Fò sí àkóónú

Jerusalem

753 verses · 2 known names

A tún mọ̀ ọ́n sí: Jerusalem's

31.7700, 35.2300 Wo lórí Google Maps

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Jerusalem

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Yóò sì ṣe ni ọjọ́ náà, èmi yóò wá láti pa gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè run tí ó wá kọjú ìjà sí Jerusalẹmu.”

  2. “Èmi ó sì tu ẹ̀mí oore-ọ̀fẹ́ àti ẹ̀bẹ̀ sórí ilé Dafidi àti sórí Jerusalẹmu, wọn ó sì máa wo ẹni tí wọn tí gún ni ọ̀kọ̀, wọn ó sì máa ṣọ̀fọ̀ rẹ̀, bí ẹnìkan ti ń ṣọ̀fọ̀ fún ọmọ rẹ̀ kan ṣoṣo àti gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí wọn yóò sì wà ni ìbànújẹ́, bí ẹni tí ń banújẹ́ fún àkọ́bí rẹ̀.

  3. Ní ọjọ́ náà ni ẹkún, ńlá ńlá yóò wà ni Jerusalẹmu, gẹ́gẹ́ bí ọ̀fọ̀ Hadadi Rimoni ni àfonífojì Megido.

  4. “Ní ọjọ́ náà ìsun kan yóò ṣí sílẹ̀ fún ilé Dafidi àti fún àwọn ará Jerusalẹmu, láti wẹ̀ wọ́n mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ àti àìmọ́ wọn.

  5. Nítorí èmi ó kó gbogbo orílẹ̀-èdè jọ sí Jerusalẹmu fún ogun; a ó sì ko ìlú náà, a ó sì kó àwọn ilé, a ó sì ba àwọn obìnrin jẹ́, ààbọ̀ ìlú náà yóò lọ sí ìgbèkùn, a kì yóò sì gé ìyókù àwọn ènìyàn náà kúrò ni ìlú náà.

  6. Ẹsẹ̀ rẹ̀ yóò sì dúró ni ọjọ́ náà lórí òkè Olifi, tí ó wà níwájú Jerusalẹmu ni ìlà-oòrùn, òkè Olifi yóò sì là á sí méjì, sí ìhà ìlà-oòrùn àti ìhà ìwọ̀-oòrùn, àfonífojì ńlá ńlá yóò wà: ìdajì òkè náà yóò sì ṣí síhà àríwá, àti ìdajì rẹ̀ síhà gúúsù.

  7. Yóò sì ṣe ní ọjọ́ náà, omi ìyè yóò tí Jerusalẹmu sàn lọ; ìdajì wọn síhà Òkun ìlà-oòrùn, àti ìdajì wọn síhà okùn ẹ̀yìn: nígbà ẹ̀rùn àti nígbà òtútù ni yóò rí bẹ́ẹ̀.

  8. A ó yí gbogbo ilẹ̀ padà bi pẹ̀tẹ́lẹ̀ kan láti Geba dé Rimoni lápá gúúsù Jerusalẹmu: yóò di bí aginjù, ṣùgbọ́n a ó sì gbé Jerusalẹmu sókè, yóò sì gbe ipò rẹ̀, láti ibodè Benjamini títí dé ibi ibodè èkínní, dé ibodè igun nì, àti láti ilé ìṣọ́ Hananeli dé ibi ìfúntí wáìnì ọba.

  9. Ènìyàn yóò sì máa gbé ibẹ̀, kì yóò sì sí ìparun mọ́; ṣùgbọ́n a ó máa gbé Jerusalẹmu láìléwu.

  10. Èyí ni yóò sì jẹ́ ààrùn tí Olúwa yóò fi kọlu gbogbo àwọn ènìyàn ti ó tí ba Jerusalẹmu jà; ẹran-ara wọn yóò rù nígbà tí wọn dúró ni ẹsẹ̀ wọn, ojú wọn yóò sì rà ni ihò wọn, ahọ́n wọn yóò sì bàjẹ́ ni ẹnu wọn.

