Fò sí àkóónú

God

11,427 ẹsẹ · 2 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God

Sẹ́ nípa ìwé
  1. “Sálọ kíákíá! Fi ara pamọ́ sí ibi jíjìn, ẹ̀yin olùgbé Hasori,” ni Olúwa wí. “Nebukadnessari ọba Babeli ti dojú ìjà kọ ọ́.

  2. “Dìde kí o sì dojú ìjà kọ orílẹ̀-èdè tí ó wà nínú ìrọ̀rùn, èyí tí ó gbé ní àìléwu,” ní Olúwa wí. “Orílẹ̀-èdè tí kò ní odi tàbí irin, àwọn ènìyàn rẹ̀ ń dágbé.

  3. Àwọn ìbákasẹ á di ẹrù àti àwọn ẹran ọ̀sìn, wọ́n á di ìkógun. Èmi yóò tú àwọn tí ó wà ní òkèèrè sí inú afẹ́fẹ́. Èmi yóò sì mú ibi wá sí àyíká gbogbo,” báyìí ní Olúwa wí.

  4. Èyí ní ọ̀rọ̀ Olúwa èyí tí ó tọ Jeremiah wòlíì wá nípa Elamu ní ìbẹ̀rẹ̀ ìjọba Sedekiah ọba Juda.

  5. Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun sọ: “Wò ó, èmi yóò fọ́ ìtẹ̀gùn Elamu, ẹni tí wọ́n sinmi lé nípa agbára.

  6. Èmi yóò mú kí afẹ́fẹ́ orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin àgbáyé lòdì sí Elamu. Èmi yóò tú wọn ká sí ìpín afẹ́fẹ́ mẹ́rin àti pé, kò sí orílẹ̀-èdè tí ilẹ̀ àjèjì Elamu kò ní lọ.

  7. Èmi yóò kẹ́gàn Elamu níwájú àwọn ọ̀tá wọn, àti níwájú àwọn tí wọ́n ń wá ẹ̀mí wọn, Èmi yóò mú ibi wá sí orí wọn, àní, ìbínú gbígbóná mi,” bẹ́ẹ̀ ni Olúwa wí. “Èmi yóò lé wọn pẹ̀lú idà, di ìgbà tí èmi yóò rẹ́yìn wọn.

  8. Èmi yóò sì gbé ìtẹ́ mi kalẹ̀ ní Elamu, èmí yóò sì pa ọba wọn àti ìjòyè wọn run,” báyìí ni Olúwa wí.

  9. “Síbẹ̀, èmi yóò dá ìkólọ Elamu padà láìpẹ́ ọjọ́,” báyìí ni Olúwa wí.

  10. Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa fi sẹ́nu wòlíì Jeremiah láti sọ fún ará ilẹ̀ Babeli:

  11. “Ní ọjọ́ wọ̀nyí àti ní àkókò náà,” ni Olúwa wí, “Àwọn ọmọ Israẹli yóò jùmọ̀ wá, àwọn, àti àwọn ọmọ Juda, wọn yóò lọ pẹ̀lú ẹkún láti ṣàfẹ́rí Olúwa Ọlọ́run wọn.

  12. Wọn ó máa béèrè ọ̀nà Sioni, ojú wọn yóò sì yí síhà ibẹ̀, wí pé ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a darapọ̀ mọ́ Olúwa ní májẹ̀mú ayérayé, tí a kì yóò gbàgbé.

  13. Gbogbo àwọn tí ó rí wọn, ti pa wọ́n jẹ àwọn ọ̀tá wọ́n sì wí pé, ‘Àwa kò jẹ̀bi nítorí pé wọ́n ti ṣẹ̀ sí Olúwa ibùgbé òdodo àti ìrètí àwọn baba wọn.’

  14. Nítorí pé èmi yóò ru, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò gbé sókè sí Babeli àwọn orílẹ̀-èdè ńlá láti ilẹ̀ àríwá. Wọn yóò gba àyà wọn lẹ́gbẹ́ rẹ̀; láti àríwá wá, à ó sì mú ọ. Ọfà wọn yóò dàbí ọfà àwọn akọni akíkanjú tí wọn kì í wà lọ́wọ́ òfo.

  15. A ó dààmú Babeli, gbogbo àwọn tó dààmú rẹ yóò sì mú ìfẹ́ wọn ṣẹ,” ni Olúwa wí.

  16. Nítorí ìbínú Olúwa, kì yóò ní olùgbé; ẹnikẹ́ni kò sì ní gbé inú rẹ̀. Gbogbo àwọn tí ó bá kọjá ni Babeli yóò fi ṣe yẹ̀yẹ́ nítorí ọgbẹ́ rẹ̀.

  17. “Dúró sí ààyè rẹ ìwọ Babeli àti gbogbo ẹ̀yin tí ẹ n ta ọfà náà. Ẹ ta ọfà náà sí i, nítorí ó ti ṣẹ̀ sí Olúwa.

  18. Kígbe mọ́ ọn ní gbogbo ọ̀nà! Ó tẹríba, òpó rẹ̀ sì yẹ̀, níwọ̀n ìgbà tí ó ti jẹ́ wí pé èyí ni ìgbẹ̀san Olúwa, gbẹ̀san lára rẹ̀. Ṣe sí i gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe sí àwọn ẹlòmíràn.

  19. Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Alágbára, Ọlọ́run Israẹli wí, “Ǹ ó fi ìyà jẹ ọba Babeli àti ilẹ̀ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe fìyà jẹ ọba, Asiria.

  20. Ṣùgbọ́n, èmi yóò mú Israẹli padà wá pápá oko tútù rẹ̀ òun yóò sì máa bọ́ ara rẹ̀ lórí Karmeli àti Baṣani, a ó sì tẹ́ ọkàn rẹ̀ lọ́rùn ní òkè Efraimu àti ní Gileadi.

  21. Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì,” ni Olúwa wí, “À ó wá àìṣedéédéé ẹ̀ṣẹ̀ Israẹli, ṣùgbọ́n a ki yóò rí ohun; àti ẹ̀ṣẹ̀ Juda ni a ki yóò sì rí mọ kankan nítorí èmi yóò dáríjì àwọn tí ó ṣẹ́kù tí mo dá sí.

  22. “Kọlu ilẹ̀ Merataimu àti àwọn tí ó ń gbé ní Pekodi. Lépa rẹ pa, kí o sì parun pátápátá,” ni Olúwa wí, “Ṣe gbogbo ohun tí mo pàṣẹ fún ọ.

  23. Mo dẹ pàkúté sílẹ̀ fún ọ ìwọ Babeli, kí o sì tó mọ ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀, o ti kó sínú rẹ̀. A mú ọ nítorí pé o tako Olúwa.

  24. Olúwa ti kó àwọn ohun èlò ìjà rẹ̀ jáde, nítorí pé Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun ti ṣiṣẹ́ ní ilẹ̀ Babeli.

  25. Gbọ́ ohùn àwọn tí ó sálọ, tí ó sì sálà láti Babeli wá, sì sọ ní Sioni, bí Olúwa Ọlọ́run wa ti gbẹ̀san, ẹ̀san fún tẹmpili rẹ̀.