Fò sí àkóónú

Jeremiah

124 ẹsẹ · 1 ọmọ ẹbí

A tún mọ̀ ọ́n sí: Jeremy, Jeremias

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Jeremiah

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremiah wá wí pé:

  2. Ọ̀rọ̀ tí ó tọ Jeremiah wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa ní ọjọ́ Jehoiakimu ọmọ Josiah ọba Juda wí pé:

  3. Nígbà yìí ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremiah wá wí pé:

  4. Nígbà náà ni Jeremiah wí fún ìdílé Rekabu pé, “Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli wí pé: ‘Nítorí tí ẹ̀yin gba òfin Jehonadabu baba yín, tí ẹ sì pa gbogbo rẹ̀ mọ́, tí ẹ sì ṣe gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó pàṣẹ fún un yín.’

  5. Ní ọdún kẹrin Jehoiakimu ọmọ Josiah ọba Juda, ọ̀rọ̀ yìí tọ Jeremiah wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa wí pé:

  6. Nígbà náà ni Jeremiah pe Baruku ọmọ Neriah, ó sì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run bá a sọ fún, Baruku sì kọ láti ẹnu Jeremiah, gbogbo ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó ti sọ fún un sórí ìwé kíká náà.

  7. Nígbà náà ni Jeremiah wí fún Baruku pé, “A sé mi mọ́! Èmi kò lè lọ sí ilé Olúwa.

  8. Baruku ọmọ Neriah sì ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí wòlíì Jeremiah sọ fún, láti ka ọ̀rọ̀ Olúwa láti inú ìwé ní ilé Olúwa.

  9. Láti inú yàrá Gemariah ọmọ Ṣafani akọ̀wé, ní àgbàlá òkè níbi ìlẹ̀kùn ẹnu-ọ̀nà ilé Olúwa tuntun. Baruku sì ka ọ̀rọ̀ Jeremiah láti inú ìwé ní ilé Olúwa sí etí gbogbo ènìyàn.

  10. Nígbà náà ni àwọn ìjòyè sọ fún Baruku wí pé, “Lọ fi ara rẹ pamọ́ àti Jeremiah, má sì ṣe jẹ́ kí ẹnìkan mọ ibi tí ẹ̀yin wà.”

  11. Dípò èyí ọba pàṣẹ fún Jerahmeeli ọmọ Hameleki, Seraiah ọmọ Asrieli àti Ṣelemiah ọmọ Abdeeli láti mú Baruku akọ̀wé àti Jeremiah wòlíì ṣùgbọ́n Olúwa fi wọ́n pamọ́.

  12. Lẹ́yìn tí ọba fi ìwé kíká náà tí ọ̀rọ̀ tí Baruku kọ láti ẹnu Jeremiah jóná tán, ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Jeremiah wá:

  13. Nígbà náà ni Jeremiah mú ìwé kíká mìíràn fún Baruku akọ̀wé ọmọ Neriah, ẹni tí ó kọ̀wé sínú rẹ̀ láti ẹnu Jeremiah gbogbo ọ̀rọ̀ inú ìwé tí Jehoiakimu ọba Juda ti sun níná. A sì fi onírúurú ọ̀rọ̀ bí irú èyí kún pẹ̀lú.

  14. Ṣùgbọ́n àti òun àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àti àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà kò fetísí ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó sọ nípa wòlíì Jeremiah.

  15. Sedekiah ọba sì rán Jehukali ọmọ Ṣelemiah àti Sefaniah ọmọ Maaseiah sí Jeremiah wòlíì wí pé, “Jọ̀wọ́ gbàdúrà sí Olúwa Ọlọ́run wa fún wa.”

  16. Nígbà yìí Jeremiah sì ń wọlé, ó sì ń jáde láàrín àwọn ènìyàn nítorí wọ́n ti fi sínú túbú.

  17. Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremiah wòlíì Ọlọ́run wá:

  18. Jeremiah múra láti fi ìlú náà sílẹ̀, láti lọ sí olú ìlú Benjamini láti gba ẹ̀tọ́ rẹ̀ nínú ohun ìní láàrín àwọn ènìyàn tó wà níbẹ̀.

  19. Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n dé ẹnu ibodè Benjamini, olórí àwọn olùṣọ́ tí orúkọ rẹ ń jẹ́ Irijah ọmọ Ṣelemiah ọmọ Hananiah mú un, ó wí pé, “Ìwọ ń fi ara mọ́ àwọn ará Babeli.”

  20. Jeremiah sọ wí pé, “Èyí kì í ṣe òtítọ́! Èmi kò yapa sí àwọn ará Babeli.” Ṣùgbọ́n Irijah ko gbọ́ tirẹ̀, dípò èyí a mú Jeremiah, ó sì mú un lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ìjòyè.

  21. Nítorí náà ni àwọn ìjòyè ṣe bínú sí Jeremiah, wọ́n jẹ ẹ́ ní yà, wọ́n tún fi sí túbú nílé Jonatani akọ̀wé nítorí wọ́n ti fi èyí ṣe ilé túbú.

  22. Wọ́n fi Jeremiah sínú túbú tí ó ṣókùnkùn biribiri; níbi tí ó wà fún ìgbà pípẹ́.

  23. Nígbà náà ni ọba Sedekiah ránṣẹ́ sí i, tí ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n mú wá sí ààfin níbi tí ó ti bi í ní ìkọ̀kọ̀ pé, “Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ kan wà láti ọ̀dọ̀ Olúwa?” Jeremiah fèsì pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, wọn ó fi ọ́ lé ọwọ́ ọba Babeli.”

  24. Nígbà náà, Jeremiah sọ fún ọba Sedekiah pé, “Irú ẹ̀ṣẹ̀ wo ni mo ṣẹ̀ yín, àwọn ìjòyè yín pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí ẹ fi sọ mí sínú túbú?

  25. Ọba Sedekiah wá pàṣẹ pé kí wọ́n fi Jeremiah sínú àgbàlá àwọn ẹ̀ṣọ́, àti kí wọn sì fún ní àkàrà ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan títí tí àkàrà tó wà ní ìlú yóò fi tán; bẹ́ẹ̀ ni Jeremiah wà nínú àgbàlá náà.