God
Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God
Báyìí ni Olúwa wí: “Wò ó ẹyẹ idì náà ń fò bọ̀ nílẹ̀ ó sì na ìyẹ́ rẹ̀ lórí Moabu.
A ó pa Moabu run gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè nítorí pé ó gbéraga sí Olúwa.
Ẹ̀rù àti ọ̀fìn àti okùn dídè ń dúró dè yín, ẹ̀yin ènìyàn Moabu,” ní Olúwa wí.
“Ẹnikẹ́ni tí ó bá sá fún ẹ̀rù yóò ṣubú sínú ọ̀fìn ẹnikẹ́ni tí o bá jáde síta nínú ọ̀fìn ní à ó mú nínú okùn dídè nítorí tí èmi yóò mú wá sórí Moabu àní ọdún ìjìyà rẹ,” ní Olúwa wí.
“Síbẹ̀, èmi yóò dá ìkólọ Moabu padà ní ọjọ́ ìkẹyìn,” ni Olúwa wí. Eléyìí ní ìdájọ́ ìkẹyìn lórí Moabu.
Nípa Ammoni. Báyìí ni Olúwa wí, “Israẹli kò ha ní ọmọkùnrin? Israẹli kò ha ní àrólé bí? Nítorí kí ni Malkomu ṣe jogún Gadi? Kí ló dé tí àwọn ènìyàn rẹ̀ ń gbé ìlú rẹ̀?
Ṣùgbọ́n ọjọ́ náà ń bọ̀,” ni Olúwa wí; “nígbà tí èmi yóò mú kí a gbọ́ ìdágìrì ogun ní Rabba tí Ammoni; yóò sì di òkìtì ahoro, gbogbo ìlú tí ó yí i ká ni a ó jó níná. Nígbà náà ni Israẹli yóò lé wọn, àwọn tí ó ti lé e jáde,” ni Olúwa wí.
Èmi yóò mu ẹ̀rù wá lórí rẹ láti ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn tó yí ọ ká,” ni Olúwa, ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.
“Olúwa àwọn ọmọ-ogun. Gbogbo yín ni ó lé jáde, kò sì ṣí ẹnìkan tí yóò dá ìkólọ Ammoni padà,” ni Olúwa wí.
Nípa Edomu. Èyí ní ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: “Ṣe kò ha sí ọgbọ́n mọ́ ni Temani? Ṣé a ti ké ìmọ̀ràn kúrò ní ọ̀dọ̀ olóyè? Ṣé ọgbọ́n wọn ti bàjẹ́ bí?
Yípadà kí o sálọ, sá pamọ́ sínú ihò, ìwọ tí ó ń gbé ní Dedani, nítorí èmi yóò mú ibi wá sórí Esau, ní àkókò tí èmi ó bẹ̀ ẹ́ wò.
Ṣùgbọ́n èmi yóò tu Esau sí ìhòhò, èmi ti fi ibi ìkọ̀kọ̀ rẹ̀ hàn, nítorí kí o máa ba à fi ara rẹ pamọ́. Àwọn ọmọ rẹ, ẹbí rẹ àti àwọn ará ilé rẹ yóò parun. Wọn kò sì ní sí mọ́.
Fi àwọn ọmọ aláìní baba sílẹ̀ èmi yóò dáàbò bo ẹ̀mí wọn. Àwọn opó rẹ gan an lè gbẹ́kẹ̀lé mi.”
Èyí ni ohun tí Olúwa wí bí ẹnikẹ́ni tí kò bá yẹ kí ó mu ago náà bá mú un, kí ló dé tí ìwọ yóò fi lọ láìjìyà? Ìwọ kò ní lọ láìjìyà; ṣùgbọ́n ìwọ yóò mú un.
Èmi fi ara mi búra ni Olúwa wí, wí pé, “Bosra yóò ba ayé ara rẹ̀ jẹ́. Yóò di ẹni ẹ̀gàn, ẹni èpè àti ẹni ègún, àti gbogbo ìlú rẹ̀ yóò di ìbàjẹ́ títí láé.”
Ní gbígbọ́, èmi ti gbọ́ ìró kan láti ọ̀dọ̀ Olúwa, a rán ikọ̀ kan sí orílẹ̀-èdè pé, ẹ kó ara yín jọ, ẹ wá sórí rẹ̀, ẹ sì dìde láti jagun.
“Ní báyìí, èmi yóò sọ ọ́ di kékeré láàrín orílẹ̀-èdè gbogbo; ẹni ẹ̀gàn láàrín àwọn ènìyàn.
Ìpayà tí ìwọ ti fà sínú ìgbéraga ọkàn rẹ sì ti tàn ọ́ jẹ; ìwọ tí ń gbé ní pàlàpálá àpáta, tí o jókòó lórí ìtẹ́ gíga síbẹ̀ o kọ́ ìtẹ́ rẹ ga gẹ́gẹ́ bí ẹyẹ idì; láti ibẹ̀ ni èmi yóò ti mú ọ sọ̀kalẹ̀ wá,” ni Olúwa wí.
Gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe gba Sodomu àti Gomorra pẹ̀lú àwọn ìlú tí ó wà ní àyíká rẹ,” ní Olúwa wí. “Bẹ́ẹ̀ ni, kò sí ẹnikẹ́ni tí yóò gbé níbẹ̀; kò sì ní sí ènìyàn tí yóò tẹ̀dó síbẹ̀ mọ́.
“Bí i kìnnìún ni òun ó gòkè wá láti igbó Jordani sí orí ilẹ̀ ọlọ́ràá, Èmi ó lé Edomu kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀ ní kíákíá. Ta ni àyànfẹ́ náà tí èmi ó yàn sórí rẹ̀? Ta ló dàbí mi, ta ni ó sì pé mi ṣe ẹlẹ́rìí? Ta ni olùṣọ́-àgùntàn náà tí yóò le dúró níwájú mi?”
Nítorí náà, ẹ gbọ́ ohun tí Olúwa ní fún Edomu, ohun tí ó ní ní pàtàkì fún àwọn tí ń gbé ní Temani. Àwọn ọ̀dọ́ àgbò ni à ó lé jáde; pápá oko wọn ni yóò run nítorí wọn.
Kí ló dé tí ìlú olókìkí di ohun ìkọ̀sílẹ̀; ìlú tí mo dunnú sí.
Lóòtítọ́, àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin rẹ yóò ṣubú lójú pópó, gbogbo àwọn ọmọ-ogun rẹ yóò pa ẹnu mọ́ ní ọjọ́ náà,” ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.
“Èmi yóò fi iná sí odi Damasku, yóò sì jó gbọ̀ngàn Beni-Hadadi run.”
Nípa ìlú Kedari àti ìjọba Hasori èyí ti Nebukadnessari ọba Babeli dojú ìjà kọ, èyí ni ohun tí Olúwa sọ, “Dìde kí o sì dojú ìjà kọ ìlú Kedari, kí o sì pa àwọn ènìyàn ìlà-oòrùn run.