God
Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God
Òdodo ni yóò jẹ́ ìgbànú rẹ̀ àti òtítọ́ ni yóò ṣe ọ̀já yí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ ká.
Wọn kò ní ṣe ni léṣe tàbí pa ni run ní gbogbo òkè mímọ́ mi, nítorí gbogbo ayé yóò kún fún ìmọ̀ Olúwa gẹ́gẹ́ bí omi ti bo Òkun.
Ní ọjọ́ náà, gbòǹgbò Jese yóò dúró gẹ́gẹ́ bí àsíá fún gbogbo ènìyàn, àwọn orílẹ̀-èdè yóò pagbo yí i ká, ibùdó ìsinmi rẹ̀ yóò jẹ́ èyí tí ó lógo.
Ní ọjọ́ náà, Olúwa yóò na ọwọ́ rẹ̀ jáde nígbà kejì láti tún gba àwọn tí ó ṣẹ́kù àní àwọn tí a ṣẹ́kù nínú àwọn ènìyàn an rẹ̀ láti Asiria wá, láti ìsàlẹ̀ Ejibiti àti òkè Ejibiti, láti Kuṣi, láti Elamu láti Babiloni, láti Hamati àti láti àwọn erékùṣù inú Òkun.
Òun yóò gbé àsíá sókè fún àwọn orílẹ̀-èdè, yóò sì kó àwọn ìgbèkùn Israẹli jọ, yóò kó gbogbo àwọn ènìyàn Juda tí a ti fọ́n káàkiri jọ, láti igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilẹ̀ ayé.
Olúwa yóò sọ di gbígbé àyasí Òkun Ejibiti, pẹ̀lú atẹ́gùn gbígbóná ni yóò na ọwọ́ rẹ̀, kọjá lórí odò Eufurate. Òun yóò sì sọ ọ́ di ọmọdò méje tó fi jẹ́ pé àwọn ènìyàn yóò máa là á kọjá pẹ̀lú bàtà.
Ọ̀nà gidi yóò wà fún àwọn ènìyàn an rẹ̀ tí ó ṣẹ́kù tí ó kù sílẹ̀ ní Asiria, gẹ́gẹ́ bí ó ti wà fún Israẹli nígbà tí wọ́n gòkè láti Ejibiti wá.
Ní ọjọ́ náà ni ìwọ ó wí pé, “Èmi ó yìn ọ́, Olúwa. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ò ti bínú sí mi ìbínú rẹ ti yí kúrò níbẹ̀ ìwọ sì ti tù mí nínú.
Nítòótọ́ Ọlọ́run ni ìgbàlà mi, èmi yóò gbẹ́kẹ̀lé e èmi kì yóò bẹ̀rù. Olúwa, Olúwa náà ni agbára à mi àti orin ìn mi, òun ti di ìgbàlà mi.”
Ní ọjọ́ náà, ìwọ yóò wí pé, “Fi ọpẹ́ fún Olúwa, ké pe orúkọ rẹ̀, jẹ́ kí ó di mí mọ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, ohun tí ó ti ṣe kí o sì kéde pé a ti gbé orúkọ rẹ̀ ga.
Kọ orin sí Olúwa, nítorí ó ti ṣe ohun tí ó lógo, jẹ́ kí èyí di mí mọ̀ fún gbogbo ayé.
Kígbe sókè kí o sì kọrin fún ayọ̀, ẹ̀yin ènìyàn Sioni, nítorí títóbi ni ẹni mímọ́ kan ṣoṣo ti Israẹli láàrín yín.”
Mo ti pàṣẹ fún àwọn ẹni mímọ́ mi, mo ti pe àwọn jagunjagun mi láti gbé ìbínú mi jáde àwọn tí ń yọ̀ nínú ìṣẹ́gun mi.
Gbọ́ ohùn kan ní àwọn orí òkè, gẹ́gẹ́ bí i ti ogunlọ́gọ̀ ènìyàn. Gbọ́ ìdàrúdàpọ̀ láàrín àwọn ìjọba, gẹ́gẹ́ bí i ti ìkórajọ àwọn orílẹ̀-èdè! Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti kó ogun rẹ̀ jọ àwọn jagunjagun fún ogun.
Wọ́n wá láti ọ̀nà jíjìn réré, láti ìpẹ̀kun ọ̀run wá Olúwa pẹ̀lú àwọn ohun ìjà ìbínú rẹ̀, láti pa gbogbo orílẹ̀-èdè náà run.
Ẹ hu, nítorí ọjọ́ Olúwa súnmọ́ tòsí, yóò sì wá gẹ́gẹ́ bí ìparun láti ọ̀dọ̀ Alágbára jùlọ.
Kíyèsi i, ọjọ́ Olúwa ń bọ̀ ọjọ́ búburú, pẹ̀lú ìbínú àti ìrunú gbígbóná— láti sọ ilẹ̀ náà dahoro, àti láti pa àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ inú rẹ̀ run.
Èmi yóò jẹ ayé ní ìyà nítorí ibi rẹ̀, àwọn ìkà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Èmi yóò fi òpin sí gààrù àwọn agbéraga èmi ó sì rẹ ìgbéraga àwọn aláìláàánú sílẹ̀.
Èmi yóò jẹ́ kí ọkùnrin kí ó wọn ju ojúlówó wúrà lọ, yóò sì ṣọ̀wọ́n ju wúrà Ofiri lọ.
Nítorí náà èmi yóò jẹ́ kí àwọn ọ̀run kí ó wárìrì; ayé yóò sì mì tìtì ní ibùjókòó rẹ̀ láti ọwọ́ ìbínú Olúwa àwọn ọmọ-ogun, ní ọjọ́ ìbínú gbígbóná rẹ.
Kíyèsi i, èmi yóò ru àwọn Media sókè sí wọn, àwọn tí kò bìkítà fún fàdákà tí kò sì ní inú dídùn sí wúrà.
Babeli, ohun ọ̀ṣọ́ àwọn ìjọba ògo ìgbéraga àwọn ará Babeli ni Ọlọ́run yóò da ojú rẹ̀ bolẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Sodomu àti Gomorra.
Olúwa yóò fi àánú hàn fún Jakọbu, yóò tún Israẹli yàn lẹ́ẹ̀kan sí i yóò sì fi ìdí wọn kalẹ̀ ní ilẹ̀ àwọn tìkára wọn. Àwọn àjèjì yóò darapọ̀ mọ́ wọn, wọn yóò sì fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ilé e Jakọbu.
Àwọn orílẹ̀-èdè yóò gbà wọ́n wọn yóò sì mú wọn wá sí ààyè e wọn. Ilé Israẹli yóò gba àwọn orílẹ̀-èdè gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin ní ilẹ̀ Olúwa. Wọn yóò kó àwọn akónilẹ́rú wọn ní ìgbèkùn wọn yóò sì jẹ ọba lórí àwọn amúnisìn wọn.
Ní ọjọ́ tí Olúwa yóò fi ìtura fún un yín kúrò nínú ìpọ́njú àti ìyà àti ìdè ìkà,