Jesus
A tún mọ̀ ọ́n sí: Jesus Christ, Immanuel, Emmanuel, Christ
Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Jesus
Nítorí àwa kò nawọ́ wa rékọjá rárá, bí ẹni pé àwa kò dé ọ̀dọ̀ yín: nítorí àwa tilẹ̀ dé ọ̀dọ̀ yín pẹ̀lú nínú ìyìnrere Kristi.
“Ṣùgbọ́n jẹ́ kí ẹni tí ó bá ń ṣògo, kí ó máa ṣògo nínú Olúwa.”
Nítorí kì í ṣe ẹni tí ń yin ara rẹ̀ ni ó ní ìtẹ́wọ́gbà, bí kò ṣe ẹni tí Olúwa bá yìn.
Nítorí pé èmi ń jowú lórí i yín bí ẹni ìwà-bí-Ọlọ́run, nítorí tí mo ti fì yín fún ọkọ kan, kí èmi bà á lè mú yín wá bí wúńdíá tí ó mọ́ sọ́dọ̀ Kristi.
Ṣùgbọ́n ẹ̀rù ń bà mí, kí ó má bà á jẹ́ pé, bí ejò ti tan Efa jẹ́ nípasẹ̀ àrékérekè rẹ̀, a lè mú ọkàn yín ṣáko lọ kúrò nínú òtítọ́ yín àti ìfarajì fún Kristi.
Nítorí bí ẹnìkan bá wá tí ó sì wàásù Jesu mìíràn, yàtọ̀ sí èyí tí a ti wàásù rí tàbí bí ẹ̀yin bá gba ẹ̀mí mìíràn, yàtọ̀ sí èyí tí ẹ ti gbà tàbí ìyìnrere mìíràn yàtọ̀ sí èyí tí ẹ ti gbà, tí ẹ sì ti yára tẹ́wọ́ gbà á.
Ó jẹ́ òtítọ́, Kristi tí ń bẹ nínú mi pé kò sí ẹni tí ó lè dá mi lẹ́kun ìṣògo yìí ni gbogbo ẹkùn Akaia.
Nítorí irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ ni àwọn èké Aposteli àwọn ẹni ti ń ṣiṣẹ́ ẹ̀tàn, tí ń pa wọ́n dà di aposteli Kristi.
Ohun tí èmi ń sọ, èmi kò sọ ọ́ nípa ti Olúwa, ṣùgbọ́n bí òmùgọ̀ nínú ìgbẹ́kẹ̀lé ìṣògo yìí.
Ìránṣẹ́ Kristi ni wọ́n bí? Èmi ń sọ bí òmùgọ̀, mo ta wọ́n yọ; ní ti làálàá lọ́pọ̀lọ́pọ̀, ní ti pàṣán, mo rékọjá, ní ti túbú nígbàkígbà, ní ti fífẹ́rẹ kú nígbà púpọ̀.
Ọlọ́run àti Baba Olúwa wá Jesu Kristi, ẹni tí ó jẹ́ olùbùkún jùlọ láéláé mọ̀ pé èmi kò ṣèké.
Èmi kò lè ṣàì ṣògo bí kò tilẹ̀ ṣe àǹfààní, nítorí èmi ó wà sọ nípa ìran àti ìṣípáyà ti Olúwa fihàn mí.
Èmi mọ ọkùnrin kan nínú Kristi ní ọdún mẹ́rìnlá sẹ́yìn, yálà nínú ara ni, èmi kò mọ̀; tàbí kúrò nínú ara, èmi kò mọ̀; Ọlọ́run mọ̀: a gbé irú ẹni náà lọ sí ọ̀run kẹta.
Nítorí nǹkan yìí ni mo ṣe bẹ Olúwa nígbà mẹ́ta pé, kí ó lé e kúrò lára mi.
Òun sì wí fún mi pé, “Oore-ọ̀fẹ́ mi tó fún ọ, nítorí pé a sọ agbára mi di pípé nínú àìlera.” Nítorí náà tayọ̀tayọ̀ ni èmi ó kúkú máa fi ṣògo nínú àìlera mi, kí agbára Kristi lè máa gbé inú mi.
Ẹ̀yin ha rò pé àwa ń sọ nǹkan wọ̀nyí láti gbèjà ara wa níwájú yín bí? Ní iwájú Ọlọ́run ni àwa ń sọ̀rọ̀ nínú Kristi; ṣùgbọ́n àwa ń ṣe ohun gbogbo, olùfẹ́ ọ̀wọ́n, láti gbé yín ró ni.
Níwọ́n bí ẹ̀yin tí ń wá àmì Kristi ti ń sọ̀rọ̀ nínú mi, ẹni tí kì í ṣe àìlera sí yin, ṣùgbọ́n tí ó jẹ́ agbára nínú yín.
Nítorí pé a kàn án mọ́ àgbélébùú nípa àìlera, ṣùgbọ́n òun wà láààyè nípa agbára Ọlọ́run. Nítorí àwa pẹ̀lú jásí aláìlera nínú rẹ̀, ṣùgbọ́n àwa yóò wà láààyè pẹ̀lú rẹ̀ nípa agbára Ọlọ́run sí yín.
Ẹ máa wádìí ara yín, bí ẹ̀yin bá wà nínú ìgbàgbọ́; ẹ máa dán ara yín wò. Tàbí ẹ̀yin fúnra yín kò mọ ara yín pé Jesu Kristi wá nínú yín? Àfi bí ẹ̀yin bá jẹ́ àwọn tí a tanù.
Ìdí nìyí ti mo ṣe kọ̀wé àwọn nǹkan wọ̀nyí nígbà tí èmi kò sí lọ́dọ̀ yín, pé nígbà tí mo bá dé kí èmi má ba à lo ìkanra ní lílo àṣẹ, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Olúwa ti fi fún mí, láti mú ìdàgbàsókè, kì í ṣe láti fà yín ṣubú.
Oore-ọ̀fẹ́ Jesu Kristi Olúwa, àti ìfẹ́ Ọlọ́run, àti ìdàpọ̀ ti Èmí Mímọ́, kí ó wà pẹ̀lú gbogbo yín.
Paulu, aposteli tí a rán kì í ṣe láti ọ̀dọ̀ ènìyàn wá, tàbí nípa ènìyàn, ṣùgbọ́n nípa Jesu Kristi àti Ọlọ́run Baba, ẹni tí ó jí i dìde kúrò nínú òkú.
Oore-ọ̀fẹ́ sí yín àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wá àti Jesu Kristi Olúwa,
ẹni tí ó fi òun tìkára rẹ̀ dípò ẹ̀ṣẹ̀ wa, kí ó lè gbà wá kúrò nínú ayé búburú ìsinsin yìí, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Ọlọ́run àti Baba wa,
Ó yà mi lẹ́nu pé ẹ tètè yapa kúrò lọ́dọ̀ ẹni tí ó pè yín sínú oore-ọ̀fẹ́ Kristi, sí ìyìnrere mìíràn.