Fò sí àkóónú

Jerusalem

753 verses · 2 known names

A tún mọ̀ ọ́n sí: Jerusalem's

31.7700, 35.2300 Wo lórí Google Maps

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Jerusalem

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ní ọdún kìn-ín-ní ìjọba rẹ̀, èmi Daniẹli fi iyè sí i láti inú ìwé, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa tí wòlíì Jeremiah, wá pé, àádọ́rin ọdún ni Jerusalẹmu yóò fi wà ní ahoro.

  2. “Olúwa ìwọ ni olódodo, ṣùgbọ́n báyìí ìtìjú dé bá àwọn ènìyàn Juda, àwọn ènìyàn Jerusalẹmu àti gbogbo Israẹli ní gbogbo orílẹ̀-èdè tí ìwọ ti fọ́n wa ká sí nítorí àìṣòótọ́ ọ wa sí ọ.

  3. Ìwọ ti mú ọ̀rọ̀ tí o sọ sí wa sẹ àti lórí àwọn alákòóso wa, nípa mímú kí ibi ńlá bá wa, irú èyí tí kò tí ì ṣẹlẹ̀ rí lábẹ́ ọ̀run, bí ó ti ṣẹlẹ̀ sí Jerusalẹmu yìí.

  4. Olúwa, ní ìbámu pẹ̀lú ìwà òdodo rẹ, yí ìbínú àti ìrunú rẹ padà kúrò ní Jerusalẹmu ìlú u rẹ, òkè mímọ́ rẹ. Ẹ̀ṣẹ̀ wa àti àìṣedéédéé àwọn baba wa ti mú Jerusalẹmu àti ènìyàn rẹ di ẹ̀gàn fún gbogbo àwọn tí ó yí wọn ká.

  5. “Nítorí náà, mọ èyí pé, láti ìgbà tí a ti gbé ọ̀rọ̀ náà jáde wí pé kí a tún Jerusalẹmu ṣe, kí a sì tún kọ́, títí dé ìgbà ọmọ-aládé, ẹni òróró náà, alákòóso wa yóò fi dé, ó jẹ́ ọ̀sẹ̀ méje àti ọ̀sẹ̀ méjìlélọ́gọ́ta, a ó sì tún ìgboro àti yàrá rẹ̀ mọ, ṣùgbọ́n ní àkókò wàhálà ni.

  6. Yóò sí ṣe, ẹnikẹ́ni tí ó ba ké pè orúkọ Olúwa ní a ó gbàlà, nítorí ní òkè Sioni àti ní Jerusalẹmu ní ìgbàlà yóò gbé wà, bí Olúwa ti wí, àti nínú àwọn ìyókù tí Olúwa yóò pè.

  7. “Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, àti ní àkókò náà, nígbà tí èmi tún mú ìgbèkùn Juda àti Jerusalẹmu padà bọ̀.

  8. Àti àwọn ọmọ Juda, àti àwọn ọmọ Jerusalẹmu ní ẹ̀yin ti tà fún àwọn ará Giriki, kí ẹ̀yin bá à lè sí wọn jìnnà kúrò ní agbègbè ilẹ̀ ìní wọn.

  9. Olúwa yóò sí ké ramúramù láti Sioni wá, yóò sì fọ ohùn rẹ̀ jáde láti Jerusalẹmu wá; àwọn ọ̀run àti ayé yóò sì mì tìtì. Ṣùgbọ́n Olúwa yóò ṣe ààbò àwọn ènìyàn rẹ̀, àti agbára àwọn ọmọ Israẹli.

  10. “Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò mọ̀ pé, èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín, tí ń gbé Sioni òkè mímọ́ mi. Ìgbà náà ni Jerusalẹmu yóò jẹ́ mímọ́; àwọn àjèjì kì yóò sì kó o mọ́.

  11. Ṣùgbọ́n Juda yóò jẹ́ ibùgbé títí láé, àti Jerusalẹmu láti ìran dé ìran.

  12. Ó wí pé, “Olúwa yóò bú jáde láti Sioni, ohùn rẹ̀ yóò sì sán bí àrá láti Jerusalẹmu wá; ibùgbé àwọn olùṣọ́-àgùntàn yóò sì ṣọ̀fọ̀, orí òkè Karmeli yóò sì rọ.”

