Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Ebed-Melech

10 ẹsẹ · 2 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

  1. Ṣùgbọ́n, Ebedimeleki, ará Kuṣi ìjòyè nínú ààfin ọba gbọ́ pé wọ́n ti ju Jeremiah sínú kànga. Nígbà tí ọba jókòó ní ẹnu-bodè Benjamini.

  2. Ebedimeleki jáde kúrò láàfin ọba, ó sì sọ fún un pé,

  3. “Olúwa mi ọba, àwọn ènìyàn wọ̀nyí ti ṣe ohun búburú sí Jeremiah wòlíì Ọlọ́run. Wọ́n ti gbé e sọ sínú kànga níbi tí kò sí oúnjẹ kankan nínú ìlú mọ́.”

  4. Nígbà náà ni ọba pàṣẹ fún Ebedimeleki ará Kuṣi pé, “Mú ọgbọ̀n ọkùnrin láti ibí pẹ̀lú rẹ, kí ẹ sì fa wòlíì Jeremiah sókè láti inú ihò, kí ó tó kú.”

  5. Ebedimeleki kó àwọn ọkùnrin náà pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n lọ sínú yàrá kan nínú ààfin ọba. Ó mú àwọn aṣọ àkísà àti okùn tọ Jeremiah lọ nínú kànga.

  6. Ebedimeleki ará Kuṣi sọ fún Jeremiah pé, “Fi àkísà àti okùn bọ abẹ́ abíyá rẹ, Jeremiah sì ṣe bẹ́ẹ̀.”

  7. Báyìí ni wọ́n ṣe fi okùn yọ Jeremiah jáde, wọ́n sì mu un gòkè láti inú ihò wá, Jeremiah sì wà ní àgbàlá ilé túbú.

  8. “Lọ sọ fún Ebedimeleki ará Kuṣi, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli wí: Èmi ṣetán láti mú ọ̀rọ̀ mi ṣẹ lórí ìlú yìí nípa àjálù kì í ṣe àlàáfíà. Ní àkókò náà ni yóò ṣẹ lójú rẹ.

  9. Ṣùgbọ́n, Èmi yóò gbà ọ́ lọ́jọ́ náà ni Olúwa wí. A kò ní fi ọ́ lé ọwọ́ àwọn tí o bẹ̀rù.

  10. Èmi yóò gbà ọ́ là; o kò ní ṣubú láti ipa idà; ṣùgbọ́n ìwọ yóò sá àsálà fún ẹ̀mí rẹ, nítorí pé ìwọ ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú mi, ni Olúwa wí.’ ”