Fò sí àkóónú

God

11,427 ẹsẹ · 2 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn náà kò tí ì yípadà sí ẹni náà tí ó lù wọ́n bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kò wá Olúwa àwọn ọmọ-ogun.

  2. Nítorí náà ni Olúwa yóò ṣe ké àti orí àti ìrù kúrò ní Israẹli, àti ọ̀wá ọ̀pẹ àti koríko odò ní ọjọ́ kan ṣoṣo,

  3. Nítorí náà, Olúwa kì yóò dunnú sí àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin tàbí kí ó káàánú àwọn aláìní baba àti opó, nítorí pé gbogbo wọn jẹ́ ìkà àti aláìmọ Ọlọ́run, ibi ni ó ti ẹnu wọn jáde. Síbẹ̀, fún gbogbo èyí, ìbínú rẹ̀ kò yí kúrò ọwọ́ rẹ̀ sì wà ní gbígbéró.

  4. Nípasẹ̀ ìbínú Olúwa àwọn ọmọ-ogun ilẹ̀ náà yóò di gbígbẹ àwọn ènìyàn yóò sì di ohun ìdáná, ẹnìkan kì yóò sì dá arákùnrin rẹ̀ sí.

  5. Manase yóò máa jẹ Efraimu, nígbà tí Efraimu yóò jẹ Manase wọn yóò parapọ̀ dojúkọ Juda. Síbẹ̀síbẹ̀, ìbínú un rẹ̀ kò yí kúrò Ọwọ́ọ rẹ̀ sì wà ní gbígbéró.

  6. láti dún àwọn aláìní ní ẹ̀tọ́ wọn àti láti fa ọwọ́ ìdájọ́ sẹ́yìn kúrò níwájú àwọn olùpọ́njú ènìyàn mi, wọ́n sọ àwọn ọ̀pọ̀ di ìjẹ fún wọn, wọ́n sì ń ja àwọn aláìní baba lólè.

  7. Ohunkóhun kò ní ṣẹ́kù mọ́ bí kò ṣe láti tẹ̀ ba láàrín àwọn ìgbèkùn tàbí kí o ṣubú sáàrín àwọn tí a pa. Pẹ̀lú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, ìbínú rẹ̀ kò kúrò, ọwọ́ rẹ̀ sì tún gbé sókè.

  8. “Ègbé ni fún àwọn ará Asiria, ọ̀gọ ìbínú mi, ní ọwọ́ ẹni tí kùmọ̀ ìbínú mi wà!

  9. Mo rán an sí orílẹ̀-èdè aláìní Ọlọ́run, mo dojú rẹ̀ kọ àwọn ènìyàn tí ó mú mi bínú láti já ẹrù gbà, àti láti kó ìkógun láti tẹ̀ mọ́lẹ̀ bí amọ̀ ní ojú òpópó.

  10. Èmi kì yóò a bá Jerusalẹmu wí àti àwọn ère rẹ̀?’ ” Gẹ́gẹ́ bí mo ṣe ṣe sí Samaria àti àwọn ère rẹ̀?

  11. Nígbà tí Olúwa ti ṣe iṣẹ́ rẹ̀ sí òkè Sioni àti Jerusalẹmu, yóò sọ wí pé, “Èmi yóò fi ìyà jẹ ọba Asiria nítorí gààrù àyà rẹ̀ àti ìgbéraga ojú rẹ̀.

  12. Nítorí náà, ni Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun, yóò rán ààrùn ìrẹ̀dànù sórí àwọn akíkanjú jagunjagun, lábẹ́ ògo rẹ̀ ni iná kan yóò ti sọ gẹ́gẹ́ bí iná ajónirun.

  13. Ìmọ́lẹ̀ Israẹli yóò di iná, Ẹni Mímọ́ rẹ̀ yóò jẹ́ ọ̀wọ́-iná, ní ọjọ́ kan ṣoṣo yóò jó yóò sì run àti ẹ̀gún àti ẹ̀wọ̀n.

  14. Ní ọjọ́ náà, àwọn tí ó ṣẹ́kù ní Israẹli, àwọn tí ó yè ní ilé e Jakọbu, kò ní gbẹ́kẹ̀lé ẹni náà tí ó lù wọ́n bolẹ̀, ṣùgbọ́n ní òtítọ́ yóò gbẹ́kẹ̀lé Olúwa, Ẹni Mímọ́ Israẹli.

  15. Àwọn ìyókù yóò padà, àwọn ìyókù ti Jakọbu yóò padà sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Alágbára.

  16. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ènìyàn rẹ, ìwọ Israẹli dàbí yanrìn ní Òkun, ẹni díẹ̀ ni yóò padà. A ti pàṣẹ ìparun, àkúnwọ́sílẹ̀ àti òdodo.

  17. Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni yóò mú un ṣẹ, ìparun tí a ti pàṣẹ rẹ̀ lórí gbogbo ilẹ̀ náà.

  18. Nítorí náà, báyìí ni Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, “Ẹ̀yin ènìyàn mi tí ó ń gbé Sioni, ẹ má ṣe bẹ̀rù àwọn Asiria, tí ó ń fi ọ̀pá lù yín, tí wọ́n sì ń gbé ọ̀gọ tì yín bí Ejibiti ti ṣe.

  19. Láìpẹ́, ìbínú mi sí i yín yóò wá sí òpin n ó sì dojú ìrunú mi kọ wọ́n, fún ìparun wọn.”

  20. Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò nà wọ́n ní ẹgba. Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe lu Midiani ní òkè Orebu, yóò sì gbé ọ̀pá rẹ̀ lé orí omi gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ní Ejibiti.

  21. Wò ó, Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun, yóò kán ẹ̀ka náà sọnù pẹ̀lú agbára. Àwọn igi ọlọ́lá ni a ó gé lulẹ̀ àwọn tí ó ga gogoro ni a ó rẹ̀ sílẹ̀.

  22. Òun yóò gé igbó dídí pẹ̀lú àáké, Lebanoni yóò ṣubú níwájú Alágbára náà.

  23. Ẹ̀mí Olúwa yóò sì bà lé e, ẹ̀mí ọgbọ́n àti ti òye, ẹ̀mí ìmọ̀ràn àti ti agbára, ẹ̀mí ìmọ̀ àti ti ìbẹ̀rù Olúwa.

  24. Òun yóò sì ní inú dídùn nínú ìbẹ̀rù Olúwa. Òun kì yóò ṣe ìdájọ́ pẹ̀lú ohun tí ó fi ojú u rẹ̀ rí, tàbí pẹ̀lú ohun tí ó fi etí i rẹ̀ gbọ́,

  25. ṣùgbọ́n pẹ̀lú òdodo ni yóò ṣe ìdájọ́ àwọn aláìní, pẹ̀lú òtítọ́ ni yóò ṣe ìpinnu fún àwọn aláìní ayé. Òun yóò lu ayé pẹ̀lú ọ̀pá tí ó wà ní ẹnu rẹ̀, pẹ̀lú èémí ẹnu rẹ̀ ni yóò pa àwọn ìkà.