  13. Èmi yóò rán iná sí orí Juda èyí tí yóò jó àwọn ààfin Jerusalẹmu run.”

  14. Ní ọjọ́ tí ìwọ dúró ní apá kan, ní ọjọ́ tí àlejò kó ogún rẹ lọ, tí àwọn àjèjì sì wọ ibodè rẹ, tí wọ́n sì sẹ́ kèké lórí Jerusalẹmu, ìwọ náà wà bí ọ̀kan nínú wọn.

  15. Àwọn ìgbèkùn Israẹli tí ó wà ní Kenaani yóò ni ilẹ̀ títí dé Sarefati; àwọn ìgbèkùn láti Jerusalẹmu tí ó wà ní Sefaredi yóò ni àwọn ìlú gúúsù ní ìní.

  16. Ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó tọ Mika ará Moreṣeti wá ní àkókò ìjọba Jotamu, Ahasi, àti Hesekiah, àwọn ọba Juda nìwọ̀nyí, ìran tí ó rí nípa Samaria àti Jerusalẹmu.

  17. Nítorí ìré-òfin-kọjá Jakọbu ni gbogbo èyí, àti nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ilé Israẹli. Kí ni ìré-òfin-kọjá Jakọbu? Ǹjẹ́ Samaria ha kọ? Kí ni àwọn ibi gíga Juda? Ǹjẹ́ Jerusalẹmu ha kọ?

  18. Nítorí tí ọgbẹ́ rẹ̀ jẹ́ aláìlèwòtán; ó sì ti wá sí Juda. Ó sì ti dé ẹnu-bodè àwọn ènìyàn mi, àní sí Jerusalẹmu.

  19. Nítorí àwọn tí ó ń gbé ni Marati ń retí ìre, ṣùgbọ́n ibi sọ̀kalẹ̀ ti ọ̀dọ̀ Olúwa wá sí ẹnu-bodè Jerusalẹmu.

  20. tí ó kọ́ Sioni pẹ̀lú ìtàjẹ̀ sílẹ̀, àti Jerusalẹmu pẹ̀lú ìwà búburú.

  21. Nítorí náà, nítorí tiyín, ni a ó ṣe ro Sioni bí oko, Jerusalẹmu yóò sì di ebè àti òkè tẹmpili bí i ibi gíga igbó.

  22. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè yóò wá, wọn yóò sì wí pé, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á gòkè ńlá Olúwa, àti sí ilé Ọlọ́run Jakọbu. Òun yóò sì kọ́ wa ní ọ̀nà rẹ̀, kí àwa kí ó lè rìn ní ọ̀nà rẹ̀.” Òfin yóò jáde láti Sioni wá, àti ọ̀rọ̀ Olúwa láti Jerusalẹmu.

  23. Ní ti ìwọ, ilé ìṣọ́ agbo àgùntàn, odi alágbára ọmọbìnrin Sioni, a ó mú ìjọba ìṣáájú padà bọ̀ sípò fún un yín; ìjọba yóò sì wà sí ọ̀dọ̀ ọmọbìnrin Jerusalẹmu.”

  24. “Èmi yóò na ọwọ́ mi sórí Juda àti sórí gbogbo àwọn ènìyàn tí ń gbé ní Jerusalẹmu. Èmi yóò sì ké kúrò níhìn-ín yìí ìyókù àwọn Baali, àti orúkọ àwọn abọ̀rìṣà pẹ̀lú àwọn àlùfáà abọ̀rìṣà,

  25. Ní àkókò wọ̀n-ọn-nì, èmi yóò wá Jerusalẹmu kiri pẹ̀lú fìtílà, èmi ó sì fi ìyà jẹ àwọn tí kò ní ìtẹ́lọ́rùn, tí wọn sì dàbí àwọn ènìyàn tí ó sinmi sínú gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ wọn, àwọn tí wọn sì ń wí ní ọkàn wọn pé, ‘Olúwa kì yóò ṣe nǹkan kan tí ó jẹ́ rere tàbí tí ó jẹ́ búburú.’