Fò sí àkóónú

Israel

1,007 ẹsẹ · 20 ọmọ ẹbí

A tún mọ̀ ọ́n sí: Jacob

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Israel

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Nígbà tí Jakọbu jí lójú oorun rẹ̀, ó rò nínú ara rẹ̀ pé, “Dájúdájú Olúwa ń bẹ ní ìhín yìí, èmi kò sì mọ̀.”

  2. Jakọbu sì dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀, ó sì gbé òkúta tí ó fi ṣe ìrọ̀rí lélẹ̀ bí ọ̀wọ́n, ó sì da òróró si lórí.

  3. Jakọbu sì jẹ́ ẹ̀jẹ́ níbẹ̀ pé, “Bí Ọlọ́run yóò bá wà pẹ̀lú mi, tí yóò sì pa mí mọ́ ní ìrìnàjò mi tí mo ń lọ, tí yóò sì fún mi ní oúnjẹ láti jẹ àti aṣọ láti wọ̀,

  4. Jakọbu sì tẹ̀síwájú nínú ìrìnàjò rẹ̀, ó sì dé ilẹ̀ àwọn ará ìlà-oòrùn.

  5. Jakọbu béèrè lọ́wọ́ àwọn darandaran náà pé, “Ẹ̀yin arákùnrin mi níbo ni ẹ̀yin ti wá?” Àwọn náà sì dáhùn pé, “Láti Harani ni.”

  6. Nígbà tí Jakọbu rí Rakeli ọmọbìnrin Labani tí í ṣe ẹ̀gbọ́n ìyá rẹ̀, pẹ̀lú àgùntàn Labani, Jakọbu súnmọ́ kànga náà, ó sì yí òkúta kúrò lẹ́nu rẹ̀, ó sì fún àwọn ẹran arákùnrin ìyá rẹ̀ Labani ní omi.

  7. Jakọbu sì fẹnu ko Rakeli ní ẹnu. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọkún.

  8. Jakọbu sì wí fún Rakeli pé ìbátan baba rẹ̀ ni òun, àti pé, òun jẹ́ ọmọ Rebeka. Rakeli sì sáré lọ sọ fún baba rẹ̀.

  9. Ní kété tí Labani gbúròó Jakọbu ọmọ arábìnrin rẹ̀, ó jáde lọ pàdé Jakọbu, ó dì mọ́ ọn, ó fi ẹnu kò ó ní ẹnu, ó sì mú un lọ sí ilé. Nígbà náà ni Jakọbu ròyìn ohun gbogbo fún un.

  10. Labani wí fún Jakọbu pé, “Bí a tilẹ̀ jẹ́ ìbátan, kò yẹ kí o máa ṣiṣẹ́ fún mi lásán láìgba ohun kankan. Sọ ohun tì ìwọ fẹ́ gbà fún iṣẹ́ tí ìwọ ń ṣe fún mi!”

  11. Jakọbu sì fẹ́ràn Rakeli, ó sì wí fún baba rẹ̀ pé, “Èmi yóò ṣiṣẹ́ sìn ọ fún ọdún méje, bí ìwọ yóò bá fún mi ní Rakeli ọmọ rẹ ní aya.”

  12. Jakọbu sì ṣiṣẹ́ sin Labani fún ọdún méje láti fẹ́ Rakeli. Àwọn ọdún wọ̀nyí sì dàbí ọjọ́ díẹ̀ lára rẹ̀, nítorí ó fẹ́ràn rẹ̀.

  13. Jakọbu sì wí fún Labani pé, “Mo ti parí àsìkò tí a jọ ṣe àdéhùn rẹ̀, nítorí náà fún mi ní aya mi, kí òun lè ṣe aya fún mi.”

  14. Jakọbu sì gbà láti sin Labani fún ọdún méje mìíràn. Labani sì fi Rakeli ọmọ rẹ̀ fún un bí aya.

  15. Nígbà tí Rakeli rí i pe òun kò bímọ, ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìlara sí Lea, arábìnrin rẹ̀, ó sì wí fún Jakọbu pé, “Fún mi lọ́mọ, bí kò ṣe bẹ́ẹ̀, èmi ó kú!”

  16. Inú sì bí Jakọbu sí i, ó sì wí pé, “Èmi ha wà ní ipò Ọlọ́run, ẹni tí ó mú ọ yàgàn bí?”

  17. Báyìí ni Rakeli fi Biliha fún Jakọbu ní aya, ó sì bá a lòpọ̀.

  18. Biliha sì lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan fún Jakọbu.

  19. Biliha, ọmọ ọ̀dọ̀ Rakeli sì tún lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kejì fún Jakọbu.

  20. Nígbà tí Lea sì ri pé òun ko tún lóyún mọ́, ó sì fi ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ obìnrin, Silipa fún Jakọbu bí aya.

  21. Silipa ọmọ ọ̀dọ̀ Lea sì bí ọmọkùnrin kan fún Jakọbu.

  22. Silipa ọmọ ọ̀dọ̀ Lea sì tún bí ọmọkùnrin kejì fún Jakọbu.

  23. Nítorí náà, nígbà tí Jakọbu ti oko dé ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà, Lea jáde lọ pàdé rẹ̀, ó sì wí pé, “O ní láti sun ọ̀dọ̀ mi ní alẹ́ yìí nítorí mo ti fi èso mándrákì tí ọmọ mi wá bẹ̀ ọ́ lọ́wẹ̀.” Nítorí náà ni Jakọbu sùn tì í ní alẹ́ ọjọ́ náà.

  24. Ọlọ́run sì gbọ́ ti Lea, ó sì lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin karùn-ún fún Jakọbu.

  25. Lea sì tún lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kẹfà fún Jakọbu.