  11. Juda pẹ̀lú yóò sì jà ni Jerusalẹmu: ọrọ̀ gbogbo àwọn kèfèrí tí ó wà káàkiri ni a ó sì kójọ, wúrà àti fàdákà, àti aṣọ, ní ọ̀pọ̀lọpọ̀.

  12. Yóò sì ṣe, olúkúlùkù ẹni tí o kù nínú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ó dìde sí Jerusalẹmu yóò máa gòkè lọ lọ́dọọdún láti sìn ọba, Olúwa àwọn ọmọ-ogun, àti láti ṣe àjọyọ̀ àsè àgọ́ náà.

  13. Yóò sì ṣe, ẹnikẹ́ni tí kì yóò gòkè wá nínú gbogbo ìdílé ayé sí Jerusalẹmu láti sín ọba, Olúwa àwọn ọmọ-ogun, òjò kì yóò rọ̀ fún wọn.

  14. Nítòótọ́, gbogbo ìkòkò ni Jerusalẹmu àti ni Juda yóò jẹ́ mímọ́ sí Olúwa àwọn ọmọ-ogun: àti gbogbo àwọn tí ń rú ẹbọ yóò wá, wọn ó sì mú ìkòkò díẹ̀, wọn ó sì bọ ẹran wọn nínú rẹ̀, ni ọjọ́ náà ni àwọn Kenaani kò ní sí mọ́ ni ilé Olúwa àwọn ọmọ-ogun.

  15. Juda ti ń hùwà àrékérekè, a sì ti hùwà ìríra ní Israẹli àti ni Jerusalẹmu: nítorí Juda tí sọ ìwà mímọ́ Olúwa di aláìmọ́, èyí tí ó fẹ́, nípa gbígbé ọmọbìnrin ọlọ́run àjèjì ni ìyàwó.

  16. nígbà náà ni ọrẹ Juda àti ti Jerusalẹmu yóò jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún Olúwa, gẹ́gẹ́ bí ti ọjọ́ àtijọ́, àti gẹ́gẹ́ bí ọdún ìgbàanì.

  17. Lẹ́yìn ìgbà tí a bí Jesu ní Bẹtilẹhẹmu ti Judea, ni àkókò ọba Herodu, àwọn amòye ti ìlà-oòrùn wá sí Jerusalẹmu.

  18. Nígbà tí ọba Herodu sì gbọ́ èyí, ìdààmú bá a àti gbogbo àwọn ara Jerusalẹmu pẹ̀lú rẹ̀.

  19. Àwọn ènìyàn jáde lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ láti Jerusalẹmu àti gbogbo Judea àti àwọn ènìyàn láti gbogbo ìhà Jordani.

  20. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn láti Galili, Dekapoli, Jerusalẹmu, Judea, àti láti òkè odò Jordani sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.

  21. Tàbí fi ayé búra, nítorí àpótí ìtìsẹ̀ Ọlọ́run ni; tàbí Jerusalẹmu, nítorí olórí ìlú ọba ńlá ni.

  22. Nígbà náà ní àwọn Farisi àti àwọn olùkọ́ òfin tọ Jesu wá láti Jerusalẹmu,

  23. Láti ìgbà yìí lọ, Jesu bẹ̀rẹ̀ sí ṣàlàyé fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kedere nípa lílọ sí Jerusalẹmu láti jẹ ọ̀pọ̀ ìyà lọ́wọ́ àwọn àgbàgbà, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé, kí a sì pa òun, àti ní ọjọ́ kẹta, kí ó sì jíǹde.

  24. Bí Jesu ti ń gòkè lọ sí Jerusalẹmu, ó pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá sí apá kan ó sì wí pé,

  25. “Wò ó, àwa ń gòkè lọ sí Jerusalẹmu. Ó sọ fún wọn pé, a ó fi Ọmọ Ènìyàn lé àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin lọ́wọ́, wọn yóò sì dá mi lẹ́bi ikú.