Jesus
A tún mọ̀ ọ́n sí: Jesus Christ, Immanuel, Emmanuel, Christ
Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Jesus
Ẹ̀yin ọmọ mi kéékèèké, ẹ̀yin tí mo tún ń rọbí títí a ó fi ṣe ẹ̀dá Kristi nínú yín.
Nítorí náà, ẹ dúró ṣinṣin nínú òmìnira náà èyí tí Kristi fi sọ wá di òmìnira, kí ẹ má sì ṣe tún fi ọrùn bọ̀ àjàgà ẹrú mọ́.
Kíyèsi i, èmi Paulu ni ó wí fún yín pé, bí a bá kọ yín nílà abẹ́, Kristi kì yóò lérè fún yín ní ohunkóhun.
A ti yà yín kúrò lọ́dọ̀ Kristi, ẹ̀yin tí ń fẹ́ kí a dá yín láre nípa òfin; pé ẹ ti ṣubú kúrò nínú oore-ọ̀fẹ́.
Nítorí nínú Kristi Jesu, ìkọlà kò jẹ́ ohun kan, tàbí àìkọlà; ṣùgbọ́n ìgbàgbọ́ ti ń ṣiṣẹ́ nípa ìfẹ́.
Ìyípadà yìí kò ti ọ̀dọ̀ ẹni tí ó pè yín wá.
Mo ní ìgbẹ́kẹ̀lé sí yín nínú Olúwa pé, ẹ̀yin kì yóò ní èrò ohun mìíràn; ṣùgbọ́n ẹni tí ń yọ yín lẹ́nu yóò ru ìdájọ́ tirẹ̀, ẹnikẹ́ni tí ó wù kí ó jẹ́.
Ẹ máa ru ẹrù ọmọnìkejì yín, kí ẹ sì fi bẹ́ẹ̀ mú òfin Kristi ṣẹ.
Iye àwọn tí ń fẹ́ ṣe àṣehàn ni ara wọn ń rọ yín láti kọlà; kìkì nítorí pé kí a má ba à ṣe inúnibíni sí wọn nítorí àgbélébùú Kristi.
Ṣùgbọ́n kí a má ṣe rí i pé èmi ń ṣògo, bí kò ṣe nínú àgbélébùú Jesu Kristi Olúwa wa, nípasẹ̀ ẹni tí a ti kan ayé mọ́ àgbélébùú fún mi, àti èmi fún ayé.
Nítorí pé nínú Kristi Jesu, ìkọlà kò jẹ́ ohun kan, tàbí àìkọlà, bí kò ṣe ẹ̀dá tuntun.
Láti ìsinsin yìí lọ, kí ẹnikẹ́ni má ṣe yọ mí lẹ́nu mọ́; nítorí èmi ń ru àpá Jesu Olúwa kiri ní ara mi.
Ará, oore-ọ̀fẹ́ Jesu Kristi Olúwa wa, kí ó wà pẹ̀lú ẹ̀mí yín. Àmín.
Paulu, aposteli Jesu Kristi nípa ìfẹ́ Ọlọ́run, Sí àwọn ènìyàn mímọ́ tí ó wà ní Efesu, àti sí àwọn olóòtítọ́ nínú Kristi Jesu:
Oore-ọ̀fẹ́ sí yín àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wá àti Jesu Kristi Olúwa.
Ògo ni fún Ọlọ́run àti Baba Jesu Kristi Olúwa wa, ẹni tí ó ti bùkún wa láti inú ọ̀run wá pẹ̀lú àwọn ìbùkún ẹ̀mí gbogbo nínú Kristi.
Àní, gẹ́gẹ́ bí o ti yàn wá nínú rẹ̀ ṣáájú ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé, láti jẹ́ mímọ́ àti aláìlábùkù níwájú rẹ̀ nínú ìfẹ́
ẹni tí ò ti yàn wá tẹ́lẹ̀ sí ìsọdọmọ nípa Jesu Kristi fún ara rẹ̀, ní ìbámu ìdùnnú ìfẹ́ rẹ̀,
fún ìyìn ògo oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀, èyí tí ò ti fi fún wa nínú Àyànfẹ́ rẹ̀.
Nínú rẹ̀ ni àwa rí ìràpadà gba nípa ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ àti ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, ní ìbámu pẹ̀lú ọrọ̀ oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run
èyí tí ó fún wa lọ́pọ̀lọ́pọ̀ pẹ̀lú gbogbo ọgbọ́n àti ìmòye,
Ó ti sọ ohun ìjìnlẹ̀ ìfẹ́ rẹ̀ di mí mọ̀ fún wa gẹ́gẹ́ bí ìdùnnú rere rẹ̀, èyí ti o pinnu nínú Kristi,
èyí tí yóò jẹ jáde ní kíkún àkókò, láti ṣe àkójọpọ̀ àwọn ohun tí ọ̀run àti ti ayé lábẹ́ Kristi.
Nínú rẹ̀ ni a yàn wá fẹ́ lẹ́yìn tí ó ti yàn wá tẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu ẹni tí ń ṣiṣẹ́ ohun gbogbo ní ìbámu ìfẹ́ rẹ̀,
kí àwa kí ó le wà fún ìyìn ògo rẹ̀, àwa tí a ti ni ìrètí ṣáájú nínú Kristi.