Fò sí àkóónú

Jesus

3,872 ẹsẹ · 6 ọmọ ẹbí

A tún mọ̀ ọ́n sí: Jesus Christ, Immanuel, Emmanuel, Christ

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Jesus

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Nítòótọ́, kò sí ìyìnrere mìíràn bí ó tilẹ̀ ṣe pé àwọn kan wà, tí ń yọ yín lẹ́nu, tí wọ́n sì ń fẹ́ yí ìyìnrere Kristi padà.

  2. Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ènìyàn ni èmi ń wá ojúrere rẹ̀ ní tàbí Ọlọ́run? Tàbí ènìyàn ni èmi ń fẹ́ láti wù bí? Bí èmi bá ń fẹ́ láti wu ènìyàn, èmi kò lè jẹ́ ìránṣẹ́ Kristi.

  3. N kò gbà á lọ́wọ́ ènìyàn kankan, bẹ́ẹ̀ ni a kò fi kọ́ mi, ṣùgbọ́n mo gbà á nípa ìfihàn láti ọ̀dọ̀ Jesu Kristi.

  4. Láti fi ọmọ rẹ̀ hàn nínú mi, kì èmi lè máa wàásù ìyìnrere rẹ̀ láàrín àwọn aláìkọlà; èmi kò wá ìmọ̀ lọ sọ́dọ̀ ẹnikẹ́ni,

  5. Mo sì jẹ́ ẹni tí a kò mọ̀ lójú fún àwọn ìjọ tí ó wà nínú Kristi ni Judea.

  6. Ọ̀rọ̀ yìí wáyé nítorí àwọn èké arákùnrin tí wọn yọ́ wọ inú àárín wa láti yọ́ òmìnira wa wò, èyí tí àwa ni nínú Kristi Jesu, kí wọn lè mú wa wá sínú ìdè.

  7. tí a mọ̀ pé a kò dá ẹnikẹ́ni láre nípa iṣẹ́ òfin, bí kò ṣe nípa ìgbàgbọ́ nínú Jesu Kristi, àní àwa pẹ̀lú gbà Jesu Kristi gbọ́, kí a bá a lè dá wa láre nípa ìgbàgbọ́ tí Kristi, kì í sì i ṣe nípa iṣẹ́ òfin, nítorí pé nípa iṣẹ́ òfin kò sí ènìyàn kan tí a ó dá láre.

  8. “Ṣùgbọ́n nígbà tí àwa bá ń wá ọ̀nà láti rí ìdáláre nípa Kristi, ó di ẹ̀rí wí pé àwa pẹ̀lú jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, ǹjẹ́ èyí ha jásí wí pé Kristi ń ṣe ìránṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ bí? Kí a má rí ì!

  9. A ti kàn mí mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú Kristi, èmí kò sì wà láààyè mọ́, ṣùgbọ́n Kristi ń gbé inú mi wíwà tí mo sì wà láààyè nínú ara, mo wà láààyè nínú ìgbàgbọ́ Ọmọ Ọlọ́run, ẹni tí o fẹ́ mi, tí ó sì fi òun tìkára rẹ̀ fún mi.

  10. Èmi kò ya oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run sí apá kan, nítorí pé bí a bá le ti ipasẹ̀ òfin jèrè òdodo, a jẹ́ pé Kristi kú lásán.”

  11. Ẹ̀yin aláìnírònú ará Galatia! Ta ní ha tàn yín jẹ, kí ẹ̀yin má ṣe gba òtítọ́ gbọ́? Ní ojú ẹni tí a fi Jesu Kristi hàn gbangba láàrín yín ni ẹni tí a kàn mọ́ àgbélébùú.

  12. Ṣé Ọlọ́run fún yín ní Ẹ̀mí rẹ̀, tí ó sì ṣe iṣẹ́ ìyanu láàrín yín nítorí tí ẹ̀yin pa òfin mọ, tàbí nítorí ẹ ní ìgbàgbọ́ sí ohun tí ẹ gbọ́?

  13. Kristi ti rà wá padà kúrò lọ́wọ́ ègún òfin, ẹni tí a fi ṣe ègún fún wa: nítorí tí a ti kọ ọ́ pé, “Ìfibú ni olúkúlùkù ẹni tí a fi kọ́ sórí igi.”

  14. Ó gbà wá là ki ìbùkún Abrahamu ba à lè wá sórí àwọn aláìkọlà nípa Kristi Jesu; kí àwa ba à lè gba ìlérí Ẹ̀mí nípa ìgbàgbọ́.

  15. Ǹjẹ́ fún Abrahamu àti fún irú-ọmọ rẹ̀ ni a ti ṣe àwọn ìlérí náà. Ìwé Mímọ́ kò ṣọ wí pé, “fún àwọn irú-ọmọ rẹ̀,” bí ẹni pé ọ̀pọ̀lọpọ̀; ṣùgbọ́n bí ẹni pé ọ̀kan ṣoṣo, “àti fún irú-ọmọ rẹ̀,” èyí tí í ṣe Kristi.

  16. Èyí tí mò ń wí ni pé: májẹ̀mú tí Ọlọ́run ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ níṣàájú, òfin ti ó dé lẹ́yìn ọgbọ̀nlénírinwó (430) ọdún kò lè sọ ọ́ di asán, kí ó sì mú ìlérí náà di aláìlágbára.

  17. Ṣùgbọ́n ìwé mímọ́ ti fi yé wa pé gbogbo ènìyàn ni ń bẹ lábẹ́ ìdè ẹ̀ṣẹ̀, kí a lè fi ìlérí nípa ìgbàgbọ́ nínú Jesu Kristi fún àwọn tí ó gbàgbọ́.

  18. Nítorí náà òfin ti jẹ́ olùtọ́jú láti mú ènìyàn wá sọ́dọ̀ Kristi, kí a lè dá wa láre nípa ìgbàgbọ́.

  19. Nítorí pé ọmọ Ọlọ́run ni gbogbo yín, nípa ìgbàgbọ́ nínú Kristi Jesu.

  20. Nítorí pé iye ẹ̀yin tí a ti bamitiisi sínú Kristi ti gbé Kristi wọ̀.

  21. Kò le sí Júù tàbí Giriki, ẹrú tàbí òmìnira, ọkùnrin tàbí obìnrin nítorí pé ọ̀kan ni nínú Kristi Jesu.

  22. Ṣùgbọ́n nígbà tí àkókò kíkún náà dé, Ọlọ́run rán ọmọ rẹ̀ jáde wá, ẹni tí a bí nínú obìnrin tí a bí lábẹ́ òfin.

  23. Àti nítorí tí ẹ̀yin jẹ́ ọmọ, Ọlọ́run sì ti rán Ẹ̀mí Ọmọ rẹ̀ wá sínú ọkàn yín, tí ń ké pé, “Ábbà, Baba.”

  24. Nítorí náà ìwọ kì í ṣe ẹrú, bí kò ṣe ọmọ; àti bí ìwọ bá ń ṣe ọmọ, ǹjẹ́ ìwọ di àrólé Ọlọ́run nípasẹ̀ Kristi.

  25. Èyí tí ó sì jẹ́ ìdánwò fún yín ní ara mi ni ẹ kò kẹ́gàn, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò sì kọ̀; ṣùgbọ́n ẹ̀yin gbà mí bí angẹli Ọlọ́run, àní bí Kristi Jesu.