ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

  5. Nígbà tí wọ́n gbọ́ ìròyìn iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe, ọ̀pọ̀ ènìyàn sì tọ̀ ọ́ wá láti Judea, Jerusalẹmu àti Idumea, àti láti apá kejì odò Jordani àti láti ìhà Tire àti Sidoni.

  6. Àwọn olùkọ́ni ní òfin sọ̀kalẹ̀ wá láti Jerusalẹmu, wọ́n sì wí pé, “Ó ni Beelsebulu, olórí àwọn ẹ̀mí èṣù, ni ó sì fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde!”

  7. Àwọn Farisi sì péjọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, àti àwọn kan nínú àwọn akọ̀wé, tí ó wá láti Jerusalẹmu,

  8. Nísinsin yìí, wọ́n wà lójú ọ̀nà sí Jerusalẹmu. Jesu sì ń lọ níwájú wọn, bí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ti ń tẹ̀lé e, ìbẹ̀rù kún ọkàn wọn. Ó sì tún mú àwọn méjìlá sí apá kan, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣàlàyé ohun gbogbo tí a ó ṣe sí i fún wọn.

  9. Ó sọ fún wọn pé, “Àwa ń gòkè lọ Jerusalẹmu, a ó sì fi Ọmọ Ènìyàn lé àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin lọ́wọ́. Wọn ni yóò dá lẹ́bi ikú. Wọn yóò sì fà á lé ọwọ́ àwọn aláìkọlà.

  10. Bí wọ́n ti súnmọ́ Betfage àti Betani ní ẹ̀yìn odi ìlú Jerusalẹmu, wọ́n dé orí òkè olifi. Jesu rán méjì nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ síwájú.

  11. Jesu wọ Jerusalẹmu ó sì lọ sí inú tẹmpili. Ó wo ohun gbogbo yíká fínní fínní. Ó sì kúrò níbẹ̀, nítorí pé ilẹ̀ ti ṣú. Ó padà lọ sí Betani pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá.

  12. Nígbà ti wọ́n padà sí Jerusalẹmu, ó wọ inú tẹmpili. Ó bẹ̀rẹ̀ sí nílé àwọn oníṣòwò àti àwọn oníbàárà wọn síta. Ó ti tábìlì àwọn tí ń pààrọ̀ owó nínú tẹmpili ṣubú. Bákan náà ni ó ti ìjókòó àwọn tí ń ta ẹyẹlé lulẹ̀.

  13. Lẹ́yìn èyí, wọ́n tún padà sí Jerusalẹmu. Bí Jesu ti ń rìn kiri ni tẹmpili, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin pẹ̀lú àwọn àgbàgbà Júù wá sọ́dọ̀ rẹ̀.

  14. Àwọn wọ̀nyí, nígbà tí ó wà ní Galili máa ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, wọ́n a sì máa ṣe ìránṣẹ́ fún un àti ọ̀pọ̀ obìnrin mìíràn tí wọ́n sì bá a gòkè wá sí Jerusalẹmu.

  15. Nígbà tí ọjọ́ ìwẹ̀nù Maria sì pé gẹ́gẹ́ bí òfin Mose, Josẹfu àti Maria gbé Jesu wá sí Jerusalẹmu láti fi í fún Olúwa

  16. Sì kíyèsi i, ọkùnrin kan wà ní Jerusalẹmu, orúkọ rẹ̀ a máa jẹ́ Simeoni; ọkùnrin náà sì ṣe olóòtítọ́ àti olùfọkànsìn, ó ń retí ìtùnú Israẹli, Ẹ̀mí mímọ́ sì bà lé e.

  17. Ó sì wólẹ̀ ní àkókò náà, ó sì dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run pẹ̀lú, ó sì sọ̀rọ̀ rẹ̀ fún gbogbo àwọn tí ó ń retí ìdáǹdè Jerusalẹmu.

  18. Àwọn òbí rẹ̀ a sì máa lọ sí Jerusalẹmu ní ọdọọdún sí àjọ ìrékọjá.

  19. Nígbà tí ọjọ́ wọn sì pé bí wọ́n ti ń padà bọ̀, ọmọ náà, Jesu dúró lẹ́yìn ní Jerusalẹmu; Josẹfu àti ìyá rẹ̀ kò mọ̀.

  20. Nígbà tí wọn kò sì rí i, wọ́n padà sí Jerusalẹmu, wọ́n ń wá a kiri.

  21. Èṣù sì mú un lọ sí Jerusalẹmu, ó sì gbé e lé ibi ṣóńṣó tẹmpili, ó sì wí fún un pé, “Bí ìwọ bá ṣe Ọmọ Ọlọ́run, bẹ́ sílẹ̀ fún ara rẹ láti ibí yìí.

  22. Ní ọjọ́ kan, bí ó sì ti ń kọ́ni, àwọn Farisi àti àwọn amòfin jókòó pẹ̀lú rẹ̀, àwọn tí ó ti àwọn ìletò Galili gbogbo, àti Judea, àti Jerusalẹmu wá: agbára Olúwa sì ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀ láti mú wọn láradá.

  23. Ó sì bá wọn sọ̀kalẹ̀, ó sì dúró ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, pẹ̀lú ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, àti ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn, láti gbogbo Judea, àti Jerusalẹmu, àti agbègbè Tire àti Sidoni, tí wọ́n wá láti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, àti láti gba ìmúláradá kúrò nínú ààrùn wọn;

  24. tí wọ́n fi ara hàn nínú ògo, wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ ikú rẹ̀, tí òun yóò ṣe parí ní Jerusalẹmu.

  25. Nígbà tí ọjọ́ àti gbà á sókè ń súnmọ́, ó pinnu láti lọ sí Jerusalẹmu.