Fò sí àkóónú

God

11,427 ẹsẹ · 2 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ṣùgbọ́n fún àwa Ọlọ́run kan ní ó wa, Baba, lọ́wọ́ ẹni tí ó dá ohun gbogbo, àti ti ẹni tí gbogbo wa í ṣe, àti Olúwa kan ṣoṣo Jesu Kristi, nípasẹ̀ ẹni tí ohun gbogbo wà, àti àwa nípasẹ̀ rẹ̀.

  2. Ṣùgbọ́n oúnjẹ kò mú wa súnmọ́ Ọlọ́run, nítorí pé kì í ṣe bí àwa bá jẹun ni àwa burú jùlọ tàbí nígbà tí a kò jẹ ni àwa dára jùlọ.

  3. Nítorí nínú òfin tí Ọlọ́run fún Mose, ni a tí kọ ọ́ pé, “Ìwọ kò gbọdọ̀ di màlúù ti ń tẹ ọkà lẹ́nu.” Ǹjẹ́ màlúù ni Ọlọ́run n ṣe ìtọ́jú rẹ̀ bi?

  4. Nígbà tí mo bá wà láàrín àwọn tí kò sí lábẹ́ òfin, èmi náà yóò dàbí ẹni tí kò sí lábẹ́ òfin (èmi kì í ṣe aláìlófin sí Ọlọ́run, ṣùgbọ́n èmí ń bẹ lábẹ́ òfin Kristi), kí èmi le jèrè àwọn tí kò sí lábẹ́ òfin.

  5. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ni inú Ọlọ́run kò dún sí; nítorí a pa wọ́n run nínú aginjù.

  6. Kò sí ìdánwò kan tí ó ti bá yín, bí kò ṣe irú èyí tí ó mọ níwọ̀n fún ènìyàn, ṣùgbọ́n olódodo ni Ọlọ́run, ẹni ti kì yóò jẹ́ kí á dán an yín wò ju bí ẹ̀yin ti le gbà, ṣùgbọ́n tí yóò sì ṣe ọ̀nà àbáyọ pẹ̀lú nínú ìdánwò náà, kí ẹ̀yin ba à lè faradà á.

  7. Rárá, ṣùgbọ́n ohun tí mo ń wí ni pé, ohun tí àwọn aláìkọlà fi ń rú ẹbọ wọn fi fun àwọn ẹ̀mí èṣù. Dájúdájú kì í ṣe ìrúbọ sí Ọlọ́run. Èmi kò sì fẹ́ kí ẹnikẹ́ni nínú yín so ara rẹ̀ pọ̀ mọ́ ẹ̀mí èṣù.

  8. Ẹ̀yin kò lè mu nínú ago tí Olúwa àti ago ti èṣù lẹ́ẹ̀kan náà; ẹ̀yin kò le ṣe àjọpín ní tábìlì Olúwa, àti ni tábìlì ẹ̀mí èṣù lẹ́ẹ̀kan náà.

  9. Nítorí “Ayé àti gbogbo nǹkan rere tí ń bẹ nínú rẹ̀, tí Olúwa ni wọ́n jẹ́.”

  10. Bí ẹnikẹ́ni bá sì kìlọ̀ fún un yín pé, “A ti fi ẹran yìí rú ẹbọ,” ẹ má ṣe jẹ́ ẹ nítorí ẹni ti o sọ fun ọ àti nítorí ẹ̀rí ọkàn.

  11. Nítorí náà tí ẹ̀yin bá jẹ tàbí tí ẹ bá mu tàbí ohunkóhun tí ẹ̀yin bá sè, e máa ṣe gbogbo rẹ̀ fún ògo Ọlọ́run.

  12. Nítorí náà, má ṣe jẹ́ òkúta ìkọ̀sẹ̀ tí ó lè gbé ẹlòmíràn ṣubú ìbá à ṣe Júù tàbí Giriki tàbí ìjọ Ọlọ́run.

  13. Ṣùgbọ́n mo fẹ́ kí ẹ̀yin mọ̀ pé, Kristi ni orí olúkúlùkù ọkùnrin, orí obìnrin sì ni ọkọ rẹ̀ àti orí Kristi sì ní Ọlọ́run.

