Fò sí àkóónú

Jeremiah

124 ẹsẹ · 1 ọmọ ẹbí

A tún mọ̀ ọ́n sí: Jeremy, Jeremias

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Jeremiah

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Nígbà náà ni Jeremiah sọ fún gbogbo àwọn aláṣẹ àti gbogbo àwọn ènìyàn wí pé: “Olúwa rán mi láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní ilé yìí àti ìlú yìí, gbogbo ohun tí ẹ ti gbọ́.

  2. (Bákan náà Uriah ọmọ Ṣemaiah láti Kiriati-Jearimu jẹ́ ọkùnrin mìíràn tí ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ kan náà ní orúkọ Olúwa. Ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ kan náà sí ìlú náà àti ilẹ̀ yín bí Jeremiah ti ṣe.

  3. Ahikamu ọmọ Ṣafani ń bẹ pẹ̀lú Jeremiah, wọn kò sì fi í lé àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti pa á.

  4. Ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ìṣèjọba Sedekiah ọmọ Josiah ọba Juda, ọ̀rọ̀ yìí tọ Jeremiah wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa wí pé.

  5. Wòlíì Jeremiah wí fún wòlíì Hananiah ní iwájú ọmọ àlùfáà àti àwọn ènìyàn tí wọ́n dúró ní ilé Olúwa.

  6. Jeremiah wòlíì wí pé, “Àmín! Kí Olúwa kí ó ṣe bẹ́ẹ̀! Kí Olúwa kí ó mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí ìwọ sọ àsọtẹ́lẹ̀ ṣẹ, láti mú ohun èlò ilé Olúwa àti gbogbo àwọn ìgbèkùn láti ilẹ̀ Babeli padà wá sí ibí yìí.

  7. Wòlíì Hananiah gbé àjàgà ọrùn wòlíì Jeremiah kúrò, ó sì fọ́ ọ.

  8. Hananiah sọ níwájú gbogbo ènìyàn wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa wí: ‘Bákan náà ni Èmi yóò fọ́ àjàgà ọrùn Nebukadnessari, ọba Babeli láàrín ọdún méjì.’ ” Wòlíì Jeremiah sì bá ọ̀nà tirẹ̀ lọ.

  9. Láìpẹ́ ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremiah wòlíì wá lẹ́yìn ìgbà tí wòlíì Hananiah ti gbé àjàgà kúrò ní ọrùn wòlíì Jeremiah wí pé:

  10. Wòlíì Jeremiah sọ fún wòlíì Hananiah pé, “Gbọ́ ọ, Hananiah! Olúwa kò rán ọ, síbẹ̀, ìwọ jẹ́ kí orílẹ̀-èdè yìí gba irọ́ gbọ́.

  11. Èyí ni ọ̀rọ̀ inú lẹ́tà tí wòlíì Jeremiah rán láti Jerusalẹmu sí ìyókù nínú àwọn àgbàgbà tí ó wà ní ìgbèkùn àti sí àwọn àlùfáà, àwọn wòlíì àti gbogbo àwọn ènìyàn tí Nebukadnessari tí kó ní ìgbèkùn láti Jerusalẹmu lọ sí Babeli.

  12. Nítorí náà, èéṣe tí o kò fi bá Jeremiah ará Anatoti wí. Ẹni tí ó ń dúró bí i wòlíì láàrín yín?

  13. Sefaniah àlùfáà ka lẹ́tà náà sí etí ìgbọ́ Jeremiah tí í ṣe wòlíì.

  14. Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremiah wá wí pé,

  15. Ọ̀rọ̀ tí ó tọ Jeremiah wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá, wí pé:

  16. Èyí ni ọ̀rọ̀ tó tọ Jeremiah wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa ní ọdún kẹwàá Sedekiah ọba Juda, èyí tí ó jẹ́ ọdún kejìdínlógún ti Nebukadnessari.

  17. Àwọn ogun ọba Babeli ìgbà náà há Jerusalẹmu mọ́. A sì sé wòlíì Jeremiah mọ́ inú túbú tí wọ́n ń ṣọ́ ní àgbàlá ilé ọba Juda.

  18. Jeremiah wí pé, “Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé:

  19. Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremiah wá pé:

  20. Nígbà tí Jeremiah wà nínú àgbàlá túbú, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ ọ́ wá lẹ́ẹ̀kejì:

  21. Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Jeremiah wá wí pé:

  22. Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremiah wá wí pé:

  23. Nígbà tí Nebukadnessari ọba Babeli àti àwọn ọmọ-ogun rẹ̀, pẹ̀lú gbogbo ìjọba àti àwọn ènìyàn ní ilẹ̀ ọba tí ó jẹ ọba lé lórí ń bá Jerusalẹmu jà, àti gbogbo àwọn ìlú tí ó yíká, ọ̀rọ̀ yìí tọ Jeremiah wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa pé:

  24. Nígbà náà ni Jeremiah wòlíì sọ gbogbo nǹkan yìí fún Sedekiah ọba Juda ní Jerusalẹmu.

  25. Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Jeremiah wá lẹ́yìn ìgbà tí ọba Sedekiah ti dá májẹ̀mú pẹ̀lú gbogbo àwọn ènìyàn ní Jerusalẹmu láti polongo ìtúsílẹ̀ fún àwọn ẹrú.