  14. Ṣùgbọ́n ọkùnrin kò ní láti fi nǹkan bo orí rẹ́ nígbà tí ó bá ń sìn, nítorí àwòrán àti ògo Ọlọ́run ni òun í ṣe, ṣùgbọ́n ògo ọkùnrin ni obìnrin í ṣe.

  15. Lóòtítọ́ láti ara ọkùnrin ni a ti yọ obìnrin jáde bẹ́ẹ̀ sì ni ọkùnrin tipasẹ̀ obìnrin wa. Ṣùgbọ́n láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ohun gbogbo ti wà.

  16. Kí ni ẹ̀yìn fúnra yín rò lórí ọ̀rọ̀ yìí? Ǹjẹ́ ó tọ̀nà fún obìnrin láti máa gbàdúrà Ọlọ́run ní gbangba láìbo orí rẹ̀ bí?

  17. Ṣùgbọ́n tí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ jiyàn lórí ọ̀rọ̀ yìí, ohun kan tí mo lè sọ sí gbogbo rẹ̀ ni pé, a kò ní ìlànà tí ó yàtọ̀ sí èyí tí mo ti sọ, pé obìnrin gbọdọ̀ fi gèlè bo orí rẹ̀ nígbà tí ó bá ń sọtẹ́lẹ̀ tàbí tí ó bá ń gbàdúrà láàrín ìjọ Ọlọ́run.

  18. Nígbà tí ẹ bá pàdé láti jẹun, kì í ṣe oúnjẹ alẹ́ Olúwa ni ẹ máa ń jẹ.

  19. Ṣé ẹ̀yin kò ní ilé tí ẹ ti lè jẹ, tí ẹ sì ti lè mu ni? Tàbí ẹ̀yin ń gan ìjọ Ọlọ́run ni? Ẹ̀yin sì ń dójútì àwọn aláìní? Kín ni kí èmi ó wí fún un yín? Èmi yóò ha yìn yín nítorí èyí? A! Rárá o. Èmi kọ́, n kò ní yìn yín.

  20. Nítorí nígbàkígbà tí ẹ bá ń jẹ lára àkàrà yìí, tí ẹ sì ǹ mu nínú ago yìí, ni ẹ tún sọ nípa ikú Olúwa. Ẹ máa ṣe eléyìí títí yóò fi padà dé.

  21. Nítorí tí ẹ bá jẹ lára àkàrà, tí ẹ sì mu nínú ago láìyẹ, tí ẹ kò ronú ara Kristi àti nǹkan tí ó túmọ̀ sí, ẹ̀ ń jẹ, ẹ sì ń mú ẹ̀bi ìdájọ́ Ọlọ́run wá sórí ara yín.

  22. Nítorí náà, èmí ń sọ fún un yín pé kò sí ẹni ti ń sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ Ẹ̀mí Ọlọ́run tí ó lè wí pé, “Ẹni ìfibú ni Jesu,” àti pé kò sí ẹni tí ó lè sọ pé, “Olúwa ni Jesu,” bí kò ṣe nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́.

  23. Onírúurú iṣẹ́ ìránṣẹ́ ni ó sì wà, ṣùgbọ́n Ọlọ́run kan náà ni ẹni tí ń ṣiṣẹ́ gbogbo wọn nínú gbogbo wọn.

  24. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti fi àwọn ẹ̀yà ara si ara wa, ó sí fi ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan sí ibi tí ó fẹ́ kí ó wà.

  25. Nítorí pé àwọn ibi tí ó ní ẹ̀yẹ ní ara wa kò nílò ìtọ́jú ọ̀tọ̀. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti pa gbogbo ẹ̀yà ara pọ̀ ṣọ̀kan lọ́nà kan, ó sì ti fi ẹ̀yẹ tó ga jùlọ fún ibi tí ó ṣe aláìní.